Àdìrẹ ni ìjọ̀ba fẹ́ fi rọ́pò Kakí tó fẹ́ gbà lọ́rùn àwọn àgùnbánirọ̀ lábẹ́ àtúntò tó bá ètò ìsìnrúùlú NYSC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita feto idagbasoke awọn ọdọ nilẹ Naijiria, Ayodele Olawande ti fidi rẹ mulẹ pe lotitọ ni ayipada ati atunto ti deba eto isinru-ilu ti awọn agunbanirọ n ṣe, ati pe ọkan pataki lara awọn atunto ọhun ni bi wọn ṣe yi aṣọ idanimọ Kaki ti wọn n lo tẹlẹ pada si aṣọ ibilẹ tii ṣe Adirẹ.
Olawande lo fidi atunto naa mulẹ lasiko to n dahun ibeere nileeṣẹ amohunmaworan Channels l'Ọjọbọ, ọsẹ yii.
Minisita ọhun sọ pe erongba naa lo waye lori ipinnu lati bẹrẹ sii ṣe igbelarugẹ fun ohun ibilẹ ati ajogunba, paapaa lati rii pe owo ti ijọba n na, lo n ṣe eto ọrọ aje ilẹ Naijiria loore.
Siwaju sii lo sọ pe kaakiri awọn ipinlẹ kan orileede Naijiria ni wọn ti n ṣe aṣọ Adirẹ jade, ati pe ijọba ni lati maa na owo sori awọn ohun ti wọn n ṣe jade nilẹ naa.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, "Aṣọ Adirẹ ni. Ilẹ Naijiria ni wọn ti n ṣe e. A ni wọn nipinlẹ Ogun, a ni wọn ni Kwara, bẹẹ la ni ileeṣẹ to n ṣe aṣọ. Ẹ jẹ ka da owo wa pada sinu eto ọrọ aje wa lorileede yii."
Minisita naa tun sọ pe labẹ eto atunto ọhun, gbogbo awọn agunbanirọ ni wọn yoo maa pin kaakiri si ẹka iṣẹ ti wọn ba kọ nile-ẹkọ, dipo bi wọn ṣe n ṣe e tẹlẹ.
O ṣalaye pe awọn akẹkọọ-gboye ti wọn ba kẹkọọ nipa eto ẹkọ niwọn yoo pin si ile-ẹkọ, leyi to yatọ si bo ti ṣe wa tẹlẹ, to jẹ pe niṣe ni wọn yoo gbe wọn kaakiri lọ si ibi ti ori ba da wọn si, lai wo ti ohun ti wọn lọ kọ nipa rẹ nile ẹkọ.
"Kii ṣe pe lẹyin ti ẹ ba kuro nilẹ ipagọ, a kan maa pin yin yin sile ẹkọ nitori pe NYSC fẹ ki ẹ lọ sile ẹkọ, ṣugbọn nitori ilana ti wọn tẹle nigba ti wọn wa nilẹ ipagọ. Fun idi eyi, yoo jẹ ki ẹ wa ni ilana iṣẹ ti wọn maa pin in yin si," o fi kun ọrọ rẹ.
Bakan naa, lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ lawọn agbegbe kan nilẹ Naijiria, Olawande sọ pe awọn ti n ṣeto lori bi awọn ileeṣẹ agunbanirọ yoo ṣe pin agunbanirọ kọọkan si awọn agbegbe ti wọn ti kẹkọọ jade, eyi ti wọn ti mọ daadaa, paapaa lawọn agbegbe to ni ipenija eto aabo.
O ni igbesẹ naa yoo fi ọkan awọn obi ati alagbatọ balẹ, ati awọn to fẹẹ sin ilẹ baba wọn balẹ, ti awọn yoo si jẹ ki onikaluku ni ẹtọ si awọn alakalẹ.
"A ni awọn agbegbe kan to n koju ipenija eto aabo, dipo ka kan an nipa fun wọn lati lọ sibẹ, ti yoo si mu ki awọn obi ati alagbatọ maa sọrọ, a tun ni lati fun wọn lanfaani lati wo o pe, 'o dara, awọn wo lo wa lagbegbe yii, awọn wo lo kawe lagbegbe naa, ti wọn mọ ibẹ daadaa?' Kii ṣe ka gbe ẹnikan lati ẹkun Guusu-Iwọ-Oorun lọ si Ariwa-Ila-Oorun.
"Bi o ba wa nifẹ sii wi pe o fẹẹ lọ si Ariwa Ila-Oorun, ki lo de ti a fẹẹ da ẹ duro, ṣugbọn ti o ko ba nifẹ lati lọ, a ko nii ṣe bẹẹ. Awọn nnkan ti a n sọ nipa rẹ ree," o ṣalaye.
Bẹẹ lo sọrọ lori awuyewuye to ti n lọ nipa wi pe wọn yoo yọwọ awọn ọmọ ogun kuro patapata ninu eto agunbanirọ, to si ni irọ to jinna si otitọ lasan ni.
O jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn araalu ni yoo maa ṣakoso ilana naa, sibẹ awọn ologun yoo ṣi maa ko ipa ti wọn lọ, paapaa lati rii pe eto aabo wa fun gbogbo agunbanirọ.
"A ko nii mu awọn ologun kuro ninu eto agunbanirọ, aṣigbọ lasan ni, ọpọ awọn nnkan ti wọn n gbe jade ni ko bojumu, idi si ree ti a fi gbọdọ maa ṣe iwadii koto di pe a sọrọ. A ko mu ologun kuro, ko si bi a ṣe maa mu awọn ologun kuro. Ohun ti a sọ ni pe a maa mu wọn kuro ninu eto pinpin awọn agunbanirọ sibi ti wọn yoo ti sin ilẹ baba wọn," minisita jẹ ko di mimọ.
Atunto yii lo waye lẹyin ti igbimọ iṣakoso, FEC buwọ lu lọjọ Aje nipa ayipada sinu eto agunbaniro, eyi to jẹ ayipada akọkọ latigba ti wọn ti da a silẹ lọdun mẹtalelaadọta sẹyin.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ipinnu, FEC sọ pe ki adajọ agba orileede Naijiria ati minisita feto idagbasoke awọn ọdọ lati mu ayipada ma ofin agunbaniro ati awọn ilana rẹ, lati le gba awọn atunto tuntun laaye, ati lati bẹrẹ sii ṣe amulo wọn.
Labẹ eto atunto naa, ẹni ti kii ṣe ologun ni yoo maa dari iṣakoso agunbanirọ, nigba ti ileeṣẹ ologun yoo maa pese eto aabo fun awọn agunbanirọ kaakiri orileede naa.



























