Wo ìdí tí kóòtù fi fagilé ẹ̀sùn ọ̀daràn tíjọba àpapọ̀ fi kan Adeniyi Adeyemi, ọ̀gá 'ayédèrú' iléeṣẹ́ PFIPC

Matthew Adeniyi Adeyemi ninu agbada funfun. O de fila, figo soju ninu ọfiisi to jokoo si.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọjọ Aje ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kejila oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni ile ẹjọ giga ilu Abuja fagile ẹsun onikoko mẹjọ ti ijọba apapọ Naijiria fi kan Adeniyi Adeyemi, ọga ileeṣẹ PFIPC ti wọn ni ayederu ni.

Adajọ Mohammed Umar ti ile ẹjọ giga naa lo fagile ẹjọ ọhun lẹyin ti ijọba apapọ pe fun un.

Eyi lo fa a ti ijọba apapọ fi gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ giga ti ijọba apapo niluu l'Abuja, pe ki wọn bẹrẹ rẹ lati ibẹrẹ pẹpẹ, ti yoo jẹ ẹjọ tuntun.

Ki lo fa eyi?

Lọjọ Aje naa, Agbẹjọro ijọba, Amofin Rotimi Oyedepo (SAN) lo pe fun fifagi le awọn ẹsun naa.

Oyedepo ṣalaye fun kootu pe Olootu eto idajọ ilẹ Naijiria ti yẹ ẹjọ naa wo, o si ri i pe ẹsun ti ọga ọlọpaa pata fi kan Adeyemi kun fun awọn kudiẹ-kudiẹ kan.

Oyedepo sọ pe iwe ti wọn ni Adeyemi ṣe ayederu rẹ ko ju ohun ti ile ẹjọ giga ilu Abuja le ṣewadii funra rẹ lọ.

O ni ki i ṣe ile ẹjọ giga ijọba apapọ ni yoo gbọ ọ.

O tẹsiwaju pe igbesẹ lati bẹrẹ igbẹjọ tuntun ti bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, ati pe Adeyemi yoo foju bale ẹjọ lọtun.

Eyi lo ṣe rọ adajọ lati fagile ẹsun naa ni ibamu pẹlu ofin.

Lẹyin alaye agbẹnusọ ijọba, agbẹjọrọ fun olujẹjọ, Ibrahim Angulu, (SAN), ko tako aba naa, lẹyin eyi si ni Adajọ Umar fagile awọn ẹsun ọhun.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tẹ o ba gbagbe, Adeniyi Adeyemi ni wọn n ba ṣe ẹjọ lori awọn ẹsun bii igbimọpọ ati iwe yiyi.

Nọmba iwe ipẹjọ rẹ naa ni FHC/ABJ/CR/25/2025, awọn meji ti ẹnikẹni ko si ri ni ijọba jọ pe lẹjọ naa.

Awọn meji naa ni wọn pe orukọ wọn ni Femi ati Aanu, amọ wọn ko foju han lode bii Adeyemi ti ẹsun naa kan gbọngbọn.

Ijọba Naijiria kọkọ fi ẹsun dida ayederu ileeṣẹ PFIPC/PEAC kan an, eyi ti Adeniyi Adeyemi jẹ ọga agba fun.

Ijọba apapọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọfiisi naa wa nileeṣẹ ijọba apapọ, to tun ni apo ikowosi, ti akọsilẹ si fi han pe olori oṣiṣẹ ilẹ yii n buwọlu iṣẹ rẹ, sibẹ, wọn ni ayederu ni.

Adeyemi taku nigba naa, o ni ileeṣẹ oun ki i ṣe ayederu, ati pe ijọba apapọ lo yan oun.

O ni Femi Gbajabiamila, Olori oṣiṣẹ nileeṣẹ Aarẹ, mọ nipa iyansipo oun ati iwe ti wọn fi yan oun pẹlu.

Gbajabiamila ni tirẹ ni irọ ni Adeyemi pa mọ oun, o ni oun yoo pe e lẹjọ ẹsun ibanilorukọ jẹ pẹlu owo nla bi ko ba ko ọrọ rẹ jẹ.

Ọrọ pada de kootu, niwaju Adajọ Mohammed Umar ti ile ẹjọ giga to wa l'Abuja, to paṣẹ ki wọn mu un fun kikọ latiyọju sile ẹjọ.

Osu keje ọdun yii ni ile igbimo asọju gbe igbimọ dide lati wadii owo ti iye rẹ jẹ, 1.302 billion naira, ninu iṣuna ọdun 2026 ti wọn ya sọtọ fun PFIPC.

Laarin asiko naa ni olori osise ile Naijira, Esther Walson-Jack,ni oun gba ẹbi fifi ọwọ si PEAC/PFIPC.

O ni illese oun lo kuna lati se awon iwadii to ye ki won too buwolu ajọ naa.

Bakan naa ni adari kan lati ọfiisi Oluṣiro owo gba, Joshua Luka, sọ fun igbimọ naa pe ọkan lara awọn ọjẹwẹwẹ oṣiṣẹ ọdọ oun ni ko ṣe ohun to yẹ.

O ni ẹni naa lo jẹ ki Adeyemi ni lẹta kan to yẹ ko lọ ọfiisi ọga gba ileese ijọba.

Wọn pada mu Adeyemi, lẹyin ti ijọba ti kọkọ lọ gbe Baba rẹ niluu Ogbomoso, ki ọrọ naa too de ibi to de duro wayi.