Afurasí ọ̀daràn mẹ́ta pa ìdílé kan run - Apá Kejì
Awọn afurasi naa jẹwọ gbogbo bi ọrọ ṣe ṣẹlẹ fawọn akọroyin nileeṣẹ ọlọpaa.
Wọn ṣalaye gbogbo bi wọn ṣe gbimọ papọ lati ṣeku pa Baba Chike, iyawo rẹ, ati awọn ọmọ wọn mẹrin.
"Mo lọ sọ fun Ejimọ wi pe Baba Chike ba foonu mi jẹ, o wa sọ pe nko gbọdọ ma gba aarọ, bo ṣe wa ba mi nilẹ laago mẹrin niyẹn wi pe ka maa lọ," Hammed sọ bẹẹ.
"O beere lọwọ mi wi pe Ojo nkọ, mo sọ fun n wi pe o wa ninu ile, o sọ pe o ti ya ka maa lọ sọdọ Baba Chike.
"Ojo naa mu ada ati kumọ jade, bi emi ṣe gbe ibọn ati ada jade niyẹn, ti a fi lọ sibẹ."
Ṣugbọn ṣa, nigba ti wọn debẹ, Ojo to jẹ aburo Hammed lo pe Baba Chike jade sita lati inu ile to wa, wi pe ko jade sita.
Nigba to n sọrọ, Ojo sọ pe, "Nigba ti a de bẹ, emi lọ ba Baba Chike wi pe ko wa ba mi wo nnkan to n ṣẹlẹ. Baba Chike sọ pe ki Hammed ma ṣe bayii fun mi, mo wa sọ pe a ko le pa wọn, wi pe owo foonu la wa gba."






