Ojú rí kí n tó rí ètò tó mú èèyàn 51,000 wo sinimá tí mo fi gba àmì ẹ̀yẹ GWR ṣe – Omowunmi Dada

Aworan Omowunmi Dada pẹlu aworan idanimọ ajọ amiẹyẹ Guinness World Records lẹyin rẹ.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsana ọdun 2026 ni ajọ to n ṣeto ami ẹyẹ gbankọgbi lagbaye, Guinness World Records, GWR kede orukọ gbajumọ oṣere tiata kan ni Naijiria, Ọmọwunmi Dada pe o ti gba amiẹyẹ ẹni ti to ṣeto sinima ti awọn eeyan to pọ julọ peju wo ni ita gbangba lagbaye.

Ninu ifọrọwerọ rẹ, Ọmọwunmi Dada ṣalaye idi ti awọn ikọ rẹ fi gba lati ṣe afihan sinima naa ni ita gbangba dipo ile iworan sinima gẹgẹbi ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ ṣe maa n ṣe.

Ohun to mu ki 'black Market' di ọmọ tuntun jojolo fun ami ẹyẹ GWR

Aworan Ọmọwunmi Dada

Ọmọwunmi ṣalaye fun ikọ BBC News Yoruba pe ohun to mu ki wọn gbe igbesẹ naa ni ipinnu oun atawọn tawọn jọ gbe sinima naa jade lati ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri. O ni oun ati ikọ oun fẹ tayọ ilana ti awọn eeyan maa n lo tẹlẹ lati ṣe afihan sinima wọn.

O ni "o de akoko kan ti a wo o pe sinima yii, ṣe a fẹ ṣe ilana gbigbe sinima lọ si ile sinima ti gbogbo awọn eeyan maa n ṣe ni , abi a fẹ ṣe nnkan kan to tun yatọ? La fi pinnu lati ṣe nnkan to yatọ.

O ni idi ti awọn fi pinnu lati ṣe nnkan to yatọ ni lati jẹ ko di mimọ fun awọn eeyan pe ko pọn dandan pe ile iworan sinima nikan lawọn onisinima le gbe sinima wọn lọ fun araalu lati le wo o.

Lootọ irinajo naa ko rọrun ṣugbọn lati ibẹẹrẹ loun ti ni igbagbọ pe yoo ṣeeṣe

Ọmọwunmi Dada ṣalaye pe orilẹede Phillipines lawọn ti wo awokọṣe ilana fifi sinima wiwo ni itagbangba naa gba ami ẹyẹ GWR nitori awọn ni wọn di ami ẹyẹ naa mu lasiko naa pẹlu ero ẹgbẹrun mẹrinlelogoji (43,000).

Nora Awolọwọ to bẹrẹ ọrọ ṣiṣe sinima naa lo sọ pe o kọkọ mu aba gbigba ami ẹyẹ naa jade, ṣugbọn ti oun si gbaagbọ lẹsẹkẹsẹ. O ni lootọ irinajo naa ko rọrun ṣugbọn lati ibẹẹrẹ loun ti ni igbagbọ pe yoo ṣeeṣe.

"Lọjọ yẹn a ni eeyan ẹgbẹrun mẹtalelọgọta ni gbagede TBS ṣugbọn ẹgbẹrun mọkanlelaadọta eeyan ni wọn wo sinima 'Black Market' lati ibẹẹrẹ de opin."