Olórí àwọn ṣọ́jà balẹ̀ sí Maiduguri lẹ́yìn àṣẹ Tinubu pé kí gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn ajínigbé gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Isah Ojo
Ọgagun agba Waidi Shuaibu,olori awọn ọmọ ogun ori ilẹ lorilẹede yii ti balẹ si ilu Maiduguri, nipinlẹ Borno bayii.
Eyi n waye lẹyin aṣẹ ti Aarẹ Bola Tinubu pa, pe gbogbo awọn to wa nigbekun ajinigbe kaakiri Naijiria gbọdọ gba itusilẹ.
Nnkan bii aago mọkanla owurọ ọjọ Abamẹta,ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni olori awọn ṣọja naa balẹ si Maiduguri.
"Tinubu paṣẹ pe ko gbọdọ si ibudo agbesunmọmi ni Naijiria mọ"
Gẹgẹ bi Minisita eto aabo, Ọgagun Christopher Musa ṣe ṣalaye ṣaaju, o ni l'Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹwaa yii ni Aarẹ Tinubu paṣẹ naa.
Ọgagun Musa sọ pe Aarẹ Tinubu lo dari ipade to ti paṣẹ ọhun nile agbara, niluu Abuja, eyi to pa fun gbogbo olori ẹṣọ alaabo pata.
Tinubu tun paṣẹ fun wọn pe ki wọn ri I daju pe ko si ibudo ajinigbe kankan ni Naijiria mọ.
Bakan naa lo ni Aarẹ paṣẹ pe kawọn ẹṣo alaabo ri I daju pe aabo wa fawọn ọmọ Naijiria lati dibo loṣu Kin-in-ni ọdun to n bọ.
"Aṣẹ ti aarẹ pa fun wa ni pe:
"Gbogbo wa gbọdọ jade ka si gba gbogbo awọn ti wọn ti ji gbe kalẹ nibikibi ti wọn ba wa.
"Ko gbọdọ si ipagọ agbesunmọmi tabi bandiiti kankan nibikibi ni Naijiria mọ."
Bẹẹ ni Minisita eto aabo wi.




























