Èyí lohun tí òfin sọ nípa àwọn tó bá ń gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ pé jàndùkú wọ ìlú àti ìjìyà tó wà fún un

Lati igba ti iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọ ati olukọ ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo ti waye, ogunlọgọ ọmọ Naijiria kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iṣẹlẹ naa.
Bi awọn kan ṣe n gbadura ki Eledua tu awọn eeyan naa silẹ lawọn mii n fi epe ranṣẹ si ijọba apapọ, bẹẹ ni ọpọ awọn mii n ṣe ifẹhonuhan.
Fun ọpọ eeyan, bi awọn ọmọde to wa ni akata awọn agbesunmọmi ninu igbo yoo ṣe gba itusilẹ lo jẹ wọn logun bo tilẹ jẹ pe ero wọn ṣọtọtọ.
Amọ ṣa, o ṣeni laanu pe bi awọn eeyan ṣe n gbadura ti wọn si n gbogun ti ijọba ko doola awọn eeyan naa lawọn mii n lo iṣẹlẹ ọhun lati mọọmọ da ibẹrubojo silẹ laarin ilu.
Irufẹ awọn eeyan bẹẹ lawọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri pe awọn agbesunmọmi ti wọ oniruru ilu nilẹ Yoruba amọ ti ko si ri bẹẹ.
Ọlọpaa tilẹ mu ọdọkunrin kan to ṣe fidio pe awọn Fulani agbenipa ti wọn ilu amọ to pada jẹwọ ni agọ ọlọpaa pe ko ri bẹẹ ṣugbọn oun ṣe fidio ọhun ki ọpọ eeyan le tẹle oun lori ayelujara.
Awọn ipinlẹ ti awọn eeyan ti gbe iroyin ẹlẹjẹ pe agbesunmọmi wọ ilu
Ipinlẹ Eko
Lagbegbe Ibeju-Lekki lawọn araalu ti ke gbajare sita pe awọn ri awọn janduku an wọn n ya wọ ilu, koda, wọn mu awọn ọdọkunrin kan pẹlu. Amọ ninu atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa kọ, wọn ni ko si ootọ kankan ninu iroyin ọhun, ki araalu ma si naani rẹ.
Ipinlẹ Oyo
Nipinlẹ Oyo, ọlọpaa fi ṣikun ofin gbe eeyan meji lori pe wọn gbe iroyin ofege pe awọn janduku agbebọn ti ya wọ ilu Lamini lagbegbe ijọba ibilẹ Ido. Ọlọpaa ni oju opo WhatsApp lawọn eeyan naa ti n pin iroyin ọhun eyii to fa ibẹru laarin awọn eeyan.
Ipinlẹ Osun
L'Osun, ọpọ awọn obi lo ya wọ awọn ile ẹkọ kan niluu Osogbo lẹyin ti wọn gbọ pe awọn janduku ti wọ ilu. Amọ nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ati gomina Ademola Adeleke yoo sọrọ, wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ.
Ipinlẹ Ondo
Bo ṣe ri nipinlẹ Osun naa lo ri nipinlẹ Ondo nigba ti ọpọ awọn obi ya wọ ile ẹkọ awọn obinrin, Fiwasaye to wa lagbegbe Alagbaka lati lọ mu awọn ọmọ wọn kuro nibẹ. Ọrọ naa le to bẹẹ titi ti kọmiṣọna fun eto ẹkọ, Ọjọgbọn Igbekele Ajibefun fi lọ sile ẹkọ ọhun lati sọ fun awọn obi pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
Ki ni ofin sọ nipa awọn to n mọọmọ pin irufẹ iroyin ẹlẹjẹ kiri
BBC Yoruba kan si amofin kan, Olusegun Kofoworola, o ni abala kọkandinlọgọta ofin Naijiria ti sọrọ lori ọrọ yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ofin naa sọ pe "Ẹnikẹni to ba kọ tabi polongo ọrọ, ahesọ tabi iroyin to le da ibẹru si aarin ilu to si mọ pe irọ ni ọrọ ọhun yoo jẹbi, o si le fi ẹwọn ọdun mẹta jura."
Amofin naa sọ pe yatọ si ofin ijọba apapọ yii, ọpọ awọn ijọba ipinlẹ naa ni wọn ti gba ofin ọhun wọle ni ipinlẹ wọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹṣẹ ni labẹ ofin lati maa pin iroyin ẹlẹjẹ to le da ipaya silẹ ti irufẹ ẹni bẹẹ si mọ pe irọ ni iroyin ọhun.
Koforowola sọ pe "Iwa ọdaran ni… ẹwọn ọdun mẹta ni ẹni naa yoo ṣe."
O fi kun pe ofin iwa ọdaran ori ayelujara naa fidi rẹ mulẹ pe irufẹ nnkan bẹẹ le sọ eeyan di ero ẹwọn, to fi mọ pipa irọ fun ọlọpaa lasiko iwadii.
Amofin Kofoworola pa ri ọrọ rẹ pe ki awọn araalu maa ṣe iwadii wọn daadaa ki wọn to maa pin oniruru iroyin kiri ori ayelujara.


























