"Ìdí rèé tí mo ṣe fi àkàrà òyìnbó mọ ṣọ́ọ̀ṣì kàtídírà ńlá, èyí tó jẹ́ ìyanu fún ọ̀pọ̀ èèyàn"

"Ìdí rèé tí mo ṣe fi àkàrà òyìnbó mọ ṣọ́ọ̀ṣì kàtídírà ńlá, èyí tó jẹ́ ìyanu fún ọ̀pọ̀ èèyàn"

Se ẹ gbagbọ pe akara oyinbo lasan ni aworan ile ijọsin ti ẹ n wo nisalẹ yii?

Bẹẹ ni, akara oyinbo ni wọn fi se agbekalẹ aworan ile ijọsin naa, tii se ijọ onitẹbọmi akọkọ nilu Ogbomọso eyi ti obinrin kan se lasiko ajọdun ijọ naa.

Se ni obinrin to se akara oyinbo ọhun, Boluwatife Adewuyi, se akara oyibo to jẹ aworan ile Katidira fun ijọ naa, eyi to n se ọpọ eeyan ni haa-hii.

Bawo ni obinrin naa ti se e, ki lo sun de idi rẹ, eelo lo na, ati pe ki lo sun de idi sise akara oyinbo?

BBC News Yoruba tọ Boluwatife Adewuyi lọ, o si sọrọ nipa irinajo aye rẹ ati bo se se akara oyinbo onile ijọsin awosifila naa.

"Ọmọ ọdun meje ni mo wa nigba ti baba mi ku, mama mi lo tọju wa dagba, ati lọ sile ẹkọ, ati jẹun ati se ohun gbogbo di inira"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Boluwatife salaye irinajo aye rẹ ati ohun to gbe de idi sise akara oyinbo ta.

"Ọmọ ọdun meje ni mo wa nigba ti baba mi ku, mama mi lo tọju wa dagba, ati lọ sile ẹkọ, ati jẹun ati se ohun gbogbo di inira.

Mama mi ko se isẹ kan to lowo lori tori naa ni awọn inira yii se wa, awọn idojukọ naa si lo jẹ ki emi naa tete jara mọ ọrọ aye mi.

Lati ilẹ ni mo ti mọ pe maa sisẹ, ki emi naa le jẹ eeyan.

Ọpọlọpọ isẹ ni mo ti se, nigba ti mo wa nile ẹkọ giga, mo maa n ta nnkan jijẹ bii worobo, bisikiiti, suuti, ti mo fi maa n ba aini awọn akẹkọọ akẹẹgbẹ mi pade.

Mo maa n ri owo tọrọ-kọbọ nigba yẹn lati fi tọju ara mi amọ nigba ti a ba wa lẹnu isinmi nile ẹkọ, n kii ni owo lọwọ.

Eyi lo fun mi ni ero lati pinnu pe ki n ro ohun miran ti mo le maa se, paapaa ti yoo ma mu owo wa, nigba ti ile ẹkọ ba pari.

Idi niyẹn ti mo se kọ isẹ sise akara oyinbo lọna ati nisẹ lọwọ."

"Lasiko kan, mo ni n ko se keeki katidira mọ, awọn eeyan ti mo ti sọ fun tẹlẹ lo se koriya fun mi lati se irufẹ akara oyinbo naa."

Bakan naa ni Boluwatife sisọ loju rẹ pe ọdun 2020 ni oun gbe igba sise akara oyinbo yii nigba ti arun Coronavirus wa, ti awọn ko si ni anfaani lati lọ sile ẹkọ.

"Mo bẹrẹ diẹ diẹ amọ ti mo ba ni owo, maa ra awọn nnkan niwọn, niwọn.

Ọpọlọpọ idanilẹkọ ni mo se lori itakun agbaye nipa sise akara oyinbo, mo si tun lọ fun idanilẹkọ nipa rẹ nilu Eko, Ibadan ati Osogbo lati mọ si nipa rẹ tori n ko fẹ tọrọ jẹ.

Mo gbagbọ pe ohun ti eeyan ba fi ero si, o maa se, idi ree to fi seese fun mi lati fi akara oyinbo mọ sọọsi katidiral Oke Elerin lasiko ajọdun."

Nigba to n salaye bi ero naa se wa sọkan rẹ, Bolutife ni oun ni awọn eeyan gidi lẹgbẹ, ti ohun si fi ero naa to wọn leti.

"Akọkọ, mo sọ fun iya mi, ọrẹ mi ati ọrẹ ẹgbọn mi, ti gbogbo wọn si gbaruku ti mi.

Igba kan tiẹ wa, ti mo sọ pe n ko se mọ awọn eeyan ti mo ti sọ fun yii ni wọn se koriya fun mi lati se irufẹ akara oyinbo naa."

Alufa ijọ salaye bi akara oyinbo naa se kamọmọ si

Nigba toun naa n ba BBC News Yoruba sọrọ, Olusoaguntan sọọsi ijọ Onitẹbọmi akọkọ nilu Ogbomoso, to wa ni Oke Elerin, Alufa Victor Oyelowo salaye pe akara oyinbo naa kamọmọ.

"Nigba to kọkọ gbe akara oyinbo naa de, gbogbo awa ti a wa nibẹ lo ya lẹnu.

Keeki naa ga, o si tobi eyi si jẹ iwuri pe ọkan ninu awọn ọdọ lo se eleyi.

Bolu ni igbakeji oludari fawọn ọdọ, ohun to si se yii ya wa lẹnu tori owo nla lo na lati se akara oyinbo naa.

A si gbadura fun lọtọ lori ohun ara to se naa."