Ọdún kan sẹ́yìn ni mo ti ń ṣàìsàn, dókítà kò sì mọ ohun tó ń ṣe mí - Opebe onítíátà

Opebe wọ aṣọ Ankara, ko de fila

Oríṣun àwòrán, KunleAfod/YouTube

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nigba ti awọn eeyan ṣi n sọrọ lori aisan jẹjẹrẹ ti gbajugbaja oṣere nni, Taiwo Hassan (Ogogo) n koju lọwọ, agba oṣere miran, Yomi King tawọn eeyan n pe ni Ọpẹbẹ tun ti ṣalaye nipa ilera tiẹ naa to ti n yingin.

Opebe toun ati Oloogbe Babatunde Omidina (Baba Suwe) jẹ ọrẹ timọtimọ nigba aye Oloogbe naa, ṣalaye nipa ailera rẹ fun Kunle Afod, gbajumọ oṣere tiata to ṣabẹwo si i laipẹ yii.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni Kunle Afod gbe fọnran ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Ọpẹbẹ soju opo Youtube rẹ, to si n ṣe awọn eeyan ni kayeefi.

Opebe wọ Ankara aláwọ̀ yẹlo, kò de fìlà, ó jókòó tí Kunle Afod to wọ aṣọ shaati búlúù àti Sokoto dúdú, ó dé fìlà oloyinbo to kọ ojú rẹ sẹ́yìn

Oríṣun àwòrán, KunleAfod/YouTube

Àárẹ̀ wo lo n ṣe Opebe?

Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwerọ naa, Ọpẹbẹ jẹ ko di mimọ pe aisan to n ṣe oun ti le lọdun kan, toun si ti na ọpọlọpọ owo lati tọju ara oun.

O fi kun un pe ki ẹjẹ yẹn maa lọ silẹ wa ninu ailera to n koju oun.

Iroyin kan tilẹ sọ pe ayẹwo oyinbo ko fi ohun to n ṣe agba oṣere yii han, sibẹ, ara rẹ ko le.

Oju ẹsẹ ni Afod to gbe fidio ifọrọwanilẹnuwo naa sita, fun Opebe ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira lati fi tọju ara rẹ.

O rọ awọn ọmọ Naijiria lati dide iranlọwọ fun un nilana ti ẹmi, ti owo nina ati itọju nilana iṣegun oyinbo.

Kunle Afod ninu ọrọ rẹ, ṣalaye pe oun rin irin ajo lọ sile Opebe latari awọn eeyan ti wọn n beere rẹ.

O ni ọpọ eeyan lo n sọ pe awọn ko ri Opebe ba sọrọ mọ fun igba pipẹ, nitori aago rẹ ko lọ.

Bẹẹ ni wọn ni àwọn ko ri i ninu awọn ere agbelewo bii tigba kan mọ.

Ẹyi ni Afod sọ pe o mu oun wa agba oṣere naa lọ.

O ṣapejuwe ibi ti oṣere yii n gbe bii ibi to wọnu pupọ, to si ṣoro lati de.

Afod sọ pe akọ iṣẹ ni lati ri Yomi King pẹlu ibi to n gbe naa.

Amọ ju gbogbo ẹ lọ, bi awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria yoo ṣe ṣaanu fun Opebe ni gbogbo iyanju yii da le lori.

Afod rọ awọn eeyan lati dide iranwọ fun Opebe, ko le baa pada ni ilera pipe.

Yomi King (Opebe)

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Yomi King (Opebe)

Ta a ni Yomi King (Opebe)

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lasiko ti ere agbelewo ko ti i pọ, ati nigba ti won ti n ṣe fiimu tawọn eeyan n gbe inu yara wo tẹlifiṣan wọn ni Yomi King tawọn eeyan mọ si Opebe ti n ṣe ere tiata Yoruba.

Ipa adẹrin-in poṣonu lo maa n ko lọpọ igba.

Ọpọ eeyan mọ ọn fun bo ṣe maa n ka awọn ika ọwọ rẹ kan kò, ti yoo si tun maa tiro bii pe ẹsẹ n dun un.

Lasiko naa, oun ati Oloogbe Babatunde Omidina (Baba Suwe) ni wọn jọ wa, ere awada ti wọn si maa n ṣe lori amohunmaworan nigba naa ni wọn pe ni Ẹrin keeke.

Ọdun 1987 ni nigba naa.

‎Ilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun ni wọn ti bi Yomi King, amọ ipinlẹ Eko to gbe ju lo maa n sabaa ka ara rẹ mọ.

Iṣẹ awọn to n tẹ nnkan si ara aṣọ, iwe ati bẹẹ bẹẹ lọ ti a mọ si Printing lo kọ nibẹrẹ ọjọ, ko too ya sinu ere ori itage.

Opebe darapọ mọ ere ori itage gẹgẹ bii ifẹ to ni si iṣẹ naa.

Ọdun 1979 lo bẹrẹ si i ṣiṣẹ itage, nigba to wa lẹni ọdun mejidinlogun pere (18).

Amọ ere oniṣe ti a mọ si Ẹrinkeeke lo gbe e jade lọdun 1987.

Oun naa si maa n sọ ọ ninu awọn ifọrọwanilẹnuwo pe Baba Suwe tawọn jọ n ṣe ere naa ni ọga oun.

Diẹ lara awọn iṣẹ ti Opebe ti kopa ni

Erinkeke 1987

Irepodun (2002)

Ijangbọn (2023)

Ẹjẹ́ Adegbenro (2006) ati bẹẹ bẹẹ lọ.