'Àwọn èèyàn parọ́ mọ́ wa pé a jí nǹkan ọmọkùnrin ẹnìkan, àyélujára sì gbà bẹ́ẹ̀'

Oríṣun àwòrán, Alfred Lasteck / BBC
- Author, Mungai Ngige
- Role, BBC Global Disinformation Unit
- Author, Alfred Lasteck
- Role, BBC Africa
- Reporting from, Tunduma
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
O le ni ọgọrin eeyn to ti ku laarin osu kẹwa ọdun 2025 si osu keje ọdun yii lori pe wọn pa irọ mọ wọn pe wọn lori ohun ti a pe ni jiji nnkan ọmọkunrin.
Ẹka ileesẹ iroyin BBC to wa fun titan imọlẹ si ayederu iroyin ti wa se awari iroyin yii lẹyin to se akojọpọ iwadii lati ileesẹ ọlọpaa lawọn orilẹede mẹfa nilẹ Afirika.
Se ni wọn n pa awọn eeyan tori ayederu ẹsun pe fifi ọwọ gba eeyan ni ejika lasan le mu ki nnkan ọkunrin dinku tabi poora patapata.
Iroyin eke yii, eyi ti sayẹnsi ko le fidi rẹ mulẹ, to n tan kalẹ lori ayelujara, lo n da kun bi wọn se n pa ọpọ eeyan naa.
"Wọn n pariwo pe a ji nnkan ọkunrin kan, ti a ko si ri ọna lati jajabọ nitori pe ogunlọgọ eeyan lo wa nibẹ."
Ọkunrin mẹkaliki kan to jẹ ọmọ ilẹ Tanzania, Boniface Mgala lo sọ bẹẹ fun BBC nipa iriri rẹ ni osu kẹrin lasiko ti awọn eeyan to fi ẹsun kan an pe o ji nnkan ọkunrin ka, na a ni anadojubolẹ.
Iriri rẹ yii naa fara jọ tawọn eeyan to wa ninu fidio kan to tẹ BBC lọwọ: awọn ọkunrin kan lo n pariwo pe nnkan ọkunrin awọn - okó abi koropọn – ti poora tabi yinrin lẹyin ti wọn fi ara kan awọn ajeji, ti awọn obitibiti ero yoo si maa sọ fun ẹni ti wọn ba fi ẹsun kan naa pe ko da ohun to ji pada.
Irufẹ ẹsun bayii si lo da lori ibẹru ati igbagbọ ninu nnkan eyi to ti wa fun ọjọ pipẹ - eyi ti ko si jẹ tuntun nilẹ Afirika, paapaa lawọn agbegbe ti wọn ti ni igbagbọ ninu agbara ajẹ, eyi to ti tan kalẹ.
Bakan naa si ni itakun agbaye n se iranwọ lati se agbelarugẹ awọn irufẹ ibẹru bii eyi.

Eyii to ṣẹṣẹ n waye ni lọlọ yii lo bẹrẹ ni Democratic Republic of Congo, nibi ti irufẹ nnkan bẹẹ ti kọkọ waye ṣaaju lọdun 2008.
Iroyin naa bẹrẹ si n tan kalẹ titi to fi de Burundi, Zambia ati Tanzania to fi mọ Mozambique, Angola, Malawi ati Kenya.
Ni Zambia, iroyin nipa nnkan ọmọkunrin to poora kọkọ milẹ titi ninu oṣu Kẹta nigba ti wọn lu ọdọbinrin kan pa, titi to fi tan de aala Tanzania.
Nile rẹ ni Mpemba, Mgala fọwọ si apa egbo ori rẹ, o si ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lasiko naa.
O ni "Ti mo ba mọ pe o ṣeeṣe ki n sọ ẹmi mi nu lọjọ naa ni, mi o ba ti lọ sinu ile ounjẹ ọhun lati lọ jẹun. Bo tilẹ jẹ pe a kii mọ akoko ti iku ba wa nitosi wa ni."
Ọjọ kinni, oṣu Kẹrin loun ati ọrẹ rẹ lọ si Tunduma lati lọ pade onibara kan nipa ọkọ to fẹ ra, amọ o pinnu lati kọkọ jẹun ṣaaju idunadura ọhun.
Ko pẹ ti wọn joko ninu ile ounjẹ naa ti ọpọ ero ya bo wọn nibẹ ti awọn ọgọrọ ero naa si wọ wọn jade.
Apa meji mii ati ẹyin kan to sọnu wa lara nnkan to fi n ṣeranti ọjọ naa.
Lasiko ti wọn n na wọn, o daku rọgbọndan. Lẹyin ọjọ meji lo to pada ji saye nile iwosan, asiko naa lo gbọ pe wọn pa ọrẹ rẹ ti wọn jọ jade.
Bayii, igi lo fi n rin, o si ni gbogbo igba ni ori maa n fọ oun.
Titi di asiko to n ba wa sọrọ, ko tii lokun ati pada sidi iṣẹ ọkọ titunṣe to yan laayo latari ilera rẹ.
Lọjọ kan naa ti wọn lu Mgala ati ọrẹ rẹ ni alubami, ayaworan kan, Michael Silavwe sọ pe oun ri irufẹ iṣẹlẹ kan naa ni Tunduma, nibi to ni awọn eeyan binu lẹyin fidio ori TikTok to sọ pe wọn ji nnkan ọmọkunrin ẹnikan lọ nibẹ.
O ni oun ri awọn eeyan ti wọn n sare niwaju ṣọọbu oun lẹyin ti wọn ni wọn mu ẹnikan to jẹ ki nnkan ọmọkunrin ẹnikan poora, lẹyin naa ni wọn dana sun ọkunrin ti wọn fẹsun kan ọhun.
"Lẹyin ti wọn dana sun un tan, gbogbo wọn tuka nigba ti ọlọpaa de ibẹ."
Ninu fidio kan ti the BBC Global Disinformation Unit wo ti awọn eeyan si ti wo ni igba to le ni 100,000 lori TikTok ati Facebok, a ri awọn eeyan ti wọn n na ọkunrin ti wọn ni o ji nnkan ọmọkunrin ẹlomii.
Asha Steven Mwakilasa, ẹni aadọta ọdun kan ni Tunduma sọ pe lẹyinorẹyin loun to mọ pe irọ lasan ni.
Obinrin naa sọ pe gbogbo igba ni ẹru maa n ba oun ti ọkọ tabi awọn ọmọ oun ọkunrin ba lọ si igboro.
Kọmiṣọna ọlọpaa agbegbe Momba, Elias Daniel Mwandobo sọ fun BBC pe iwadii awọn fi han awọn kan lo wa nidi awọn iṣẹlẹ naa.
Ọlọpaa naa sọ pe ti awọn kan ba ti daran tan ni wọn maa n mọọmọ ru araalu soke lati bo aṣiri ara wọn.
Ninu fidio mii ni Tanzania, awọn eeyan n lu ọkunrin kan niluu Dar es Salaam pe ko da nnkan ọmọkunrin to ji pada ti ọkunrin naa si n bẹbẹ pe oun ko ṣe nnkan ti wọn fẹsun rẹ kan oun.
BBC tun ri irufẹ fidio bẹẹ to suyọ ni Mozambique ati Kenya.
Irufẹ awọn fidio bayii nibi ti wọn ti n fi ẹsun jiji nnkan ọmọkunrin ẹlomii kan awọn eeyan pọ jantii rẹrẹ loju opo TikTok ati Facebook.
Pupọ awọn fidio ọhun ti a ṣayẹwo rẹ ni wọn ṣi pọ lori ayelujara.
Agbẹnusọ kan nileeṣẹ Meta sọ pe awọn n ṣagbẹyẹwo awọn fidio naa awọn yoo si yọ wọn kuro loju opo awọn ti wọn ba tako ilana.
Ni ti TikTok, wọn ko tii fesi si atẹjisẹ ti BBC fi ṣọwọ si wọn.
Onkọwe nni, Julien Bonhomme, sọ pe ẹrọ ilewọ ati ayelujara maa n mu ki iroyin ẹlẹjẹ tete tan kalẹ lati de ọdọ ọpọ eeyan, o si maa n ṣoro lati da duro to ba ti bẹrẹ si n milẹ titi.
Ninu iwe rẹ, 'The Sex Thieves: The Anthropology of a Rumor', o ni kii kan n ṣe pe awọn eeyan n sọ pe nnkan ọmọkunrin ẹnikan poora, amọ awọn eeyan kan funra wọn n sọ pe nnkan ọmọkunrin awọn poora.
Fidio ori ayelujara le mu ki iroyin ẹlẹjẹ da bii eyii to jẹ ootọ pọnbele latari bi awọn eeyan ṣe fẹran ati maa mu foonu wọn kiri ni gbogbo igba, gẹgẹ bii onkọwe naa ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Orilẹede Mozambique ni ọrọ naa ti buru julọ nibi ti ọlọpaa ti sọ pe ninu oṣu Karun un, eeyan marundinlọgọta ni wọn ṣekupa nibẹ.
Lara awọn ti wọn pa ni ọlọpaa, oṣiṣẹ eto ilera ati oṣiṣẹ ijọba kan.
Aarẹ orilẹede naa, Daniel Chapo bu ẹnu atẹ iṣekupani naa atawọn iroyin ẹlẹje ọhun, o ni ko si iwadii kankan to fi han pe ẹnikẹni sọ ẹya ara wọn nu.
Awọn oṣiṣẹ eto ilera meji ti wọn ku naa ni wọn kọlu ninu ile ati ni ibiṣẹ wọn lagbagbe Cabo Delgado to jẹ agbegbe ti awọn alakakiti ẹsin Islam maa kọlu loorekoore.
Awọn ile iwosan to wa lagbegbe naa ni ijọba ti pa fun ọsẹ diẹ ti wọn si bẹrẹ awọn ipolongo kan lati tako iroyin ẹlẹjẹ ọhun.
Orilẹede Kenya ni iṣekupani to waye lọlọ yii ti ṣẹlẹ lẹyin ti wọn gbẹmi awọn eeyan mẹjọ ni Kwale ati Mombasa.
Nigba ti iṣẹlẹ akọkọ waye ni Mombasa, ọlọpaa di ẹbi rẹ ru awọn gbajumọ ori ayelujara to n pin irọ kiri ki awọn eeyan ba le maa tẹlẹ wọn.
Kọmiṣọna ọlọpaa agbegbe naa, Mohamed Noor sọ fun BBC pe "Irufẹ iroyin ẹlẹjẹ bẹẹ le yọri si iku awọn eeyan."
O ni ọlọpaa ti kawọ iwa ipa naa, o si ti fi ṣikun ofin mu ọpọ afurasi.
Lara awọn to ni wọn mu ni baba ati ọmọ kan ti wọn ri ẹwọn ọdun kan he lẹyin ti wọn jẹwọ pe awọn fẹsun kan eeyan pe o mu ki nnkan ọmọkunrin ẹnikan poora.
Irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ tun waye ni Malawi, nibi ti ọgọrọ ero ti ṣekupa eeyan mẹjọ.
Ni Tunduma, to wani Tanzania, ọkunrin to n tun ọkọ ṣe ti wọn pa ọrẹ rẹ naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ti n gbadun diẹdiẹ lẹyin iṣẹlẹ ọhun, apa rẹ ṣi wa lara oun, bẹẹ ni oun ko ni gbagbe iṣẹlẹ naa titi lai.
























