Mo ṣetán láti tẹ́tí sí gbogbo ohun táwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ekiti bá n fẹ́

Oríṣun àwòrán, Biodun Oyebanji/Facebook
Gomina ipinlẹ Ekiti, Biodun Abayomi Oyebanji ti sọ pe oun ti ṣetan lati tẹti si gbogbo ibeere awọn araalu, ki oun si ṣiṣẹ le wọn lori.
Oyebanji sọ pe oun mọ daju pe iṣẹ ṣi pọ foun lati ṣe ni saa iṣejọba keji to bẹrẹ lọnii, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Gomina naa lo sọ eyi nibi eto iburawọle fun saa keji iṣejọba rẹ, eyi to waye niluu Ado-Ekiti tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ekiti.
Oyebanji pẹlu igbakeji rẹ, Arabinrin Monisade Afuye ni adajọ agba ipinlẹ naa bura fun ni gbagede Pavillion to wa niluu Ado-Ekiti.
Nigba to n sọrọ, Oyebanji ṣeleri lati tubọ ṣe agbekalẹ oniruuru iṣẹ akanṣe onidagbasoke fun igbayegbadun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa.
Lasiko to n ba awọn eeyan, Oyebanji mẹnu ba awọn ipa ribiribi ti iṣakoso rẹ ṣe ni saa akọkọ, lara eyi to ti tọka si ṣiṣe opopona, pipese iṣẹ fawọn ọdọ ati awọn nnkan miran.
Bakan nna ni Gomina Oyebanji fi ẹmi imoore han si Ọlọrun ati paapaa awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lori bi wọn ṣe nigbagbọ ninu rẹ, lati dibo yan an fun saa keji.
O ni gbogbo ohun ti awọn araalu ba n fẹ patapata loun yoo tẹti si, lati rii pe oun ṣe e fun wọn, gẹgẹ bi ọna lati san oore pada fun wọn.
Nigba toun naa n sọrọ, Aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Tinubu gbe oṣuba kare fun awọn olugbe ipinlẹ Ekiti lori ifẹ ti wọn fi han si gomina wọn.
Tinubu ti igbakeji rẹ, Kashim Shettima ṣoju fun sọ pe bi awọn araalu ko ba nigbagbọ ninu iṣakoso Oyebanji, paapaa ẹgbẹ oṣelu APC, wọn ko nii dibo yan an lẹẹlkeji.
Bẹẹ lo gbe oriyin fun Oyebanji ati igbakeji rẹ, Afuye lori akitiyan wọn lati mu igbe aye dẹrun fun gbogbo araalu.
Siwaju sii ninu ọrọ tiẹ naa, adajọ agba ipinlẹ Ekiti, Onidajọ Adekanye Ogunmoye to bura fun gomina ati igbakeji rẹ, rọ wọn lati mu ileri wọn ṣe fun awọn araalu.
Àwọn wo ló wà níbẹ̀?
Ọpọ awọn olori ọba alaye nilẹ Yoruba bii Ọọni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi; Ewi tiluu Ado-Ekiti, Oba Rufus Adejugbe; Adu Alagbado Ogoga tiluu Ikere-Ekiti atawọn miran lo wa nibẹ.
Awọn gomina bii, Lucky Ayeidatiwa ti ipinlẹ Ondo, Hope Uzodinma ti ipinlẹ Imo, AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ko gbẹyin.
Bẹẹ lawọn gomina tẹlẹ bii Ayodele Fayose, Kayode Fayemi, Segun Oni, Otunba Niyi Adebayo, to fi mọ Oloye Bisi Akande, naa foju han.
Yatọ eyi, gbogbo awọn afẹnifẹre Gomina Oyebanji ni wọn wa ni gbagede naa lati wo bi nnkan ṣe lọ.
Òní ni ayẹyẹ ìbúrawọlé fún Gomina Biodun Oyebanji ti ìpínlẹ̀ Ekiti

Oríṣun àwòrán, @Oyebanji Biodun
Oni ọjọ kẹrindilogun, osu kẹwaa, ọdun 2026, ni eto iburawọsẹ ẹlẹẹkeji fun Gomina Biodun Abayomi Oyebanji ti ipinlẹ Ekiti.
Gbagede Pavilion to wa nilu Ado Ekiti ni eto naa yoo ti waye loni.
Ti a ba ko gbagbe pe ogunjọ, oṣu kẹfa, ọdun 2026 yii leto idibo yiyan gomina waye jake jado ipinlẹ Ekiti.
Nibi ti Ọkan o j'ọkan oludije fun ipo Gomina lati inu ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ti kopa lọjọ naa.
Awọn bii, gomina Biodun Abayomi Oyebanji ti APC, Dr Wole Oluyede ti PDP ati Amb. Dare Bejide ti ADC ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lẹyin eto idibo naa ni ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC kede gomina Biodun Oyebanji gẹgẹ bi ẹni to jawe Olubori pẹlu iye ibo bii ẹgbẹrun lọna okooleloodunrun odin kan ati okoolenigba ati merin (319,224).
Leyi to fi fagba han awọn yooku tiwọn jijọ gbapoti ipo naa nipinlẹ Ekiti lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa ọdun 2026 gẹgẹ bi ajọ INEC ti Kede.


























