You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣọ́ọ̀ṣì kan rèé tí wọn kií lanu sọ̀rọ̀, ọwọ́ lásán làwọn akọrin, oníwàásù àti olùjọ́sìn fi ń júwe
Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.
Oniruuru ile ijọsin la mọ, bawọn Kristẹni se ni awọn ṣọọṣi ti wọn ti n jọsin, lawọn musulumi ni awọn mọsalasi ati Yidi ti wọn ti n kirun.
Bakan naa ni awọn ẹlẹsin abalaye si ni ọpọ ojubọ tiwọn, ohun to si wọpọ nipa awọn ibudo ijọsin naa ni pe wọn maa n kọrin, lu ilu, sọrọ tabi pariwo lawọn ile ijọsin naa.
Amọ ninu irinkerindo ileesẹ iroyin BBC News Yoruba la ti se alabapade ibudo ijọsin kan eyi to jẹ ara meeriri.
Ninu ṣọọṣi naa, awọn olujọsin kii la ẹnu wọn sọrọ, ọwọ lasan nikan ni wọn fi maa n juwe.
Bawo wa ni ile ijọsin naa se jẹ? Ki lo de ti wọn kii fi sọrọ, ọna wo si ni wọn n gba se ijọsin wọn, ti ede wọn se n ye ara wọn?
"Ṣọọṣi odi ni wọn n pe ibi, odi ni ọpọ olujọsin, ẹgbẹ akọrin ati oniwaasu"
Ninu iwadi BBC News Yoruba nipa ṣọọsi yii, a ri pe awọn eeyan to ni ipenija lati sọrọ tabi gbọ ọrọ lo wa fun.
Ileẹkọ olukọni fawọn akanda ẹda to wa ni ilu Oyo nipinlẹ Oyo si ni Sọọsi naa wa.
Idi si ree ti wọn se n pe ijọ naa ni ṣọọsi awọn odi, tori ọpọ awọn eeyan ti ko le sọrọ tabi gbọ ọrọ lo wa nibẹ.
A tun sawari rẹ pe ninu ile ijọsin naa, awọn olujọsin ibẹ kii pariwo rara, ọwọ lasan ni wọn fi maa n juwe lasiko ti wọn ba n kọrin tabi waasu.
Nigba to n ba BBC News sọrọ, ọkan lara awọn olujọsin ni ṣọọsi awọn odi salaye pe pẹlu idakẹrọrọ ni awọn ti n jọsin.
"Gbogbo ẹgbẹ akọrin lo jẹ odi, awọn oniwaasu naa si jẹ odi, ọwọ lasan nikan la maa fi n sapejuwe lati ba ara wa sọrọ.
Koda, wọn n ka bibeli ninu ijọ naa amọ ọwọ lasan ni wọn fi n juwe"
"Ọpọ ipenija lo n koju sọ́ọ̀ṣì awa odi, a ko tii pari kikọ ile igbọnsẹ, se orule ṣọ́ọ̀ṣì, paanu ti si, ilẹ ṣọọsi si n bo"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, obinrin kan to le sọrọ, to si gbọ ọrọ, salaye fun wa pe ilu to ba ya sawọn odi lọwọ ni wọn maa n lu.
"Ijo ba ba ba wọn lara ni wọn n jo, ilu to ba ba wọn lara ni wọn n lu ni sọọsi awọn odi, yatọ si bo se maa n waye ni sọọsi awọn eeyan to le sọrọ."
Bakan naa ni osisẹfẹyinti kan to ba wa sọrọ ni ipenija owo n ba wọn finra ni sọọsi awọn odi.
O ni owo to pọju ti wọn maa n da lasiko isin ọjọ Aiku ni ẹgbẹrun marun Naira.
"A maa n se iwuri fawọn akẹkọọ to jẹ olujọsin ni sọọsi awọn odi lati wa jọsin ni, ti a si se ounjẹ fun wọn, ti owo ba wa.
Amọ lọpọ igba, a maa n parọwa si wọn lati wa gbọ ọrọ Ọlọrun."
Bakan naa lo tun sọrọ nipa awọn isẹ ti ko tii pari lara sọọsi awọn odi naa.
"A ko tii pari kikọ ile igbọsẹ wa, a ko tii se orule inu sọọsi awọn odi naa, ti paanu ijọ naa si ti si nigba ti ilẹ ṣọọsi naa ti n bo."