You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Owó epo tó lọ sókè lọ́jà àgbáyé ṣàkóbá fún owó lítà epo ní Nàíjíríà, bí Trump ṣe ń tẹ̀síwájú láti dí epo Iran mọ́lé
Owo epo rọbi tun ti gbẹnu soke lọja agbaye lẹyin ikede pe Amẹrika tun ti n gbaradi lati tẹsiwaju pẹlu bi wọn ṣe di epo Iran mọle nitori Strait of Hormuz.
Epo rọbi Brent crude wọ $119 agba kan ni irọlẹ ọjọru, eyi to jẹ alekun ida meje ni ọjọ kan ṣoṣo lati ibẹre oṣu yii.
BBC ri mọ pe awọn alaṣẹ lẹka ohun amuṣagbara to fi mọ adari ileeṣe Chevron, Mike Wirth lọ ṣepade pẹlu Aarẹ Donald Trump ni ọjọ Iṣẹgun lati jiroro lori awọn ọna ti wọn fi maa mu adinku ba ipa alekun naa maa ni lori awọn araalu.
Awọn oniṣowo epo gba pe ipade naa lo jẹ ami pe o ṣeeṣe ki Trump tẹsiwaju lati tẹsiwaju pelu didi Strait of Hormuz lati ma fi aaye gba epo Iran lati gba ọna naa kọja.
Lara ohun ti wọn tun jiroro le lori ni ohun to n ṣẹlẹ ni Venezuela, afẹfẹ gaasi atawọn mii gẹgẹ bi oṣiṣẹ White House kan ṣe sọ.
Ipade yii yatọ si iroyin ti Wall Street Journal gbe pe Trump ti sọ fun awọn eeyan rẹ lati gbaradi lati tẹsiwaju didi awọn oju omi Iran mọle lojuna ati mu ikurẹtẹ ba eto ọro aje Iran.
Iran naa ni awọn ko ni fi aaye gba ki ọkọ oju omi kankan gbe epo gba Strait of Hormuz kọja latari bi US ṣe di awọn mọle ati ogun to n gbe ti awọn.
Lati igba ti Amẹrika ati Israel ti n gbogunti Iran ni owo epo ti n gbẹnu soke latari bi Strait of Hormuz to jẹ ọna kan ti w ani titi pa latari ogun naa.
Iran gbegi dina awọn gbigbe epo gba Strait of Hormuz, ori omi ti wọn n gbe ida ogun gbogbo epo agbaye gba.
Ṣaaju ni ibẹrẹ oṣu yii ni Iran ṣekilọ pe ọkọ agbepo to gbiyanju lati gba ori omi naa kọja ni wọn maa ṣe ikọlu si.
Bakan naa ni Amẹrika naa kede pe awọn ọmọ ogun ohun maa da ọkọ to bag be epo lati Iran pada, tawọn ko ni jẹ ko gba oju ọna naa kọja.
Iwadii BBC Verify fi han pe ọkọ oju omi Iran mẹrin lo gba oju ọna naa kọja leyin ti Amẹrika se wọn mọle.
Eto ọrọ aje agbaye ti di akurẹtẹ bi gbogbo nnkan ṣe ti n gbowo lori, ti wọn ko si ri ọja ko lọ silẹ okeere mọ
Ogun naa ti wa mu kialekun ba owo epo rọbi ni ọja agbaye.
Amọ lẹyin ti wọn kede didawọ ogun duro fun igba kan na laaarin Lebanon ati Israel, owo epo ja walẹ lọja agbaye ati nigba ti Amẹrika ati Iran naa dawọ ogun duro diẹ.
Amọ lati bii ọjọ mejila sẹyin bayii ni owo ti tun n lọ soke sii bi Amẹrika ṣe tẹsiwaju didi epo Iran mọle.
Eto ọrọ aje lo ti n koju ikurẹtẹ bi gbogbo nnkan ṣe ti n gbowo lori, ti wọn ko si ri ọja ko lọ silẹ okeere mọ.
Ọwọngogo ti lekun pẹlu ida aadọta gẹgẹ ajọ oluṣiro Iran ṣe gbe jade.
Ni ọsẹ to kọja ni ijọba ni Iran sọ pe awọ eeyan to le ni miliọnu meji ni wọn ti padanu iṣẹ wọn.
Ile ifowopamọ agbaye ti fojusun pe o ṣeeṣe ki owo gbẹnu soke pẹlu ida mẹrinlelogun ni ọdun 2026 ti ogun Iran b awa sopin ni oṣu Karun-un.
Owo epo bẹntiroolu tun gbẹnu soke ni Naijiria
Ni Naijiria ẹwẹ, ileeṣẹ ifọpo Dangote ti mu alekun ba iye ti wọn n ta bẹntiroolu pelu naira marundinlọgọrin, N75.
Ni ọjọru ni ikede naa jade pe owo epo yoo tun gbenu soke di N1,275 lati N1,200.
Lati igba ti Amẹrika ati Israel ti n gbogunti Iran, eyi to ṣe idiwọ fun epo lọja agbaye ni epo bẹntiroolu naa ti n gbẹnu soke ni Naijiria.
Bakan naa ni wọn tun ni Dangote ṣe idaduro tita epo sita fun igba kan na.