INEC àti DSS bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lẹ́yìn tí àlàyé nípa olùdìbò lu síta lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, INEC
Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC ti sọ pe oun to bẹrẹ iwadii bi alaye nipa oludibo kan ṣe lu sita lati oju opo ayelujara oun.
Ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun, INEC sọ pe oun gbe igbesẹ yii lẹyin ti iroyin nipa oloṣelu kan to tun jẹ gbajugbaja oṣere tiata, Emeke Ike, lu sita loju opo Continuous Voter Registration (CVR) ajọ naa.
Ṣaaju ni Emeka Ike ti kọkọ dunkoko pe oun yoo pe Lere Olayinka, to jẹ agbẹnusọ minisita fun FCT, Nyesom Wike lẹjọ lẹyin ti alaye nipa oun lu jade lori ẹrọ INEC, eyii ti Olayinka fi soju opo X rẹ.
Oṣere tiata naa lo dije fun ipo ile igbimọ aṣojuṣofin fun ẹkun AMAC/Bwari labẹ asia ẹgbẹ NDC.
Ọrọ kan Lere Olayinka lẹyin to gbe ohun to jọ alaye nipa Ike sita loju opo X rẹ, eyii ti igbagbọ wa pe o mu loju opo ayelujara INEC bo tilẹ jẹ pe ko yẹ ko ni anfani lati ri alaye ọhun.
Loju opo X Olayinka to fi alaye naa si ni alaye nipa nọmba iforukọsilẹ Ike wa, to fi mọ awọn alaye mii bii nọmba idanimọ idibo rẹ, aworan rẹ, orukọ ati ọjọ to fi orukọ silẹ, eyi to n ṣafihan pe oju opo ayelujara INEC lo ti ri alaye ọhun.
INEC ati DSS bẹrẹ iwadii
Ninu atẹjade ti ẹni to ṣoju INEC, Mohammed Haruna, fi sita, o sọ pe pe INEC ko fi ọrọ naa ṣere rara.
INEC sọ pe ni itẹsiwaju ifọrukosilẹ awọn oludibo, wọn fun awọn to n ṣiṣẹ iforukọsilẹ naa lanfani lati ri awọn iroyin kan nipa awọn ti wọn n fi orukọ wọn silẹ amọ awọn oṣiṣẹ naa ko ni lanfani naa si alaye naa mọ lẹyin ti eto iforukọsilẹ ọhun ba ti pari.
Wọn ni iwadii yajoyajo ti awọn ṣe ti fun wọn lanfani lati mọ ẹni to wọ oju opo naa lati mu iroyin nipa Emeka Ike to lu sita.
INEC tẹsiwaju pe "Gẹgẹ bo ṣe eyẹ, a ti fi ọrọ wa awọn oṣiṣẹ wa ti ọrọ kan lẹnuwo, bẹẹ ni gbogbo awọn ẹka ti ọrọ kan n fọwọsowọpọ lori iwadii ti a n ṣe."
Ninu alaye rẹ, INEC ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS naa ti bẹrẹ iwadii tirẹ lori ọrọ ọhun, oun si ti ṣeleri lati fọwọsọwọpọ pẹlu DSS lori iwadii rẹ to n ṣe.


























