Ó lè jẹ́ ìjọba Makinde ló ṣagbátẹrù ìjínigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ l'Ogbomoso láti ba orúkọ Tinubu jẹ́ - Fayose

Seyi Makinde wọ aṣọ buba buluu, Ayo Fayose wọ buba funfun

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayose, ti sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ wi pe ijọba ipinlẹ Oyo lo ṣagbatẹru ijinigbe awọn akẹkọọ ati olukọ to ṣẹlẹ l'Ogbomoso.

Fayose to sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe lori ileeṣẹ tẹlifisan Channels lalẹ ana ọjọ Aje sọ pe ijọba Gomina Seyi Makinde le ṣe eleyii lati ba orukọ Aarẹ Bola Tinubu jẹ.

Iṣẹlẹ ijinigbe naa ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ kaakiri ori itakun ayelujara.

Lopin ọsẹ to kọja ni Aarẹ Tinubu ran igbimọ ẹlẹni marun un lọ si Ahoro Esinele ati Yawote l'Ogbomoso nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Igbimọ naa si ṣeleri wi pe awọn ẹṣọ eleto aabo yoo ri pe awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe pada sile ni alaafia.

Amọ, Fayose ti sọ pe ojuṣe ijọba ipinlẹ ni lati ri pe eto aabo to peye wa fun araalu ki ọrọ to kan ijọba apapọ.

Fayose ni idi niyii tawọn gomina fi n gba owo gobọi loṣooṣu fun eto aabo.

''Ki ọrọ to o kan ijọba apapọ, ijọba ibilẹ ati ijọba ipinlẹ wa nibẹ.

Gomina Makinde ko ṣiṣẹ rẹ bii iṣẹ lori ọrọ ijinigbe to ṣẹlẹ l'Ogbomoso, oṣelu ni gomina gbaju mọ dipo ọrọ eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ rẹ.

Lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa gbe tan ni Makinde kopa ninu ibo abẹnu sipo aarẹ.

Ko gbe igbesẹ kankan lori ijinigbe to ṣẹlẹ, lẹyin to wọle ibo abẹnu tan ni o to lọ ṣabẹwo si ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe,'' Fayose lo sọ bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Ekiti sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ijọba ipinlẹ Oyo lo wa nidii iṣẹlẹ ọhun lati le jẹ kawọn araalu maa sọrọ ti o dara nipa ijọba Tinubu.

Ọpọ eeyan lo ti bẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ ijinigbe naa, wọn si ti kepe ijọba apapọ lati doola awọn to wa lakata ajinigbe naa.

BBC Yoruba kan si ijọba ipinlẹ Oyo lati fesi sọrọ ti Fayose sọ, amọ, wọn o fesi kankan titi to fi di asiko ti a kọ iroyin yii.