Ẹ ò gbọdọ̀ fá wàhálà kan - Imam mọ́ṣáláṣí tí wọ́n gún lọ́bẹ lẹ́yìn àdúrà fohùn ránṣẹ́

Imam Musa Lukwa ti wọn gun lọbẹ

Oríṣun àwòrán, Animashaun Salman

Àkọlé àwòrán, Imam Musa Lukwa ti wọn gun lọbẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Sokoto ti paṣẹ ki wọn gbe mọṣalaṣi Lukuwa Jumu'at to wa ni Mabera, niluu Sokoto ti pa lẹyin ti wọn gun alfah kan, Musa Lukawa, lọbẹ nibẹ.

Ijọba ipinlẹ naa tun ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii to peye lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun pẹlu ikede pe mọṣalaṣi naa ti di ibi ti wọn ti wuwa ọdaran.

Aṣẹ yii lo jade ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ijọba ipinlẹ ọhun, Abubakar Bawa, fi lede laarọ oni ọjọ Iṣẹgun.

Aṣẹ yii lo n jade lẹyin wahala kan to bẹ silẹ ni mọṣalaṣi naa ti wọn si kọlu Lukuwa leyin to lewaju adura tan nibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ na sọ pe awọn ero inu mọṣalaṣi ọhun kọlu ẹni to gun alfah wọn lọbẹ ti wọn si lu u titi ti ẹmi fi bọ lẹnu rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Sokoto, Ahmad Rufa'I sọ pe nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹwaa ọsan lawọn gba ipe pajawiri nipa iṣẹlẹ naa.

O ni iwadii awọn fi han pe lẹyin adura ni afurasi naa wọ inu mọṣalaṣi ọhun to si kọlu Lukuwa pẹlu ọbẹ ọwọ rẹ ki wọn to gbe alfah naa lọ sile iwosan fun itọju.

Wayi o, Lukuwa ti fi ohun ranṣẹ si awọn alatilẹyin rẹ ki wọn ma fa wahala kankan, o fi kun pe ara oun ti balẹ lẹyin ikọlu ọhun.

Latari ikọlu naa ni ijọba ṣe pasẹ ki wọn gbe mọṣalaṣi naa ti pa fun iwadii to peye.

Yatọ si eyii, ijọba tun ti gbe igbimọ kan dide ti yoo ṣewadii ohun to n da ija ẹsin silẹ lagbegbe naa lọna ati wa ọna abayọ si rogbodiyan ọhun.

Ijọba ipinlẹ ọhun tun yẹba fun ẹnikẹni ti wọn ni o n bu anọbi Muhammad, idile rẹ, awọn obi rẹ tabi awọn akọwọrin rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba ipinlẹ Sokoto bọwọ fun Muhammad, o si tẹle ofin rẹ, lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ipinlẹ ọhun ki wọn ṣe bẹẹ gẹgẹ.

O tun parọwa si gbogbo araalu ki wọn ṣọra fun sisọ ọrọ ti yoo tunbọ da oju ọrọ naa ru siwaju si.