Ẹ̀sùn jìbìtì N69m mí-ìn tún wọlé tọ Blessing CEO, yàtọ̀ sí ti 36m tí wọ́n kọ́kọ́ torí rẹ̀ fi pamọ́ sí àhámọ́

Blessing Nkiruka Okoro (Blessing CEO)

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àkọlé àwòrán, Blessing Nkiruka Okoro (Blessing CEO)
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajumọ sọrọsọrọ ori ayelujara, Blessing Nkiruka Okoro tawọn eeyan mọ si Blessing CEO ni ọmọ ti wọn n sọ lọwọ ni kootu bayii.

Idi ni pe igbẹjọ meji ọtọọtọ waye fun un lọjọ kan ṣoṣo, lori ẹsun jibiti ọtọọtọ ti o jọra wọn.

Ṣaaju ni iroyin ti jade lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, pe Adajọ ti fi aaye beeli silẹ fun Blessing CEO lori ẹsun jibiti miliọnu mẹtadinlogoji (36m) to n jẹjọ rẹ.

Amọ lọjọ yii kan naa ni igbẹjọ tuntun lori ẹsun jibiti mi-in tun waye fun Blessing, niwaju Adajọ R.A Oshodi, nibi ti wọn ti fẹsun jibiti N69.15 miran kan sọrọsọrọ yii, niluu Eko kan naa ti igbẹjọ akọkọ ti waye.

Bawo ni ọrọ ẹsun Jibiti N69.15 ṣe tun jẹ?

Ajọ Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) to n ba Blessing ṣe ẹjọ lori ẹsun 36m owo ile ti wọn ni ki i ṣe tirẹ to si gbowo lori rẹ, naa lo tun gbe e lọ si kootu lori ẹsun tuntun yii.

Nibi igbẹjọ tuntun to waye nile ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun ọtọ bii eyi, n'Ikeja, ni wọn ti ka ẹsun onikoko meji mi-in si Blessing CEO lẹsẹ.

Awọn ẹsun naa bi wọn ṣe ka a ni gbigba owo lọwọ eeyan pẹlu ẹtan ati ole jija.

Gẹgẹ bi EFCC ṣe wi, wọn ni Blessing CEO gba N69.15 million lọwọ Hope Chiropractic Health Clinic Limited,pẹlu ẹtan.

EFCC ṣalaye pe Blessing sọ fawọn to gbowo yii lọwọ wọn pe oun loun ni ile kan to wa lojule Kin-in-ni, Opopona Tunbosun Osobu, Lekki, niluu Eko.

Ọdun marun-un lo ni wọn yoo fi lo ile naa gẹgẹ bi adehun.

Ẹsun keji ti wọn fi kan an ni pe o da owo naa si apo ara rẹ, o si fi ṣe ara rindin lẹyin to mọ pe ile onile lo gbowo rẹ.

Laaarin ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta ọdun 2025 ni wọn ni Blesssing CEO huwa eke naa, eyi to lodi sofin ilẹ Naijiria.

Blessing loun ko jẹbi

Nigba to n dahun ibeere kootu, pe ṣe o jẹbi ẹsun tuntun ti wọn fi kan an yii, Blessing CEO ni oun ko jẹbi.

Lẹyin to ni oun ko jẹbi, Agbefọba C.C. Okezie, beere fun ọjọ igbẹjọ miran, ki kootu si fi olujẹjọ si ahamọ EFCC, titi ti yoo fi yọju sile ẹjọ giga n'Ikoyi, lori ẹsun jibiti mi-in to tun ni lọjọ kẹwaa oṣu yii.

Adajọ pada paṣẹ pe ki wọn fi Blessing si ahamọ EFCC, o si sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun oṣu Keje ọdun 2026.

Nigba naa lo ni wọn yoo sọrọ lorii gbigba beeli rẹ ati itẹsiwaju ẹjọ naa.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ẹsun 36m ti Blessing n jẹjọ rẹ ṣaaju, owo ti wọn ni o gba lọwọ obinrin kan, Ifeyinwa Nonye Okoye, to waye lọjọ Iṣẹgun kan naa, Adajọ D.I Dipeolu fun sọrọsọrọ naa ni anfaani beeli pẹlu miliọnu mẹwaa naira.

O ni awọn oniduuro naa gbọdọ fi iwe ẹri to fi han pe wọn niṣẹ lọwọ han.

Wọn gbọdọ fi nọmba BVN, NIN, nọmba ẹrọ ibanisọrọ wọn to jẹ oujulowo, iwe irinna, iwe owo ori sisan ti wọn san lati ọdun meji sẹyin, ati fọto pelebe wọn mẹfa silẹ fun kootu.

Ọkan lara awọn oniduuro naa si gbọdọ jẹ mọlẹbi rẹ bi Adajọ ṣe paṣẹ.

Ẹ o ranti pe Blessing n jẹjọ ẹsun yii latari ile kan to ni oun loun ni i, ni Lekki, ipinlẹ Eko.

EFCC sọ pe o fi ẹtan gba 36m lọwọ obinrin kan to n jẹ Ifeyinwa Nonye Okoye, pẹlu ẹtan pe o ya a nile naa gbe.

Ṣugbọn eyi ko pada ri bẹẹ.

Blessing ti n da owo naa pada bi agbẹjọro rẹ ṣe wi, bo tilẹ jẹ pe o tun ni oun ko jẹbi ẹsun yii.

Gbogbo eyi n waye lẹyin ikede aisan jẹjẹrẹ ọyan onipelele kẹrin (stage 4) ti Blessing kede pe o n ba oun ja.

Ikede rẹ igba naa lo mu kawọn ọmọ Naijiria kan dawo fun un loṣu diẹ sẹyin.

Ikede arun jẹjẹrẹ naa tun pada ja sirọ, ọpọ eeyan lo si binu si I nigba naa, bawọn mi-in ṣe ni ko da owo awon pada kia.

Sọrọsọrọ yii pada tọrọ aforiji, bo tilẹ jẹ pe ṣaaju lo ti kọkọ ni oun ko fipa gbowo lọwọ awọn to dawo foun.