Ìṣọ́ òru di ibùdó ẹ̀jẹ̀ níjọ CAC Eda Oniyo l‘Ekiti, agbébọn pa pásítọ̀, jí ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ gbé lọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ di boo lọ, yago fun mi lalẹ ana ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kérin 2026 nigba tawọn agbebọn kan ya wọ ile ijọsin CAC Eda Oniyo Ekiti lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ṣadeede lawọn agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si ṣekupa pasitọ ijọ naa, ki wọn to ji awọn ọmọ ijọ kan gbe lọ.

Awọn o-ṣoju-mi-koro ni awọn agbebọn naa ṣọṣẹ fun bii iṣẹju meloo kan, ki wọn to ji awọn olujọsin naa lọ sinu igbo.

Ohun ti a gbọ ni pe, awọn agbalagba atawọn ọmọde wa lara awọn olujọsin ti wọn ji gbe lọ naa.

A ko tii le sọ ni pato iye awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ, amọ, iṣẹlẹ naa ti da ibẹru-bojo silẹ niluu Eda Oniyo-Ekiti.

Oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ekiti kan, ti ko fẹ ka darukọ rẹ sọ pe awọn agbonfinro ti bẹrẹ si ni wa awọn eeyan ti wọn gbe lọ.

O ni oun ni idaniloju wi pe gbogbo awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ lawọn agbofinro yoo doola.

Ileesẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori isẹlẹ naa

Bakan naa, Kọmisọna ọlọpaa ìpínlẹ̀ Ekiti, CP Falade Adegoroye Michael, ti ṣeleri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe iwadii iṣẹlẹ bi awọn agbebọn to ya wọ ile ijọsin CAC Eda Oniyo-Ekiti nibi ti wọn ti yinbọn pa pasitọ ti wọn si ji awọn ọmọ ijọ gbe lọ.

CP Micahael sọ pe ajọ ọlọpaa gbọdọ fọwọ ofin mawọn janduku agbebọn to ṣiṣẹ laabi naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni nnkan bii ago mẹwaa abọ alẹ ana ọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹrin yii ni awọn agbebọn marun un ṣadeede ya wọ ṣọọṣi naa.

O ni isẹlẹ naa waye lasiko ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ, ti wọn si yinbọn pa alufaa ijọ naa.

"Awọn ọlọpaa, awọn eṣọ Amotekun atawọn fijilante ti bẹ sinu igbo lati doola awọn ọmọ ijọ ti wọn jigbe lọ"

Lẹyin ti wọn ṣekupa alufaa ijọ ọhun tan, ni wọn ji awọn ọmọ ijọ kan gbe lọ.

Awọn ọlọpaa, awọn eṣọ Amotekun atawọn fijilante ti bẹ sinu igbo lati doola awọn ọmọ ijọ ti wọn jigbe lọ.

Bakan naa ni wọn fọwọ ofin mawọn janduku agbebọn naa.

Kọmiṣọna ọlọpaa wa rọ awọn olugbe ilu naa wi pe ki wọn mase foya tori awọn agbofinro yoo ṣagbara wọn lati doola awọn ti wọn ji gbe lọ.

Bakan naa ni kọmiṣọna ọlọpaa sọ pe ileeṣẹ yoo ri wi pe iru iṣẹlẹ yii ko waye mọ.

CP Michael tun sọ fawọn eeyan ilu naa lati maa tẹle ohun ti ijọba sọ tẹlẹ wi pe ki wọn maa fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti nigba kugba ti wọn ba ti fẹ ṣe iṣọ oru ki ileeṣẹ ọlọpaa le pese eto aabo to peye fun wọn.

Kọmiṣọna ọlọpaa tun rọ awọn araalu lati wa lojufo nigba gbogbo ki wọn si fi to ọlọpaa leti ti wọn ba ti kẹẹfin ẹnikẹni to n ṣe nnkan to mu imura dani.