"Ibọn ba mi ni igba aya lọjọ naa, titi di oni, mi o ri idajọ ododo gba", Ọdun mẹ́fà lẹ́yìn ìwọ́de EndSARS ṣé ìdájọ́ òdodo tí wáyé?

Awọn to n ṣeranti iṣekupani iwọde EndSARS
    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, BBC News Yoruba
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni awọn ọdọ bẹrẹ ifẹhonuhan EndSARS tako ifiyajẹni ẹka SARS ti ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria,.

Iwọde naa jẹ ọkan gboogi lara awọn iwọde to milẹ titi julọ ni Naijiria ati kaakiri ilẹ adulawọ lasiko naa.

Amọ nigba ti yoo di ogunjọ oṣu Kẹwaa ọhun ni iwọde naa gbọna mii yọ lẹyin ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu paṣe konile-o-gbele, ki awọn ọmọ ogun to lọ ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde ọhun ni iloro Lekki Toll Gate.

Awọn to wa nibẹ jabọ pe awọn ọmọ ogun lo yinbọn fun awọn oluwọde bo tilẹ jẹ ijọba sọ pe ko ri bẹẹ ko to gbe igbimọ oluwadii kan dide lati wadii ohun to ṣelẹ nibẹ.

Iku awọn oluwọde naa jẹ eyii to pana iwọde ọhun lẹsẹkẹsẹ amọ ọdun mẹfa lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye, ki ni ayipada to ti de ba ẹkaeto aabo Naijiria ati pe ṣe afojusun awọn oluwọde naa wa si imuṣẹ?

"Ibọn ba mi ni igba aya lọjọ naa, titi di oni, mi o ri idajọ ododo gba"

Ọta ibọn nibi Lekki Toll Gate ti ologun ti yinbọn fun awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Ọta ibọn nibi Lekki Toll Gate ti ologun ti yinbọn fun awọn oluwọde

BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn to fara gbọta ibọn lasiko iwọde naa ni iloro Lekki, Agbeze Ifeanyi Matthew to sọ pe iṣẹlẹ naa da ọgbẹ si oun lara amọ titi di oni ko si idajọ ododo kankan fun oun.

O ni "Emi ni adẹrinpoṣonu ti wọn yinbọn fun ni Lekki Toll Gate logunkọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

"Lati ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹwaa la ti wa nibẹ pẹlu awọn ọrẹ mi, ibẹ ni a sun mọju.

"Ibẹ ni a wa lasiko ti gomina Sanwo-Olu kede konile-o-gbele.

"Nigba ti awọn ologun de ti rogbodiyan naa bẹrẹ, aya ni ọta ibọn ti ba mi.

"Aya mi ni apa ọtun ni, ọta ibọn naa wọle simi laya, o fọ egungun aya mi, o si jade lodi keji."

"Bi ibọn naa ṣe ba mi tan, mi o mọ ibi ti mo wa mọ, mo ṣaa pe wọn gbe mi digbadigba lọ sile iwosan ijọba to wa ni Marina amọ wọn ni wọn ko le tọju mi, ki wọn to fi mi ranṣẹ si ile iwosan ijọba to wa ni Ikeja."

Agbeze Ifeanyi Matthew laisko iwọde endsars ati lẹyin ti ibọn ba a tan
Àkọlé àwòrán, Agbeze Ifeanyi Matthew laisko iwọde endsars ati lẹyin ti ibọn ba a tan

O ni ọsẹ kan gbako loun lo nile iwosan ki wọn to ni ki oun maa lọ sile.

Ọdọkunrin naa sọ pe titi di oni yii, apa ọgbẹ naa ṣi wa lara oun , koda o yẹ ki wọn ṣiṣẹ abẹ fun oun amọ oun ko ni owo lati ṣiṣẹ abẹ naa.

O tẹsiwaju pe oun wa lara awọn to lọ sọrọ niwaju igbimọ oluwadii iṣẹlẹ naa ti igbimọ naa si fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ologun yinbọn fun awọn oluwọde amọ titi di oni yii, ijọba ko fun oun ni owo gba mabinu, bẹẹ lawọn to padanu ẹmi wọn ko ri idajọ ododo gba.

"Wọn ko fun wa lowo gba mabinu kankan titi di oni o, lẹyin iṣẹlẹ naa, a yọju siwaju igbimọ oluwadii, a paara-paara nibẹ fun odididi ọdun kan, sibẹ, a ko ri nnkankan."

Lẹyin naa lo gba ijọba niyanju lati ṣe ohun to yẹ nitori iran to wa lode lonii, inu wọn ko dun si ijọba apapọ.

Ti mo ba di Aarẹ, a maa ṣewadii EndSARS lakọtun – Sowore

Omoyele Sowore wọ aṣọ ati igo dudu
Àkọlé àwòrán, Sowore ni ko yẹ ki iwọde naa pari lẹyin iku awọn oluwọde
Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC, to tun jẹ ọkan lara awọn to lewaju iwọde EndSARS naa, Omoyele Sowore ti sọ pe iwọde ọhun jẹ asiko ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin ninu itan ijijagbara awọn ọdọ ni Naijiria.

Sowore sọ fun BBC Yoruba pe iwọde ọhun jẹ asiko ti awọn ọdọ Naijiria sọ pe o to gẹ si ifiyajẹni awọn ọlọpaa ati lati fẹhonuhan lodi si ipo ti ọrọ aje Naijiria wa lasiko naa.

O ni ti oun ba de ipo Aarẹ Naijiria, oun yoo pada ṣi iwe iranti kan iwọde naa, iwadii yoo waye lori rẹ, bẹẹ ni gbogbo awọn to gbẹmi awọn ọdọ lọna aitọ yoo foju wina ofin.

Sowore sọ pe "Fun ọpọlọpọ awọn ọdọ, igba akọkọ ti wọn maa jijagbara funra wọn niyẹn, ohun to n dun wọn ni bi ọlọpaa ṣe n ṣe awọn ọdọ, gbogbo agbaye lo si mi titi lasiko iwọde naa.

"Awọn ọlọpaa ti a fẹhonu lodi si, wọn ti pada sẹnu iṣẹ, awọn ọdọ ti wọn pa, wọn bo orukọ wọn mọlẹ, wọn ṣi n pa irọ titi di oni yii pe wọn ko pa ẹnikẹni.

"Amọ, ṣe ẹni ti ko pa eeyan lo n fun aawọn eeyan ni riba ki wọn pa iwadii yẹn mọlẹ?

"Idi niyii ti a fi n sọ pe ki wọn tun iwadii naa ṣe, ti wọn ba si kọ lati tun iwadii naa ṣe, ti awa ba gba ijọba, a maa tun iwadii naa ṣe."

Ṣe iwọde EndSARS ṣe aṣeyọri?

Lekki Toll Gate lasiko iwọde EndSARS

Bo tilẹ jẹ pe ijọba wọgile ẹka SARS naa lọdun naa lọhun, titi di oni, awọn ọlọpaa ṣi n ṣe awọn ọdọ ṣibaṣibo ni Naijiria.

Lọpọ igba lawọn ọlọpaa maa dunkoko moọ awọn ọdọ paapaa awọn ti wọn ba n lo ọkọ olowo nla ti wọn si fura si pe wọn le jẹ onijibiti ori ayelujara.

Sowore ni kii ṣe pe iwọde naa kuna lati ṣe aṣeyọri to yẹ ko ṣe amọ o maa ṣaṣeyọri daadaa ti awọn ọdọ ko ba fori pamọ lẹyin akọlu Lekki Toll Gate lọdun mẹfa sẹyin.

O ni "Iwọde yẹn, ọjọ keji, bi wọn ṣe paayan yẹn, ọjọ keji, ko yẹ ki awọn ọdọ sa wọle, niṣẹ lo yẹ ki wọn tẹsiwaju.

"To ba jẹ pe iwọde naa tẹsiwaju lọjọ naa ni, kii ṣe Naijiria ti a wa bayii ni a maa wa."

Sowore pari ọrọ pe ijọba gbọdọ mọ pe o ṣeeṣe ki irufẹ ki iwọde bẹẹ tun waye lọjọ iwaju ti ko ba ṣe ohun to yẹ.

Wayi o, ọpọ awọn araalu lo ti bẹrẹ si n ṣeranti awọn ọdọ to padanu ẹmi wọn lasiko iwọde naa bayii.

Yatọ si awọn ọdọ to ku, ọpọlọpọ dukia lo jona, to fi mọ ọkọ ayọkẹle, ọkọ ekero BRT, ati oniruru agọ ọlọpaa pẹlu awọn awọn agbofinro lo ba iṣẹlẹ naa lọ.