Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà buwọ́lu N500bn owó ètò ààbò pàjáwìrì láti ṣẹ́gun ìgbésùnmọ̀mí

Aarẹ Bola Tinubu. O wọ agbada alawọ aro, o de fila alawọ kan naa, o lo igo soju, o si kawọ rẹ mejeeji sori tabili bo ṣe n rẹrin-in muse ninu aworan yii.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti buwọlu owo ti iye rẹ jẹ ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira (₦500 billion) gẹgẹ owo ti wọn yoo lo lati ṣẹgun ai si aabo ati igbesunmọmi to gbilẹ kan lorilẹede yii.

Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni igbesẹ naa waye.

Eyi waye lẹyin ti igbimọ to n ri si bi wọn ṣe n pin owo 'Federation Account Allocation Committee' (FAAC), fẹnuko lati mu owo naa ninu asunwọn wọn.

Ayọkuro owo naa ni iroyin sọ pe o waye ṣaaju owo oloṣooṣu ti wọn maa n pin laaarin ijọba apapọ, ipinlẹ ati tawọn ibilẹ.

Bakan naa ni iroyin sọ pe awọn kọmiṣanna eto inawo lati awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, ti wọn jẹ ọmọ igbimọ FAAC, mọ nipa iyọkuro owo yii.

Gbogbo rẹ wa fun lati tete ji giri si ijinigbe, iṣekupani ati eto aabo to ti mẹhẹ lorilẹede Naijiria bi wọn ṣe sọ.

Ìṣúná owó

Akọsilẹ kan lati ọdọ FAAC, fi han bi wọn ṣe yọwo loṣu Karun -un ọdun yii lasiko ijọkoo awọn igbimọ naa.

Bi akọsilẹ naa ṣe wi:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

₦250 billion ni wọn ya sọtọ fun idasi awọn ologun, nigba ti wọn ya ₦252 billion mi-in kalẹ fun idagbasoke nnkan amayedẹrun.

Bakan naa ni wọn yọ ₦450 billion si asunwọn owo ori epo .

Eyi waye lẹyin ikede FAAC, pe oun pin ₦2.3 trillion fun ijọba apapọ, ipinlẹ atawọn ijọba ibilẹ eétàdínláàdórin ó lé mẹ́rin (774) ninu owo to wọle loṣu Karun-un ọdun 2026.

Ninu atẹjade ti Bawa Mokwa, Adari ikede lọfiisi oluṣiro owo agba fun Naijiria fi sita l'Ọjọru, o fidi ẹ mulẹ pe ₦2.30 ni wọn pin fun ẹka ijọba mẹtẹẹta yii.

O ni afikun ba owo naa pẹlu ₦43 billion,lati ₦2.26 trillion ti wọn pin loṣu to kọja.

Bakan naa ni akọsilẹ tun ṣalaye afikun to ba owo oṣu Kẹrin, yatọ si ti oṣu Kẹta ọdun yii.

Amọ loju iwoye ọpọ eeyan nilẹ yii, pẹlu bi ijọba ṣe n ya obitibiti owo sọtọ lati ṣẹgun iṣoro aabo to, ikọlu ọlọkan-o-jọkan ko yee waye.

Ṣugbọn labẹ bo ṣe wu ko ri, iṣakoso Aarẹ Bola Tinubu sọ pe oun yoo maa mu eto aabo ni ọkunkundun, ki ọrọ aje paapaa le duro, ki ọkan araalu si balẹ si i.