Bukky Wright sọ̀rọ̀ lórí ikú Kola Oyewo àti Ogogo, bí wọn kò ṣe pe ọ̀pọ̀ àgbà òṣèré tó jìyà tíátà sí iṣẹ́ mọ́ àti ohun tí ìjọba le ṣe láti ṣèrànwọ́

Àkọlé fídíò, Ikú Kola Oyewo àti Ogogo dún mí, ohun tí mo fẹ́ kí ìjọba ṣe rèé láti ran àwọn òṣèré lọ́wọ́ fún ìdẹ̀rùn ọjọ́ alẹ̀ - Bukky Wright
Bukky Wright sọ̀rọ̀ lórí ikú Kola Oyewo àti Ogogo, bí wọn kò ṣe pe ọ̀pọ̀ àgbà òṣèré tó jìyà tíátà sí iṣẹ́ mọ́ àti ohun tí ìjọba le ṣe láti ṣèrànwọ́
Published

Awọn agba bọ, wọn ni oku n sunkun oku, akasọlori n sunkun ara wọn bẹẹ si ni bi a ba ku la n di ere, eeyan ko sunwọn laaye.

Eyi lo mu ki gbajumọ osere tiata lobinrin kan, Bukky Wright se n se idaro awọn agba ọjẹ meji lagbo tiata, ti wọn jẹ alajọsisẹpọ rẹ amọ ti wọn ti di ara ilẹ bayii.

Awọn agba ọjẹ mejeeji naa ni gbajumọ osere tiata, Kola Oyewo, ẹni to siwọ isẹ ni ọjọ Kejila osu Kefa ọdun 2026 lẹni ọgọrin ọdun tori aisan jẹjẹrẹ ile itọ.

Ẹni keji ni Taiwo Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo ẹni to jade laye lọjọ kẹtalelogun osu kẹjọ ọdun 2026 tori aisan jẹjẹrẹ lẹni ọdun mẹrindinlaadọta.

Bukky Wright, lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ, salaye irufẹ ajọsepọ to ni pẹlu awọn gbajumọ osere mejeeji naa.

Bakan naa lo tun sọ idi to se yẹ ki ijọba se iranwọ fawọn onitiata lori ipese ilera to peye, paapaa ni ọjọ alẹ wọn.

Bukky Wright wọ asọ Adire alawọ pupa ati dudu, o lo irun wiigi sori

"Ibanujẹ ọkan lo jẹ fun mi, iku Kola Oyewo ati Ogogo ba mi lojiji, tori ka ni Ogogo ti wa lori aisan tẹlẹ, boya..., bi o tilẹ jẹ pe n ko ro iku ro o"

Nigba to n sọrọ lori ajọsepọ to ni pẹlu oloogbe Kola Oyewo, Bukky wright sọ fun BBC News Yoruba pe ọpọ ere tiata ni oun ati oloogbe naa ti dijọ kopa ninu rẹ.

"Ibanujẹ ọkan lo jẹ fun mi ati pe iku awọn mejeeji ba mi lojiji, paapaa Ogogo, tori ka ni o ti wa lori aisan tẹlẹ, bi o tilẹ jẹ pe n ko ro iku ro o.

Ki ni yẹn ba mi lojiji debi pe n ko ri ara gba si, n ko le sọrọ, se ẹ mọ ki n kan sẹlẹ si eeyan, ko ma mọ nnkan ti mo le sọ tabi nnkan ti mo le se.

Emi ati uncle Kola Oyewo la dijọ se aimọye isẹ bii sinima Agogo Eewọ ati Saworo Idẹ nigba ti emi ati Ogogo naa ti dijọ se aimọye isẹ.

Koda, ọrọ naa ko ye mi, n ko mọ ohun ti mo le sọ."

"Ọpọ awọn eeyan maa n foju wo pe osere maa n ni owo rẹpẹtẹ amọ pupọ ninu awa osere, kii se tori owo la ti se wa, amọ tori ifẹ si isẹ naa, ko to di akoko yii ti owo ti wa ninu isẹ tiata"

Bakan naa ni Bukky Wright tun sọrọ nipa igbe aye awọn onitiata ati bi wọn se maa n pa awọn agba osisẹ, to ti jiya nidi isẹ naa ti, lai pe wọn sidi isẹ mọ.

"Ọpọ awọn eeyan maa n foju wo pe osere maa n ni owo rẹpẹtẹ amọ pupọ ninu awa osere, kii se tori owo la ti se wa.

Amọ tori ifẹ si isẹ naa la se darapọ mọ ere tiata, ko to di akoko yii ti owo ti wa ninu isẹ tiata.

A gba wipe ko si ẹni to fẹ sowo, ti ko fẹ jere, sugbọn ika ko dọgba, paapaa julọ, nigba ti awa bẹrẹ isẹ yii, ko si owo nidi rẹ.

Isin yii ni owo sẹsẹ n wa ninu isẹ tiata, wọn ko pe awọn gbalagba to fara jiya nidi isẹ yii sẹnu isẹ mọ.

Ti a ko ba si pe wọn si isẹ mọ, ki la fẹ ki wọn jẹ?"

"Mo rọ ijọba lati ba wa ṣe agbekalẹ banki onikolo ti awọn osere le maa da owo pamọ si diẹdiẹ, nigba ti wọn si ni eegun lati sisẹ"

Nigba to n sọrọ lori bi awọn osere tiata se le pọn omi silẹ de oungbẹ titi de ọjọ alẹ, Bukky Wright ke si ijọba lati se iranwọ fawọn osere nipa agbekalẹ awọn ilana kan.

Mo wa fẹ rọ ijọba lati ba wa gbe awọn ilana kan dide, bii agbekalẹ banki onikolo ti wọn le maa da owo pamọ si diẹdiẹ si nigba ti wọn si ni eegun lati sisẹ.

To ba di igba ti eegun ko si lati sisẹ mọ, owo yii yoo se pada lọ ko, lati fi gbọ bukata ọjọ alẹ wọn."

Bukky Wright wọ asọ lesi alawọ buluu ati gele rẹ

Ta ni Bukky Wright?

Oluwabukola Sekinat Ajoke Wright, ti ọpọ eeyan n pe ni Bukky Wright, ni wọn bi lọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹta ọdun 1965, iyẹn ọdun mọkanlelọgọta sẹyin.

Ọmọbibi ilu Abeokuta ni baba rẹ to jẹ ọmọlẹyin Kristi nigba ti iya rẹ jẹ musulumi.

Lẹyin ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, Bukky Wright lọ sile ẹkọ fasiti ilu Eko, o si gba oye imọ ijinlẹ lori ẹkọ nipa ọrọ aje.

Ọdun 1996 ni Bukky Wright bẹrẹ isẹ tiata , bo se foju han ninu ere Super Story pẹlu ileesẹ Wale Adenuga to n gbe ere tiata naa sita lori tẹlifisan.

O si ti kopa ninu ọpọ sinima lede oyinbo ati abinibi eyi to sọ ọ di gbajumọ osere.

Yatọ si ere tiata, Bukky Wright tun ti dipo dije fun ipo oselu ninu ẹgbẹ oselu Social Democratic Party (SDP) lọ sile asofin ipinlẹ Ogun labẹ idari Gomina Olosegun Osoba.

Bakan naa lo tun jẹ onisowo, to si jẹ oludari ileesẹ aransọ ati asaraloge kan.

Yoruba and English languages, including Wale Adenuga's Television series Super story.

Bukky Wright bimọ ọkunrin kan ti orukọ wọn n jẹ Eniola ati Gbenga, ti ọkan ninu wọn si ti se igbayawo, bi ọmọ kan.

Bukky Wright ti gba ami ẹyẹ lorisirisi ninu awọn sinima to ti kopa lagbo tiata, lara awọn ere naa ni:

Saworo ide (1999)

Agogo Eewo (2002) o se Tinuola

Above Love (2004)

Abeni (2006)

The Narrow Path (2006)

Outkast (2011)

Kodun Kopo Kope (KKK)

Arinzo (2013)

Gidi Blues (2016) o se iyaafin Kuti

Omotara Johnson

Unforgivable

Afefe Alaafia

Dugbe Dugbe

Nkem Temi

Ago Meje

Oko Nnene

Habitat

Red Hot (2013)[16]

Iyore (2014) o se olori Toyin Adekoya

When Love Happens (2014) o se iyaafin Laguda

Poison (2018) o se Sola

Special Jollof (2020)

Kadara (2022) o se Mama Shade

Mother-In-Law (2023) o se Madam Kola

Red Circle (2025)

Aso Ebi Diaries (2025)