Afurasí ọ̀daràn mẹ́ta pa ìdílé kan run - Apá Kínní
Afurasí ọ̀daràn mẹ́ta pa ìdílé kan run - Apá Kínní
Published
Lori Kayeefi BBC News Yoruba tọtẹ yii, ilu Oloba nipinlẹ Oyo ni Kayeefi gbe wa lọ, nibi ti awọn gendekunrin mẹta ti pa idile kan run.
Awọn afurasi naa ṣalaye bi wọn ṣe pa awọn idile ẹlẹni mẹfa naa run, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ awọn mẹtẹẹta.
Lasiko ti awọn ọlọpaa n foju wọn han fawọn akọroyin, awọn afurasi naa sọrọ.
Ṣaaju asiko yii, awọn ara agbegbe Oloba ba BBC sọrọ nipa awọn amookunṣeka naa.
Ọgbẹni "Ẹyọ ẹnikan n da gbe inu ibẹ yẹn. Inu oṣu Kẹta, ọdun yii la lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ nibẹ, ti a si beere ọrọ lọwọ ẹ.
"O sọ pe baba wa to jẹ Mọgaji lo fun oun nibẹ lati maa fi da oko, awa sọ pe ṣe ibi tẹ ẹ lọrun, o si sọ pe o tẹ oun lọrun."
O ṣeni laanu pe ko ju bi oṣu diẹ lọ, lẹyin eyi ni awọn afurasi naa lọ ṣeku pa mọnu ile to n gbe.






