Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ àwọn ọmọ onílùú lásìkò ìfẹ̀hónúhàn- Ìjọba Naijiria kìlọ̀ fáwon èèyàn rẹ̀ tó ń gbé ní South Africa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba orilẹede Naijiria ti ṣe ikilọ tuntun fun awọn eeyan rẹ to n gbe ni South Africa, lẹyin ti iroyin jade pe awon kan tun n pete ati kọlu awọn ajoji lapa kan orilẹede naa.

Ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria loke okun, Nigerians in Diaspora Commission (NiDCOM) lo kede eyi lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin ọdun 2026.

NidCOM sọ pe awon kan fi ẹhonu han lawọn igboro ilu South Africa titi to fi mọ Cape Town, Durban ati agbegbe East London.

Wọn fi kun un pe wọn sọ iwọde naa di ole jija, won si ba dukia jẹ pẹlu.

Atẹjade ajọ yii waa rọ awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni South Africa lati tẹ ẹ jẹjẹ, ki wọn ma si ṣe doju ija kọ awọn ọmọ oniluu.

Ikilọ yii lo n waye lẹyin ti alakooso agba kan lati Naijiria fun Johannesburg, sọ pe iwadii fi han pe awon kan n pete iwọde tuntun lagbegbe Gauteng, laaarin ọjọ Aje si Ọjọruu oṣu yii (Monday 27 - Wednesday 29 April).

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Ninu awon fidio to jade sori ayelujara, awon ọmọ orilẹede South Africa kan gbe igi dani, won fi n lu awon alawọ dudu miran to n gbe niluu naa, wọn n sọ pe ki wọn kuro niluu awon.

Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni iru ikọlu bẹẹ kan awon ọmọ orilẹede Ghana kan to n gbe ni South Africa.

Ohun ti a gbọ ni pe o wu awon olufẹhonuhan naa lati jẹ ki ijọba South Africa le awon ajoji jade lorilẹede naa, eyi si jẹ ọrọ kan to maa n fa awuyewuye niluu naa.

Ṣaa, Ajọ NidCOM gba awọn ọmọ Naijiria to fi ibẹ ṣebugbe nimọran, lati ri i pe wọn ko koju awọn ọmọ oniluu.

Ajọ naa ni ki wọm rin jinna si agbegbe ifẹhonuhan, ki wọn si maa tẹti si iroyin agbegbe wọn lati mọ bo ba ṣe n lọ.

Bakan naa ni wọn kilọ fun awon to ni ileeṣẹ ati okoowo ninu awon ajoji lati ma ṣe ṣi i lasiko yii, nitori awon ni awon olufẹhonuhan naa maa n dojusọ ju.

Wọn yoo da gbese si wọn lorun nigba ti won ba ko oja won lo tabi ti won ba awon dukia won jẹ lasiko iwọde.

Wọn fi kun un pe ileeṣẹ Naijiria to wa ni Johannesburg yoo wa ni ṣiṣi silẹ, wọn yoo si maa ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ eleto aabo South Africa, lati da aabo bo awon ọmọ Naijiria.

Awon ikọlu to ti waye ri ni South Africa

Iwa ifẹhonuhan to kun fun ikorira alawọ dudu, to si n pe fun kawon ajoji kuro niluu awon ti n waye tipẹ ni South Africa.

O ti le ni ogun ọdun ti ikọlu bẹẹ ti n waye.

Ohun ti awon omo oniluu maa n sabaa so ni pe awon ajoji ti gba gbogbo iṣẹ to yẹ kawon maa ṣe tan, won si maa n ri won bii ẹni ti ko yẹ ko ti okeere waa jẹ gaba lori awon.

Ni 2008 to waye, eeyan to le ọgọta (60) lo di oloogbe.

Ni 2015 ati 2019, wọn dojusọ awon ajeji kaakiri Africa titi kan awọn ọmọ Naijiria, Zimbabwe ati Somalia.

Eyi lo fa a ti awon omo ilu wonyi naa fi ni awon yoo gbesan pada.

Awọn ọmọ Naijiria kan naa fi ehonu han ni 2019 lori ohun to n ṣẹle ni South Africa nigba naa, won si n bẹrẹ si i ba awọn dukia ileeṣẹ to je ti South Africa lorilẹede Naijiria jẹ, awon bii MTN ati Shoprite Holdings.

Ikilọ tuntun lori ikọlu naa lo n waye ṣaaju ọjọ kẹtadinlgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii, ti wọn n pe ni Freedom Day ni South Africa.

Ọjọ naa ni wọn ya sọtọ fun isinmi lẹnu iṣẹ, ti wọn fi n sami ayajọ ọjọ idibo akọkọ ti ko ni ẹlẹyamẹya ninu, ti wọn di ni 1994, to si fi opin si akoko Apartheid ni South Africa.