Hantavirus: Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn tuntun tó ṣẹ́yọ, àti bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Eeyan mẹta lo ti padanu ẹmi wọn bayii lẹyin ti wọn lugbadi arun hantavirus to bẹ silẹ ninu ọkọ oju omi kan to kọja ninu omi okun.

Ajọ WHO to n mojuto ọrọ eto ilera lagbaaye lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Ajọ WHO ni awọn ti ṣawari ẹnikan to ti ko arun naa, nigba tawọn tun fura si eeyan marun un mii to ṣee ṣe wi pe wọn ti ko arun ọhun.

WHO sọ fun BBC pe ''iwadii kikun si n lọ lọwọ lori awọn eeyan tawọn fura si pe wọn ni arun ọhun.''

Iroyin ajakalẹ arun naa jẹ jade lati inu ọkọ oju omi MV Hondius to rinrin ajo lati orilẹede Argentina si Cape Verde.

Ohun ti a mọ nipa arun hantavirus ree

Aarun hantavirus jẹ agbarijọpọ awọn kokoro aifojuri to maa n wa lara awọn eku.

Awọn eeyan maa n ko arun yii nigba ti wọn ba mi eemi idọti to wa lori igbẹ irufẹ awọn eku bẹẹ sinu.

Ajọ CDC to n ri si ọna lati dẹkun ajakalẹ arun sọ pe awọn eeyan maa n ko arun naa lati ibi itọ, igbẹ ati itọ ẹnu iru awọn eku to ba larun naa lara.

Kii saba ran nipa ki eku ge eeyan jẹ.

Hantavirus le jẹ ki o maa rẹ eeyan, o si tun le jẹ ki eeyan ni aisan iba.

Nigba to ba ya ni ooyi yoo maa kọ iru eeyan bẹẹ ti yoo si tun maa ni ẹfọri.

Ajọ CDC sọ pe ida 38% awọn eeyan ti ko ba ti le mi daadaa mọ latari arun yii ni wọn maa n ku.

Hantavirus tun maa n jẹ ki eeyan ni aisan iba to n maa ṣakoba fun kindinrin.

Ifunpa iru eeyan bẹẹ tun le lọ silẹ, o le maa da ẹjẹ ninu ara, kindinrin iru eeyan bẹẹ tun le daṣẹ silẹ lojiji.

Eeyan meloo lo ti lugbadi arun hantavirus lagbaaye?

Eeyan bii ẹgbẹrun lọna aadọjọ (150,000) eeyan lo maa ni arun yii lọdọọdun.

Amọ, nilẹ Yuroopu ati Asia ni o ti wọpọ julọ lagbaaye.

O le ni idaji awọn eeyan to n karun naa to maa n wa lati orilẹede China nikan.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe laarin ọdun 1993 si 2023, eeyan ti ko din ni 890 lo larun naa lorilẹede Amẹrika.

Amọ, Seoul virus to jẹ irufẹ ọkan lara ẹda arun hantavirus eyi to maa n wa lara awọn eku lorilẹede Norway wa nibi gbogbo kaari aye.

Bawo ni wọn ṣe n ṣetọju arun hantavirus?

Ko si ọna kan gboogi ti wọn maa n gba lati ṣetọju ẹni to ba ko arun hantavirus.

Ajọ CDC sọ pe awọn eeyan le lo afẹfẹ ''oxygen'' ati oogun to n koju kokoro lati fi ṣe itọju ẹni to ba ni iru arun yii.

Awọn ti arun naa ba ti wọ lara le lọ si ile iwosan fun itọju ni wọọdu pajawiri.

Ajọ naa wa rọ awọn eeyan lati jina si ẹnikẹni to ba ti fara kan eku lati le dẹkun arun ọhun.

CDC tun rọ awọn eeyan lati di ibi gbogbo ti eku le gba wọle wọn.

Bakan naa ni ajọ ọhun tun gbawọn eeyan ni imọran wi pe ki wọn maa wọ ibọwọ ati iboju ti wọn ba n gba igbẹ eku ki wọn ma ba lugbadi arun naa.