Ibùdó ìfọpo tí mo fi lọ́lẹ̀ ní Kenya yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kó tó di ọdún 2030 - Dangote
Eto gbogbo ti to bayii fun ifilọlẹ ibudo ifọpo Dangote ni orilẹede Kenya.
Ibudo ifọpo naa yoo maa ṣiṣẹ fun ẹkun ila oorun Africa.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Aliko Dangote ṣalaye pe, oun ko nii lọkan lati bẹrẹ ileeṣẹ ifọpo kankan ni agbegbe naa lawọn ọdun diẹ sẹyin.
Ṣugbọn ó ní ipinnu oun lati rii pe Africa dẹkun kiko awọn ohun alumọni rẹ ṣọwọ si oke okun lọ ṣe okùnfà ìgbésẹ̀ yìí.
O ni èyí yóò jẹ ki awọn naa le bẹrẹ si ni ta awọn ohun elo ti wọn ti funrawọn pari iṣẹ rẹ, ìdí sì rèé tí oun fi pinnu lati da ileeṣẹ ifọpo naa silẹ.
Dangote ṣalaye pe ileeṣẹ ifọpo ti wọn fẹ ṣe ifilọlẹ rẹ lorilẹede Kenya yoo bẹrẹ iṣẹ ki o to di ọdun 2030, iyẹn ọdun mẹrin si asiko yii.

Aliko Dangote sọ eyi nigba to n dahun ibeere BBC lori bi idasilẹ ileeṣẹ ifọpo rẹ ṣe fẹ ṣe anfani fun awọn eeyan agbegbe ẹkun naa ati orilẹede Kenya gan an funrarẹ pẹlu bi awọn onwoye ṣe n sọ ọ pe idasilẹ ileeṣẹ ifọpo rẹ lorilẹede Naijiria ko mu adinku ba iye owo tawọn eeyan n san lori epo bẹntiroolu lorilẹede Naijiria. O ni ko si otitọ ninu ọrọ ti awọn eeyan n sọ ati wi pe iye ti awọn eeyan n san fun epo bẹntiroolu lorilẹede Naijiria lo fẹẹ kere julọ bi wọn ba gbe e yẹwo pẹlu iye ti awọn eeyan n san lawọn orilẹede to yii ka.






