Àwọn ọmọdékùnrin méjì ṣekúpa èèyàn mẹ́ta nínú mọ́ṣáláṣí, pa ara wọn lẹ́yìn rẹ̀

Awọn obinrin mẹta ti wọn di mọra wọn

Oríṣun àwòrán, EPA

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ọdọkunrin meji kan ti lọ ṣẹkọlu si Mọṣalaṣi kan ni San diego, California nibi ti wọn ti yinbọn fun ọkunrin mẹta kan, ki wọn to pa ara wọn.

Ni owurọ ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin bii wakati ti meji ti iya ọkan ninu awọn ọmọ naa pe awọn ọlọpaa pe ọmọ oun ti sa kuro nile pẹlu ọrẹ rẹ kan to si jọ pe wọn fẹ lọ pa ara wọn ni.

Ọlọpaa ti n wa awọn ọmọ naa ko to di pe ikọlu waye si mọṣalaṣi San Diego, ti wọn si ba awọn tawọn ọmọ naa yinbọn fun niwaju mọṣalaṣi naa pelu oju ọgbe ọta ibọn lara.

Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa gba ipe pe wọn gburoo ibọn lati inu ọkọ kan tawọn ọlọpaa si ba oku awọn ọkunrin mejeeji naa, ẹni ọdun metadinlogun ati ẹni ọdun mejidinlogun ninu ọkọ kan nibi ko jin pupọ si mọṣalaṣi naa.

Lara awọn to jade laye nibi ikọlu naa ni ẹṣọ aabo kan to n ṣiṣẹ ni mọṣalaṣi naa, ẹni ti wọn lo ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe ikọlu naa ko pọ ju bẹẹ lọ.

Ọga ọlọpaa San Diego, Scott Wahl ni ẹṣọ aabo naa huwa akin pẹlu bo ṣe da aabo bo ẹmi ọpọ eeyan.

Awọn alaṣẹ ko i tii darukọ awọn mẹta tompadanu ẹmi wọn ninu ikọlu naa amọ eeyan kan to mọ ẹṣọ aabo to jade laye naa ri sọ fun ileeṣẹ iroyin CBS pe ọmọ mẹjọ lo fi saye.

Awọn oluwadii sọ pe wọn ko le fidi ikọlu naa mulẹ amọ igbagbọ wa pe o le jẹ ikorira nitori mọṣalaṣi naa, eyi to jẹ mọṣalaṣi to tobi julọ ni San Diego ati nnkan ti ọkan lara awọn afurasi naa maa n kọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nnkan bii wakati meji ki ikọlu naa to waye ni iya ọkan lara awọn afurasi naa pe awọn ọlọpaa pe ọmọ oun ti ko lara awọn ibọn oun ati ọkọ ti oun ko si mọ ibi ti wọn n lọ.

O ni ọmọ oun ati eeyan kan ni wọn jọ kuro nile ti wọn si wọ aṣọ awọn ologun.

Wahl sọ pe awọn ọlọpaa ko ri iwa tawọn ọmọkunrin naa hu bii eni to fẹ pa ara wọn bikoṣe wọn huwa ikorira ati pe iwe ti wọn kọ kalẹ ṣafihan ikorira.

Awọn oluwadii lọ sile ẹkọ ti ọkan lara awọn afurasi naa n lọ ko to jade laye ati ile itaja ti wọn gbe ọkọ iya rẹ to gbe jade si.

Lasiko tawọn ọlọpaa n ba iya ọmọ naa sọrọ lọwọ ni wọn gburoo ibọn ti awọn ọdọkunrin naa fi pa ara wọn.

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ kan sọ fun CBS pe oun gbọ to iro ibọn ọgbọn, ohun to farapẹ kiki ibọn lera wọn.

O ni ohun kọkọ gbọ iro ibọn pupọ ti oun ko si gbọ nnkankan mọ fun bii iṣẹju die ki oun to tun gbọ iro ibọn naa lera wọn pada.

Ẹni naa sọ pe oun n jẹun ọsan lọwọ ni oun gburoo ibọn naa, ti oun si sare pe 911 tawọn ọlọpaa si de laarin iṣẹju marun-un si mẹwaa.

Imam Taha Hassane, adari mọṣalaṣi San Diego sọ pe o jẹ ohun to buru lat ṣe ikọlu si mọṣalaṣi, pe ile ijọsin ni kii ṣe oju ogun.

Awọn musulumi ni wọn n gbaradi fun ọdun ileya, eyi ti yoo waye ni ọse to n bọ.

Gomina California, Gavin Newsom ninu atẹjade kan to fi lede ni ikọlu to waye naa jẹ ohun to buru paapaa nile ijọsin tawọn ẹbi ti n pejọ lati ṣe ijọsin.

O ni ipinlẹ naa ko ni fi aaye gba iwa igbeṣumọmi tabi ṣiṣe iwa ipa sawọn eeyan nitori ẹsin.

Nigba to n sọrọ lori ikọlu naa, Aarẹ Donald Trump ni iṣẹlẹ to buru gidi ni to si ni awọn maa ṣe agbeyẹwo iṣẹlẹ naa daadaa.