Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ohun tó fa ìkọlù ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ nílẹ̀ Mali èyí tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ
Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ohun tó fa ìkọlù ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ nílẹ̀ Mali èyí tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ
Rogbodiyan to buyọ lọjọ Abamẹta lorilẹde Mali, ti awọn agbesunmọmi ti kọlu ibudo ologun ko ti i fi gbogbo ara relẹ tan.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni wahala mi-in tun ṣẹyọ laaarin awọn ọmọ ogun ọlọtẹ atawọn ologun Mali.
Gẹgẹ bi akọroyin Mali kan ṣe ṣalaye fun BBC, rogbodiyan tuntun naa n waye ni Ariwa Kidal.

Ikọ ologun ilẹ Russia ni iroyin sọ pe wọn n ti awọn ologun Mali lẹyin lati koju awon agbesunmọmi Tuareg.
Koda, wọn ti pa Minisita fun eto aabo ni orilẹede naa, Sadio Camara, nile rẹ to wa ni olu ilu orilẹede naa, Bamako pẹlu mọlẹbi rẹ mẹta.
BBC News Yoruba wa se akojọpọ iroyin nipa ohun ti a mọ ti awọn agbebọn fi se ikọlu silẹ Mali, alaye ree ninu fidio yii.






