Mọ̀ sí i nípa Ibikunle, Akọni Ìlú Ibadan tó jẹ́ Balogun kan ṣoṣo tó rẹ́yìn Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò

Ti a ba pe ori akọni, a o fi ida la ilẹ gaaraga, bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ri pẹlu Balogun Ibikunle, akọni ilu Ibadan to jagun to si kẹru ko ẹru.
Ko tii si Balogun kankan to rẹyin Aarẹ Onakakanfo ri ninu itan ilẹ Yoruba afi Balogun Ibikunle.
Onimọ nipa itan ilu Ibadan, Ọgbẹni Adewale Ibikunle, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC News Yoruba.
Awọn ẹbi sọ fun BBC Yoruba pe ''a bi Balogun Ibikunle ni ilu Ijado, baba rẹ ni a n pe ni Ogunrounbi, iya rẹ si n jẹ Aina Ewedoyin to jẹ ọmọba ilu Ogbomoso.
Gẹgẹ bi itan ṣe fi idi rẹ mulẹ, wọn maa n pe Ibikunle si ogun kaakiri laye ọjọun, koda, Alaafin Oyo naa maa n pe si ogun.
''O wa ṣakiyesi wi pe o maa n saba gbe ogun lọ si ilu Ibadan nibi ti ẹgbọn rẹ n gbe.
Ọdọ ẹgbọn rẹ yii to n jẹ Tooki ni Ibikunle de si, Tooki yii si ni wọn n pe ni Onibudo.
Ni ọdọ Tooki ni Ibikunle wa ti gbogbo ilu fi mọ pe jagunjagun ni i ṣe.
Lọpọ igba ti o ba tẹle Tooki jade lawọn eeyan maa n sọ pe ki wọn fi ọwọ wọ Tooki tori kiniun wa pẹlu rẹ iyẹn Ibikunle, ohun to bi kiniun Onibudo ree,'' Ọgbẹni Adewale Ibikunle lo sọ bẹẹ.
''Agbala Ibikunle ju oko baba ẹlomiran lọ''
Lasiko Balogun ni wọn mọ odi yika ilu Ibadan lati daabo bo ilu naa.
Odi Ibikunle bẹrẹ lati agbegbe Oke Mapo lọ si ọna ibode, o si tun lọ si Kudeti.
Mogaji ile Balogun Ibikunle sọ pe awọn araalu kan tako awọn to mu ẹsun kristẹni wa silu Ibadan.
O ni Ibikunle lo sọ pe ki awọn Babalawo ṣe ayẹwo ọrọ naa bo ya nnkan ti yoo mu ewu dani fun ilu ni.
Lẹyin tawọn alawo wo o tan ni wọn sọ pe ki wọn fun wọn laye, bayii ni ẹsin kristẹni ṣe wọ ilu Ibadan.
Ibikunle ja ogun Ijaye, o si tun ja ogun Fulani niluu Osogbo, bakan naa ni o tun ja ogun Ijebu Ẹrẹ, ogun Ara, ogun Kutujẹ eyi ti i ṣe ogun ti Ibikunle ja gbẹyin ki ọlọjọ to de.
Balogun Ibikunle ko ku soju ogun, oju oori rẹ si wa nile di oni.
Ibikunle nikan ni Balogun to rẹyin Kurumi, Aarẹ ọna Ijaye.
Itan tun fidi rẹ mulẹ pe ko si ogun ti Ibikunle ja ti ko bori.
Mogaji ile Balogun Ibikunle fikun ọrọ rẹ pe agbala Ibikunle ju oko baba ẹlomiran lọ.
O ni ilẹ Balogun Ibikunle pọ yanturu kaakiri ilu Ibadan tori alagbara ni.



























