Kà nípa Najeem Folasayo Salaam tó ń du ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ADC

Oríṣun àwòrán, @Najeem Salam Fcbk
Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 yii ni eto idibo sipo gomina ipinlẹ Osun yoo waye, ọpọ oloṣẹlu lo si n du ipo naa.
Lara awọn oloṣelu jankan lati ipinlẹ Osun to n du ipo naa ni Ọmọwe Najeem Folasayo Salaam labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC.
Ọmọ alailobi ni ọkunrin naa amọ ko gba ki ipinlẹ rẹ ṣakoba fun ọjọ ọla rẹ, o tiraka titi to fi di Ọmọwe, aṣofin ati ẹni to n du ipo gomina.
Eyii ni awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Najeem Folasayo Salaam.
Ibẹrẹ aye Najeem

Oríṣun àwòrán, Najeem Salam
Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 1965 ni wọn bi Ọmọwe Najeem Folasayo Salaam niluu Ejigbo, nipinlẹ Osu, nibi to ti ṣe ibẹrẹ aye rẹ.
Nigba to wa lọmọ ọdun meji pere lo padanu baba rẹ, ti iya rẹ si tun dagbere faye lẹyin to pe ọmọ ọdun mẹwaa.
Lẹyin iku awọn obi rẹ, ẹgbọn iya rẹ kan to jẹ obinrin lo gba a tọ.
Ẹsin Musulumi ni Najeem Salan n ṣe.
Bi Najeem ṣe kawe
Najeem bẹrẹ ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ ni Ansar-U-Deen, to wa niluu Ejigbo laarin ọdun 1975-1981.
O kuro nibẹ lọ si Baptist High School, to wa ni ilu Ejigbo, yii kan naa.
Najeem tun lọ si Oyo State College of Arts and Science nibi to ti gba oye 'A level' laarin ọdun 1987-1989.
Lẹyin naa lo lọ si fasiti Obafemi Awolowo University, to wa niluu Ile Ife, nibi to ti kawe titi to fi gboye Ph.D ninu imọ oṣelu, Political Science.
Yatọ si awọn iwe to ka yii, o tun kọ awọn ẹkọ mii nilẹ Gẹẹsi, ilẹ Amẹrika, UAE, Brazil, eti bẹẹ bẹẹ lọ.
Irinajo rẹ ninu oṣelu

Oríṣun àwòrán, @Najeem Salaam
Najeem wọ inu oṣelu lasiko to wa nile ẹkọ fasiti ninu ẹgbẹ Association of Political Science Students.
Lọdun 2002, o dije fun ipo ni ijọba ibilẹ rẹ amọ o lulẹ. Nigba ti yoo di ọdun 2007, o dije du ipo gẹgẹ bii aṣofin nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, o si jawe olubori.
Nigba ti yoo di ọdun 2009, ile yẹ aga nidi rẹ latari pe ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu rẹ ko si lori iwe idibo lọdun naa lọhun, wọn tun ibo naa di amọ o lulẹ nigba ti ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan wọle.
Ni 2011, o dije du ipo nile igbimọ aṣofin naa lẹẹkeji o si wọle. Asiko naa di abẹnugan ile ọhun.
Ninu eto idibo ọdun 2015, o pada dije, o si wọle. O ṣe agbẹnusọ ile naa titi di ọdun 2018, eyii to sọ ọ ọkan lara awọn aṣofin to pẹ julọ ninu ile naa nipinlẹ Osun.
Wọn yan an sipo alaga ẹgbẹ Caretaker Committee of the Conference of Speakers of State Legislatures lọdun 2012.
Lẹyin naa lo di ọga agba ati adari ẹka Marketing and Business Development nileeṣẹ ijọba, Nigerian Communications Satellite Limite.
Afojusun rẹ fun ipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, Okiss Pixel
Orukọ ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ ọ si ni "Iwaloye."
Oun lo n dije du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ninu idibo gomina Osun ti yoo waye lọjọ Abamẹta ọsẹ yii.
Lara awọn nnkan to ni oun yoo gbajumọ ti oun ba gori itẹ gomina ipinlẹ Osun ni atunṣẹ eto ẹkọ, eto aabo to peye, idagbasoke ọrọ aje ipinlẹ Osun, idagbasoke eto ọgbin, igbayegbadun araalu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

























