Táńkà epo Dísù rébọ́ sílẹ̀ láti orí afárá Otedola, iná sọ, èèyàn méjì jóná kọjá ààlà

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ pannapanna ipinlẹ EKo ree lasiko ti wọn ṣẹṣẹ pa ina ọkọ agbepo to jona tan lori afara Otedola
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fun bi ọpọ wakati ni ori afara Femi Otedola to wa nipinlẹ Eko fi da paro-paro, nigba ti ọkọ agbepo nla kan deedee ṣubu lulẹ, to si gbina loju ẹsẹ.

Ọkọ agbepo oni lita ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn naa la gbọ pe o jabọ silẹ ni aarin meji afara naa, ko to di pe o gbina.

Epo rọbii ti wọn n pe ni disu (diesel), la gbọ pe ọkọ agbepo naa gbe, lasiko to jabọ lulẹ lori afara ọhun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ileeṣẹ pannapanna nipinlẹ Eko sọ pe ọkọ agbepo naa jona kọja idanimọ lasiko ọhun.

Awọn alakoso sọ pe nnkan bi agogo mẹrin kọja iṣẹju mẹsan irọlẹ ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni wọn ranṣẹ pe awọn.

"Ileeṣẹ pannapanna ipinlẹ Eko ti pa ijamba ina ọkọ agbepo oni lita mẹtalelọgbọn to ṣubu lori afara Otedola nipinlẹ Eko," atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Deedee agogo mẹrin kọja iṣẹmẹsan irọlẹ la gba ipe pajawiri nipa ọkọ agbepo to n jona, eyi to n gbe epo bọ lati ileeṣẹ elepo rọbii.

"Ọkọ agbepo naa jabọ s'aarin meji afara Otedola, to si ṣokunfa ko gbina loju ẹsẹ."

Atẹjade naa ti Margaret Abimbola Adeseye to jẹ alakoso agba buwọlu sọ pe loju ẹsẹ ni awọn oṣiṣẹ wọn lati ẹkun Alausa ati Ikeja ti gbera lọ sibẹ.

"Agogo mẹrin kọja iṣẹju mẹrindinlogun ni ikọ wa debẹ, ti wọn si bẹrẹ igbesẹ lati pa ina naa loju ẹsẹ, lai fi akoko ṣofo," Adeseye fi kun ọrọ rẹ.

O tẹsiwaju pe igbesẹ naa lo jẹ ki wọn ri ina ọhun pa patapata, ati pe igbesẹ ti n lọ lati rii pe wọn gbe ajoku ọkọ agbepo naa kuro nibi to jona si, lati dẹkun ijamba ọjọ iwaju miran.

Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ awọn yoo tubọ maa fi to gbogbo araalu leti nipa ohun to ṣokunfa ijamba naa, ati iye awọn to fara kaaṣa nigba ti iṣẹ iwadii ba tubọ pari.

Adeseye wa fidi rẹ mulẹ pe gẹgẹ bi ojuṣe ileeṣẹ awọn, awọn yoo tubọ maa dide si aabo ẹmi ati dukia araalu lai fi akoko ṣofo.

O wa rọ awọn awakọ lati maa ṣe suuru, ki wọn si maa tẹle itọni awọn alakoso, paapaa lawọn agbegbe ti iṣẹlẹ pajawiri ba ti n ṣẹlẹ.

Kí ní àjọ LASTMA sọ?

Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa, LASTMA fi sita, wọn ni eeyan ti ko din ni meji lo jona kọja idanimọ lasiko ijamba ina ọhun.

Atẹjade naa ti alakoso eto ilanilọyẹ, Adebayo Taofiq buwọlu, sọ pe yatọ si awọn to ku sinu ijamba naa, awọn miran tun farapa yannayanna.

"Ileeṣẹ LASTMA loni, tun ti ṣiṣẹ wọn lati daabo bo ẹmi ati lati ṣiṣẹ lori iṣẹlẹ ijamba ọkọ, lẹyin ti ọkọ agbepo diu (diesel) kan jabọ lori afara Otedola, to si gbina labẹ fara naa," atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Ijamba naa ṣokunfa iku eeyan meji ti wọn jona kọja sisọ, leyi to jẹ ka tete gbe wọn kuro lọ sibi ti wọn yoo ti ri itọju."

Siwaju sii ni wọn sọ ọ di mimọ pe awọn pẹlu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ pannapanaa ni wọn jọ ṣiṣẹ ọhun.