Ṣé lóòótọ́ làwọn agbébọn tún yawọ ìlú Ogbomoso? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Oyo Police/X
Yoruba ni ina eṣiṣi kii joni ni ẹẹmeji, eni ti Sango ba si toju rẹ ja ko ni maa ba wọn bu ọba Koso.
Bẹẹ ni ọrọ ri fun awọn ara ilu Ogbomoso ati agbegbe rẹ paapaa awọn ile ẹkọ to wa ni awọn ilu bi wọn ṣe ni kawọn akẹkọọ maa lọ sile ti wọn si ti gbogbo ile ekọ wọn pa.
Igbesẹ yii ko ṣẹyin bi awọn kan ṣe gbe iroyin pe niṣe ni awọn agbegbọn tun ti yawọ ilu Ogbomoso ati ilu Ajaawa ti wọn si tun n ṣọṣẹ.
Eyi da ibẹrubojo sọkan awọn araalu nitori ni ọjọ aje to kọja yii ni awọn yabọ ile ẹkọ meji ni agbegbe yii ti wọn si ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ gbe lọ.
Akoroyin BBC News Yoruba to wa ni ile ẹkọ kan nilu Ogbomoso lati lọ ṣe ifọrọwanilẹnuwo sọ pe niṣe ni ọga agba ile ẹkọ sadede ni kawọn akẹkọọ maa lọ sile, ti wọn si n sare ti gbogbo ilẹkun ile ẹkọ naa.
O ni eti ko ṣẹyin bi iroyin ṣe kan olukọ agba naa leti pe awọn agbebọn tun ti n ṣọṣẹ laaarin igboro ilu Ogbomoso ati ilu Ajaawa.
O ni ko pẹ sigba naa ni awọn obi ati alagbatọ n sare wa sile ẹkọ naa lati wa mu awọn ọmọ wọn nitori ibẹru awọn ajinigbe.
Lẹyin naa ni akọroyin wa tun lọ kaakiri awọn ile ẹkọ kọọkan ni ilu Ogbomoso lati mọ ohun to n ṣẹlẹ lawọn ile ẹkọ naa.
Laran awọn ile ẹkọ ti a ṣe abẹwo si ni ile ẹkọ Girama Ogbomoso, Ile ẹkọ alakọbere Ebenezer to wa ni agbegbe Okelerin, ile ẹkọ Millennium, Ogbomosho High School ati awọn Ile ẹkọ miiran.
Niṣe ni ọpọ awọn ile ẹkọ yii w ani titipa nigba ti a fi maa debẹ, tawọn mii si n mura lati ti ile ẹkọ wọn.
Amọ awọn alaṣẹ ti wa jiyan iroyin pe agbebọn kankan ko wọ inu igbooro Ogbomoso tabi Ajaawa lati ṣọṣẹ, pe iroyin ofege lasan ni.
Awon oṣiṣẹ Ajọ NSCDC ni wọn ri kii ṣe awọn afurasi agbebọn
BBC News Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lati mọ nipa ohun to ṣẹlẹ lori iroyin tawọn eeyan n sọ ati idi ti tawọn eeyan fi n sọ pe awọn agbebọn tun ti wọlu.
Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Oyo, Ayanlade Olayinka ṣalaye pe ikọlu awọn agbebọn to ṣọṣẹ lọjọ Ẹti to kọja ni ko i tii tan lara awọn eeyan.
O sọ pe aawọn akẹkọọ ile ẹkọ Girama Areago lọ ri awọn oṣiṣẹ ajọ NSCDC kan lẹyin ile ẹkọ wọn sugbọn tawọn eeyan naa ṣe ajoji si wọn, ti wọn si figbe ta.
O ni eyi lo fa a ti awọn kan ninu wọn ṣe ro wi pe awọn agbebon lo tun wa ti wọn si n tan iroyin naa tawọn eeyan sis are gba a mọ wọn lọwọ.
Ayanlade ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ajọ NSCDC lati ilu Ilorin lo lọ ṣe ajọyọ ọjọ ibi fun ọkan lara wọn ni agbegbe Areago eyi to ṣe ajoji sawọn akẹkọọ naa ti wọn si fi wọn pe awọn ajinigbe agbebon.
O fi kun pe lẹyin naa ni ifanfa waye laaarin awọn oluko atawọn alejo naa eyi to mu ki awọn akẹkọọ fọn si igboro, ti wọn si tan iroyin ofege pe awọn agbebọn lo kọlu ilu wọn.
O ni awọn ọlọpaa ti wa si fọn si igboro ilu Ogbomoso lati fi ọkan awọn ara ilu balẹ pe ko si ohun to jọ ikọlu awọn agbebọn ni ilu naa.
'A rọ awọn akẹkọọ lati pada sile ẹkọ'
O rọ awọn eeyaan lati maa fidi iroyin mulẹ daadaa ki wọn to maa tan iroyin ka nitori iroyin ofege le ba ohun to pọ jẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Akọwe agba fun eto ẹkọ ẹkun akọkọ nilu Ogbomoso, Ogbeni Paul Oyedokun ti rọ awọn akẹkọọ lati pada si ẹnu ẹkọ wọn pe ko si ohun to jọ ikọlu awọn ajinigbe ni ilu Ogbomoso
Oyedokun ni ko si aawọ kankan ninu ilu Ogbomoso, oni iroyin ofege yii le mu ki awọn to ni ẹjẹruru padanu ẹmi wọn, o rọ awọn to n gbe iroyin ofege lati dẹkun ṣiṣe bẹẹ.
Nigba ti o n sọrọ lori eto aabo kaakiri ile ẹkọ, o ni ijọba n ṣe ohun gbogbo lati ri wi pe gbogbo ile ẹkọ niluu Ogbomosho ati agbegbe rẹ ni aabo to daju wa fun, to si rọ awọn obi lati jẹ ki awọn ọmọ wọn pada si ile ẹkọ ki eto ẹkọ le tẹsiwaju bo ṣe yẹ.



























