Ṣé àjọ EFCC kúnjú òṣùnwọ̀n láti tọpinpin ẹ̀sùn àjẹbánu bó ṣe dá ogójì òṣìṣẹ́ rẹ̀ dúró lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́?

Àwọn òṣìṣẹ́ àjọ EFCC mẹ́rin wọ àṣọ ìlékè iṣẹ́ wọn aláwọ̀ pupa sọ́rùn, wọ́n ń rìn lọ láàrin èrò

Oríṣun àwòrán, EFCC/Web

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Alaga ajọ EFCC to ń gbogun ti iwa ibajẹ, Ola Olukoyede, ti kéde wí pé ajọ naa ti da òṣìṣẹ́ rẹ to le ni ogoji duro lẹnu iṣẹ lori ẹsun iwa ibajẹ.

Olukoyede sọrọ yii fawọn akọroyin nibi eto to fi n ṣami ọdun mẹta to de ipo alaga EFCC.

O fikún ọrọ rẹ pe bii marun un oṣiṣẹ àjọ naa lo n jẹjọ lọwọ lori oniruuru ẹsun iwa ajẹbanu.

"Lati nnkan bii ọdún meji ati aabọ sẹyìn ni mo ti sọ pe ki oṣiṣẹ EFCC to le logoji lọ gbe ile wọn lori ẹsun iwa ajẹbanu.

A si tun n gbero lati gbe awọn mii lọ sí ile ẹjọ.

Awọn araalu le wo bi ẹjọ naa yoo ṣe lọ nile ẹjọ.

Ti mo ba n fọwọ ofin máwọn oṣiṣẹ àjọ mii lori iwa ibajẹ, ki lo maa mu mi ti mi o ni mu awọn oṣiṣẹ àjọ temi," Olukoyode lo sọ bẹẹ.

"EFCC ni yoo sọ gbedeke irufẹ ẹbun tawọn oṣiṣẹ rẹ le gba lọwọ ẹnikẹni''

Olukoyode sọ pe igbesẹ yii wa lara igbiyanju EFCC lati ri pe ọwọ oṣiṣẹ ajọ naa mọ.

''Ọwọ awọn to n ba EFCC ṣiṣẹ gbọdọ mọ tori eeyan ko le maa gbogun ti iwa ibajẹ nigba ti ọwọ toun gan an ko mọ.

Bakan naa ni a ti gbe eto kan kalẹ labẹ eyi ti gbogbo oṣiṣẹ wa gbọdọ maa sọ fun EFCC nipa ẹbun ti ẹnikẹni ba fun wọn yala lati ọwọ ọrẹ tabi ibatan wọn.

EFCC yoo tun sọ gbedeke irufẹ ẹbun tawọn oṣiṣẹ rẹ le gba lọwọ ẹnikẹni,'' alaga EFCC lo sọ bẹẹ.

Olukoyode wa pe fun atunṣe eto idari awọn ileeṣẹ ijọba lati le gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria.

O ni kii ṣe awọn agbofinro lo le gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ kumọ bi ko ṣe eto ijọba to mọyan lori ti yoo dena mawọn to ba fẹ lu owo ilu ni ponpo.

EFCC gba ₦1.23trn, $684.5m owo ilu ati dukia 10,053 laarin oṣu mẹrinlelọgbọn

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, alaga EFCC Olukoyede ti sọ pe ajọ naa ti ri owo ijọba to to N1.23trn gba laarin oṣu mẹrinlelọgbọn.

Olukoyede ṣalaye wi pe ko din ni ₦1,233,612,040,411.11, $684,478,457.32, £373,905.78 ati €9,343,803.66 ti ajọ naa ri gba laarin asiko yii.

O ṣalaye siwaju sii wi pe ₦397.26 bn, eyi to jẹ ida 33% ni EFCC ri gba fun ijọba apapọ nikan nigba ti ₦836.34 bn to jẹ 67% jẹ awọn ti EFCC ri gba lawọn oniruuru ileeṣẹ ijọba, awọn eeyan atawọn to wa loke okun.

Alaga EFCC ni ẹsun 39,615 ni awọn ṣe iwadii rẹ ninu eyi ti eeyan 10,872 ti jẹbi ẹsun tawọn fi kan wọn laarin ọdun 2023 si 2026.

Gẹgẹ bi Olukoyede ti ṣalaye, ẹsun to ni ṣe pẹlu ṣiṣe owo kumọ kumọ jẹ 46,288 laarin ọdun 2024 si 2026.

Ọga agba EFCC ṣalaye pe owo ti ko din ni ₦661.32bn ati $492.37 ninu owo tawọn ri gba ni ajọ naa ti da pada fawọn ajọ to lowo naa.

Olukoyede sọ pe ₦325.35 bn ni EFCC da pada fawọn eeyan ati awọn ileeṣẹ, bakan naa ni awọn tun da ₦335.97bn pada fun oniruuru ileeṣẹ ijọba to fi mọ ajọ to n pawo wọle fun ijọba.

Yatọ si owo, Olukoyede tun ṣalaye pe EFCC tun ri dukia ijọba bii 10,053 gba laarin ọdun 2023 si 2026 yii.

Lara awọn dukia ti wọn ri gba ni 1,177 ile, ọkọ 370, 251 ilẹ, to fi mọ awọn ile ẹkọ, ileeṣẹ, ṣọọbu ati ọkọ baalu.

Bakan naa ni o tun sọ pe EFCC ri oniruuru nnkan alumọni atawọn nnkan mii towo rẹ to ₦12.07 bn gba, eyi ti ajọ naa ti da pada fun ijọba apapọ.

Gbàjarè oo! Inú àpò àṣùwọ̀n owó orí ayélujára 'crypto' ni wọ́n n jí owó ìjọba ìbílẹ̀ pamọ́ sí báyìí – EFCC figbe ta

Awọn osisẹ ajọ EFCC bii meje wọ asọ awọleke ti wọn tẹ orukọ EFCC si lara, wọn durp ;ati takurọsọ

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣẹ owo ilu kumọkumọ nilẹ Naijiria, EFCC ti sọ pe inu apo aṣuwọn ori ayelujara ti ẹnikẹni ko le tọpinpin rẹ ni wọn n ji owo ijọba ibilẹ ko si bayii.

EFCC sọ pe nigba ti wọn ba wọ owo naa kuro ninu apo aṣuwọn ijọba ibilẹ sinu apo aṣuwọn ileeṣẹ aladani, ni wọn yoo to ṣẹṣẹ wọ sinu apo aṣuwọn crypto lori ayelujara, ki aṣiri ma ba a tu.

Alaga ajọ EFCC, Ola Olukoyede lo fidi aṣiri yii mulẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja.

"A ti gbẹsẹ le awọn apo aṣuwọn naa fun wakati mejilelaadọrin ri, lati le ṣe iwadii awọn ibi ti owo naa n lọ, ati ohun ti wọn fẹ fi ṣe ni pato"

Bo tilẹ jẹ pe Olukoyede ko darukọ awọn ijọba ibilẹ, ileeṣẹ ati awọn ipinlẹ tọrọ naa kan, sibẹ o sọ pe ajọ EFCC ko le gboju kuro ninu bi owo ilu ṣe n fo kaakiri lọna to nii fura si.

O ni ẹka ileeṣẹ wọn to n ri si ewu jibiti, iyẹn FRACD ti ṣawari awọn ọna ti owo ijọba n gba fo kaakiri lọna to mu ifurasi lọwọ.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe, awọn ti gbẹsẹ le awọn apo aṣuwọn naa fun wakati mejilelaadọrin ri, lati le ṣe iwadii awọn ibi ti owo naa n lọ, ati ohun ti wọn fẹ fi ṣe ni pato.

Ohun tó n bà mí lọ́kàn jẹ́

Ọga agba EFCC naa sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ foun nigba ti awọn eeyan ba n pe fun ori oun, lori awọn igbesẹ ti ajọ EFCC ba gbe lati gbogun ti iwa jibiti.

Ninu ọrọ rẹ, o ni, "Nigba ti a ba kofiri owo to n fo kaakiri lọna to nii fura si, a maa dide lati gbesẹ le e fun igba diẹ. Mo mọ pe ninu yin lo n beere fun ori mi," Olukoyede sọ bẹẹ.

"Wakati mejilelaadọrin la fi gbesẹ le owo naa. Ki wọn wa ṣalaye ibi ti owo naa n lọ, idi ti wọn fi n wọ owo naa. A ri bi owo ṣe n fo lati inu apo aṣuwọn ijọba ibilẹ sinu apo aṣuwọn ileeṣẹ aladani.

"Yatọ si eyi, a tun ṣakiyesi pe inu apo aṣuwọn ori ayelujara ti a mọ si 'cryptocurrency wallets' ni awọn owo naa lọ.

"Ṣe opopona ti ẹ fẹẹ ṣe niyẹn? Ṣe awọn araalu naa le jẹ anfaani ninu ọna lati wa owo ori ayelujara yii? Ṣe niṣe lẹ n sọ fun mi pe ki n di oju mi si iru nnkan bẹẹ? A jẹ wi pe ẹ ko nilo mi lori ipo yii niyẹn," alaga EFCC sọ bẹẹ.

Alaga ajọ EFCC, Olukoyede ree lasiko to n sọrọ nibi ipade ajọ naa to waye laipẹ yii niluu ABuja, o mu ẹrọ gbohungbohun to fi n sọrọ dani, bẹẹ lo n fi ọwọ ṣe apẹjuwe ọrọ to n sọ

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

"A kò lè káwọ́ gbera ki wọn maa ji owo ijọba"

Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe idagbasoke naa lo jẹ ki ajọ EFCC bẹrẹ igbesẹ lati ma ṣe duro de igba ti wọn ba n ji owo ilu, ko to di pe awọn dide, ati pe awọn nilo lati kọkọ da awọn owo naa duro, lati mọ ohun ti wọn wa fun, ati ibi ti wọn n lọ.

"Ki lo de ti a ṣe maa duro digba ti wọn ba ji owo ijọba? Ki lo de ti a ko le yi nnkan pada si bo ti tọ? Ohun pataki ti a si gbọdọ mu wa si ileeṣẹ ree," Olukoyede jẹ ko di mimọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju eto idibo gomina nipinlẹ Osun to waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni ajọ EFCC gbesẹ le aṣuwọn ipinlẹ naa, lori ẹsun ti wọn fi kan ijọba nipa owo to n fo lọna ifurasi.

Ṣugbọn sibẹ, EFCC ko fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ Osun ni wọn ti ṣawari idagbasoke tuntun yii, bẹẹ si ni ko darukọ ipinlẹ miran pẹlu.

"Jìbìtì orí ayélujára tí kọjá 'Yahoo-Yahoo', wọn n lo awọn ọdọ lati ji owo ijọba sinu apo asunwọn Crypto"

Olukoyede tun fi kun ọrọ rẹ pe iwa jibiti ori ayelujara ti kọja ohun ti awọn eeyan mọ si Yahoo-Yahoo, pẹlu bo ṣe sọ pe wọn ti n lo awọn ọdọ bayii lati fi ji owo ilu ko pamọ sinu apo aṣuwọn ori ayelujara ti a mọ si 'cryptocurrency wallets'.

O sọ pe, "A ti wa ni ipo naa lorileede Naijiria bayii, leyi to jẹ pe awọn oṣiṣẹ ati aṣoju ijọba ti n ji owo ko, ti wọn si n ko o pamọ sinu apo aṣuwọn cryptocurrency.

"Ọpọ awọn adari ẹka ileeṣẹ ijọba ti a n ṣe iwadii wọn lọwọ bayii, ẹ ko le ri dukia gid ikan mọ wọn. Wọn n ji awọn owo yii ko, wọn n fun awọn akẹkọọ, awọn ọdọ. Kaakiri agbaye ni wọn ti n ṣi apo aṣuwọn ori ayelujara. Wọn a si ko awọn owo naa sibẹ laaarin wakati mẹrinlelogun.

"Owo naa n lọ soke okun. Wọn n rai le nibikibi lagbaye, wọn n ra awọn nnkan olowo nla to jọju. Awọn nnkan to n lọ nigboro lasiko yii ree."

"Àwa náà kò dúró, a ti gbe oju opo kalẹ lati tọpinpin apo aṣuwọn ori ayelujara, pẹlu awọn to ti forukọsilẹ ni Naijiria"

Olukoyede sọ pe igbesẹ yii, lo jẹ ki awọn naa ṣagbekalẹ ọna lati maa tọpinpin awọn owo ori ayelujara wọnyi, paapaa awọn eyi ti wọn ṣi nilẹ Naijiria, ti wọn si fi n ji owo ko.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o fidi rẹ mulẹ pe oju opo awọn dukia ori ayelujara to to ogoji ni awọn ti fun ni iwe aṣẹ, lẹyin agbeyẹwo ti wọn ṣe nipa wọn, ati agbara ti awọn ileeṣẹ naa ni.

"Ni bayii, awa naa ti ṣagbekalẹ oju opo ti a fi n tọpinpin apo aṣuwọn ori ayelujara yii, pẹlu awọn to ti forukọsilẹ ni Naijiria, ohun ti a n ṣe ree," o fi kun ọrọ ree.

Nigba to n tọka si awọn aṣeyọri ajọ naa lati bi ọdun mẹta sẹyin, Olukoyede sọ pe awọn ti gba ọpọ dukia ori ayelujara ti wọn fi jibiti ko jọ nipasẹ CBEX.

O ni ohun to n fun wọn ni ipenija bayii, ni bi wọn ko ṣe tii mọ awọn to wa nidi agbekalẹ CBEX naa.

"Nigba ti ẹ ba gba awọn dukia ori ayelujara wọnyi, nibo lẹ fẹẹ ko wọn si? Ko si otitọ. Idi ree ti a ko fi le maa tẹsiwaju bayii.

"EFCC lé ogójì òṣìṣẹ́ danù torí ìwà àjẹbánu"

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn oṣiṣẹ ti ko din ni ogoji ni ajọ naa ti le danu lẹnu iṣẹ, nitori iwa jibiti ti wọn ka mọ wọn lọwọ.

O ni laaarin ọdun meji aabọ si mẹta toun ti gba iṣakoso, loun ti ṣawari awọn oniwa jibiti ninu awọn oṣiṣẹ wọn, to si loun ko le gboju kuro lara wọn.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe pupọ ninu awọn ti wọn le danu yii, ni wọn ti n foju ba ile-ẹjọ, nigba ti wọn n ṣe iwe awọn yooku lọwọ lati kawọ pọyin rojọ niwaju ile-ẹjọ.