Ǹ jẹ́ ẹ mọ nípa Ọdún Ẹlẹ́gba Èjìwà l‘Eko níbi tí takọ-tabo kìí wọ aṣọ tàbí bàtà?

Àkọlé fídíò, Ǹ jẹ́ ẹ mọ nípa Ọdún Ẹlẹ́gba Èjìwà níbi tí takọ-tabo kìí wọ aṣọ tàbí bàtà?
Ǹ jẹ́ ẹ mọ nípa Ọdún Ẹlẹ́gba Èjìwà l‘Eko níbi tí takọ-tabo kìí wọ aṣọ tàbí bàtà?

Idalu ni iselu, agbegbe tabi ilu kọọkan si lo ni ise ati asa tireẹ.

Bẹẹ lo ri ni agbegbe Iru ti adugbo Ero wa, nibi ti wọn ti n se ọdun Ẹlẹ́gba Èjìwà.

Ki lo n jẹ ọdun Ẹlẹgba Ejiwa, asiko wo ni wọn n se e?

Ki lo de ti takọ tabo kii fi wọ asọ lasiko ọdun naa, ki si ni pataki ọdun yii?

BBC News Yoruba wa nibi Ọdun Ẹlẹgba Ejiwa fun ti ọdun 2026 lati wa idahun sawọn ibeere yii, alaye ree.

Awọn obinrin ro iro funfun mọ aya wọn, wọn joko silẹ lasiko ọdun Ẹlẹgba Ejiwa

"Lasiko ọdun Ẹlẹgba, obinrin ko gbọdọ wọ bata, ti wọn yoo ro asọ de igba aya, tawọn ọkunrin yoo si ro asọ mọ idi lai wọ bata"

Lasiko ọdun Ẹlẹgba Ejiwa yii, BBC News Yoruba se akiyesi pa ọpọ awọn olujọsin to wa nibẹ ni ko wọ asọ soke aya wọn.

Awọn ọkunrin ro iro mọ idi, ti wọn si si igẹ aya wọn silẹ, nigba ti awọn obinrin ro iro mọ aya lai wọ asọ kankan soke aya wọn.

Nigba to n sọrọ lori idi ti eyi se ri bẹẹ, Oniru ti ilu Iru nipinlẹ Eko, Ọba Omogbolahan Lawal ni Ido ni awọn olujọsin ti maa n kọkọ bẹrẹ ọdun naa.

"Ido ni Ọlọfin to jẹ babanla wa wa, ibẹ si la ti kọkọ se ọdun Ẹlẹgba Ejiwa akọkọ.

A ni awọn eewọ fun ẹnikẹni to ba maa wọ agbo Ẹlẹgba.

Fun awọn obinrin, wọn ko gbọdọ wọ bata, ti wọn yoo si ro asọ de igba aya wọn.

Amọ to ba jẹ awọn ọkunrin ni, wọn yoo ro asọ mọ idi wọn lai wọ bata pẹlu."

Awọn ọkunrin ro iro funfun mọ idi wọn, duro laarin erolasiko ọdun Ẹlẹgba Ejiwa

"Ni gbogbo ile Ọlọfin ti wọn ti maa n se ọdun Ẹlẹgba, aiwọ asọ fun takọ tabo wa lati ṣe etutu ni"

Kabiyesi tun fikun pe ni gbogbo ile Ọlọfin ti wọn ti maa n se ọdun Ẹlẹgba, aiwọ asọ fun takọ tabo wa lati se etutu ni.

O ni etutu naa ni yoo mu ki alaafia ati ifọkanbalẹ le wa nilu, ti yoo si tuba tusẹ, kawọn ohun meremere daadaa si le wọ inu ilu ni ọdọọdun.

O fikun pe o ni awọn Orúpò to wa, ile Ojúrẹ ni Ọlọ́nà wa, ti wọn si ti maa n ki awọn eeyan to ba wa se ọdun Ẹlẹgba kaabọ.

"Ile Ojurẹ yii naa ni Esu ati Ogun wa, ti wọn yoo ti ki awọn eeyan sinu agbo."