Ààrẹ Tinubu ló ni àsìkò ti tó fún mi láti lọ dupò gómínà Oyo- Adelabu

Adebayo Adelabu ati Aarẹ Bola Tinubu n bọ ara wọn lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Adebayo Adelabu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi asiko ọrọ ko ba ti I to, a ki I sọ, eyi ni Adebayo Adelabu, minisita tẹlẹ fun ọrọ ina mọnanọna lorilẹede yii, sọ pe o fa a ti oun ko fi tete kede erongba oun lati du ipo gomina ipinlẹ Oyo.

Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni ikede kan waye, pe Adelabu ti kọwe fi ipo minisita silẹ, nitori ati du ipo gomina.

Ko pẹ lẹyin ikede naa ti iroyin tun fi jade pe minisita tẹlẹ naa ko ti i kọwe fipo silẹ, ati pe o si di ipo rẹ mu gẹgẹ bii minisita ninu ijọba Tinubu.

Ko tun pẹ sigba naa ni iroyin tun gbode, pe Adelabu ti pada kọwe fipo rẹ silẹ bii minisita, o si ti ṣetan lati lọ fun ipo gomina ipinlẹ Oyo.

"O di dandan ki n ṣe gbogbo eto pari pẹlu Aarẹ ni mi o ṣe tete kede pe mo fẹ dupo gomina, nigba ti Aarẹ sọ pe asiko ti to ni mo ṣẹṣẹ kede"

Ninu fidio kan lori ayelujara, a ri Adelabu to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lori awuyewuye to wa nidii ikọwe fipo silẹ naa.

"Mo wo o pe mo ṣaa maa lọ ri ẹni to yan mi siṣẹ ki n too fiwe silẹ, a ṣaa maa wo ara wa lojukoju, idi ti mo ṣe da a duro nigba yẹn niyẹn, pe ki n fi aaye silẹ lati ri wọn (Aarẹ Tinubu),'' bẹẹ ni Adelabu wi.

O ni Aarẹ paapaa tun pe awon eeyan lọtun-losi nipinlẹ Oyo, wọn si jọ sọrọ, ki wọn le mọ ibi to de duro.

"Mi o le parọ mọ wọn, odidi Aarẹ orilẹede, wọn maa gbọ ti mo ba parọ mọ wọn.

"Awọn ni wọn sọ fun mi pe, "Bayo, asiko ti to, pe ki n lọ bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ. Lagbara Olorun, nnkan ti won sọ fun mi niyẹn. Aarẹ lo sọ fun mi pe ki n fiwe silẹ,"

Minisita tẹlẹ naa ṣo pe oun ati Tinubu jọ ni ajọsọ ọrọ. Tinubu si sọ pe ou

n ko ni i da oun duro lati dupo gomima to ti n wu oun tipẹ, bo tilẹ jẹ pe o wu u kawọn jọ maa ṣiṣẹ pọ lọ.

O tẹsiwaju pe Aarẹ sọ pe to ba ṣee ṣe lati fa oludije ti ẹgbẹ fẹnuko le lori kalẹ, yoo ri bẹẹ, bi ko ba si ṣee ṣe, kawọn lọ dibo abẹle ti a mọ si pamari lati yanju rẹ.

"A ko ni i gba ki ẹnikan tun gbe eeyan le wa lori ni 2027"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju fidio naa, Adabayo Adelabu sọrọ nipa bi ipo gomina ipinlẹ Oyo ṣe ti bọ mọ ẹgbẹ APC lọwọ nipinlẹ Oyo ri, to si jẹ pe ko ṣẹyin ẹnikan.

Ẹnikan ọhun ti Adelabu ko darukọ rẹ pato, amọ to n paṣamọ si pẹlu sisọ pe oun ko darukọ eeyan o, ni awọn to wa nibẹ n ba a darukọ pe Ladoja ni.

Gẹgẹ bi Adelabu ṣe wi:

"Lati 1999 to fi di isinyi, ẹẹmeji ni wọn ti le wa kuro lori ijọba, bẹẹ ni abi bẹẹ kọ?

Awọn to wa nibẹ kigbe pe bẹẹ ni.

"2003 ati 2019.

"2003, ta a lo wa nidii ẹ?"

Awọn ero kigbe pe Ladoja, Adelabu tun ni ati, wọn tun dahun pe Sarafa Alli.

Nigba naa ni Adelabu sọ pe oun ko darukọ eeyan o.

O ni ni 2019 ti oun jade dupo gomina, ti awon ṣe ibo apapọ, awọn ni sẹnetọ meji ninu mẹta , ọmọ ile igbimọ aṣoju mẹwaa ninu mẹrinla.

Adelabu sọ pe awon ko ba wole ipo gomina nigba naa bi ko ba jẹ ti awon ti won sọ pe laye, ko ni i ri bẹẹ.

O ni niṣe ni awon kan kora wọn jọ, ti Ladoja wa ṣiwaju wọn.

Ko gbọdọ tun ri bẹẹ mọ lo wi.

Adelabu sọ pe wọn fiya jẹ awọn, awon yoo si kọ ìyà naa bayii.

O ni ita loun ti n sọ ọ yii, ko ṣee ṣe ki nnkan tun ri bii ti tẹlẹ yẹn mọ.

Adelabu sọ pe APC tobi ju ohun ti ẹnikan yoo deede maa paṣẹ rẹ lọ.