Ọwọ́ tẹ afurasí márùn ún tó jí àwọn àgùnbánirọ̀ láti Ibadan gbé ní Imo

Oríṣun àwòrán, NYSC
Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ afurasi marun un lori ẹsun pe awọn lo wa nidi ijinigbe awọn arinrinajo to n lọ fun agunbanirọ nipinlẹ Imo laipẹ yii.
Aṣeyọri yii lo waye lẹyin ajọsẹpọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ agbofinro mii.
Ilu Port Harcourt, to wa nipinlẹ Rivers ati ipinlẹ Abia ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi ọhun lẹyin ajọṣepọ awọn agbofinro.
Igbesẹ titọpinpin wọn titi ti ọwọ fi tẹ wọn lo waye laarin ọjọ kẹwaa si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii.
A gbọ pe mẹta ninu awọn afurasi naa lo salọ amọ wọn ti kọkọ fara gbọta ibọn agbofinro.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti awọn afurasi naa ji ogun arinrinajo gbe loju ọna marosẹ Owerri si Onitsha lasiko ti wọn n lọ fun ipagọ agunbanirọ ni ipinlẹ Imo.
Ilu Ibadan, ni ipinlẹ Oyo ni awọn ọdọ ọhun ti gbera lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun yii ki awọn afurasi ọhun to da ọkọ akero wọn lọna.
Ipinlẹ Abia ati Akwa Ibom ni wọn n lọ fun ipagọ agunbanirọ.
Ilu Umunoha, to wa ni ijọba ibilẹ Mbaitoli ni wọn ti kọlu ọkọ akero meji to ko awọn eeyan naa ti wọn si n bere obitibiti miliọnu owo itusilẹ wọn lẹyin naa.
Nigba ti yoo di ọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun ni wọn doola awọn agunbanirọ naa ni ilu Amakohia-Ubi, to wani ijọba ibilẹ Owerri West, lẹyin naa ni awọn agbofinro ti n wa awọn afurasi ọhun.
Ijọba Imo sọ pe awọn ko san owo kankan fun awọn ajinigbe naa ki wọn to doola awọn eeyan naa ọhun.
Amọ awọn obi wọn sọ fun awọn akọroyin pe awọn san owo itusilẹ, koda, wọn ni awọn kan lara wọn san owo ti iye rẹ to miliọnu mẹfa naira ki wọn wọn to gba itusilẹ ọmọ wọn.
Lẹyin naa ni wọn sọ pe ijọba ti da owo itusilẹ ti wọn san pada.



























