'Nígbà tí awakọ̀ wa ra ọ̀bẹ lójú ọ̀nà, dúró séréséré, lara ti ń fu wá pé nǹkan máa ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà'

Ọkan lara awọn agunbanirọ ti awọn ajinigbe to n lọ si ilẹ baba wọn tawọn ajinigbe ji gbe ni ipinlẹ Imo ti ba BBC sọrọ lori ohun ti wọn la kọja ninu irinajo wọn ki wọn to ko sọwọ awọn ajinigbe naa.
Ọmọbinrin naa to n sọrọ pẹlu ijaya sọ fun BBC News Yoruba pe lati igba ti awọn ti n lọ loju ọna ni awọn ti n fura pẹlu bi awakọ naa ṣe n duro loju ọna.
O sọ pe nigba ti awọn n lọ ni awakọ naa ra ọbe tuntun loju ọna, to si n duro lawọn aaye kọọkan lati ra awọn nnkan ti awọn ko mọ.
O ṣalaye pe nigba ti awọn de ilu Ọrẹ nibi ti ọpọ ọkọ ti maa n duro, awọn ko duro nitori awọn ti duro fun ọpọ wakati tẹlẹ, ti awọn si n tẹsiwaju pẹlu irinajo naa.
O fi kun pe ilu Onitsha ni awọn ti duro lati sun mọjumọ ki awọn to tẹsiwaju ninu irinajo naa ni owurọ ọjọ keji.
O ni oun ko mọ nnkankan mọ titi ti awọn fi ko sọwọ awọn ajinigbe nitori oun ti sun lọ, ti wọn si ko awọn rin ninu igbo.
O ṣalaye pe lati igba ti awọn ajinigbe naa ti n ko awọn rin lati owurọ ti wọn ji awọn gbe, awọn ko duro titi di owurọ ọjọ keji ki wọn to maa sọ fun awọn lati maa kan sawọn ebi wa.
'Ìjínigbé ọmọ mi fún mi ní ẹ̀jẹ̀ rúru, àwọn ohun tí mo là kọjá rèé'
Okan lara awọn obi agunbaniro ti awọn ajinigbe jigbe loju ọna Imo si Abia ni ọjọ Kiini, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 lasiko ti wọn n lọ si ibudo ifinimọle ni ipinlẹ Imo ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ṣaaju ki awọn ọmọ naa to gba itusilẹ kuro ni ahamọ ajinigbe.
Arabinrin Halimat Akande sọ pe niṣe ni oun ni ifunpa giga lẹyin iṣẹlẹ naa, to si jẹ pe oun kii ni ipenija ilera naa ṣaaju ki iṣẹlẹ naa to waye.
Akande tun ṣalaye pe yatọ si oun, ọpọ awọn obi lko koju ipenija ilera kan tabi omiran lẹyin ti wọn gba ipe ijaya pe awọn ọmọ wọ ti bọ sọwọ awọn ajinigbe.
O ṣalaye pe ojiji ti iroyin naa ba awọn mu ki ọpọlọpọ awọn obi ni ipenija ilera eyi ti ọpọ wọn n tọju bayii.
"Emi gẹgẹ bi ẹnikan, mi o ni ifunpa giga ri laye mi ṣugbọn lẹnu igba ti ọrọ yii ṣẹlẹ ifunpa mi wọ 150 ko da bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii, ara mi ṣi n gbọn.
"Lara awọn obi ti a jọ sare kaakiri nigba ti o fi ma di ọjọ mẹta ko le jade ninu ile mọ, ki a wa ma i ti gbọ ohun awọn ọmọ wa titi di asiko yii, ki ni ko ba ṣẹlẹ si wa?"
Nigba to n sọrọ lori bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, Akande ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ati bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ.
O sọ pe awọn ibeji oun ni wọn lọ gbera lọjọ kiini ninu oṣu Kẹwaa lati lọ si ipagọ ti wọn pin wọn si fun agunbanirọ ni ipinlẹ Enugu ati Abia.
O ṣalaye pe Taiwo gbera lọ si Enugu nigba ti Kehinde si n lọ si Abia ni deede aago mẹsan-an owurọ.
O ni ẹgbọn awọn ibeji naa ṣamulo GPS lati fi maa mọ ibi ti awọn mejeeji de ninu irinajo wọn ti awọn si n sọrọ bi wọn ṣe n lọ ninu irinajo wọn.
O ni nigba ti o di bii aago mẹta oru ni oun dide lati mọ ibi ti wọn de ṣugbọn ti ko si ẹnìkankan ninu awọn mejeeji to gbe ẹrọ ibanisọrọ wọn ti oun si ro boya wọn ti sun ni amọ nigba ti o di aago marun-un ti oun tun dide ni oun oun ri atẹjiṣẹ pe awọn ti ko sọwọ awọn ajinigbe.
"Loju ẹsẹ ni mo bẹ sita lati ke fun gbogbo ọmọ orile-ede Naijiria lati gba mi bi mo ṣe n lọ si ile-iṣẹ amohunmaworan, ni mo lọ ile-iṣẹ radio lẹyin naa ni mo gba ibudokọ ti awọn ọmọ naa ti wọkọ lọ láti fi to wọn lati pe iṣẹlẹ ti ṣẹlẹ si awọn ọmọ wa."
"Ibẹru pe ki wọn ma fi iya jẹ awọn ọmọ wa ni a kọkọ ṣe wa owo ti wọn beere fun"
Nigba to n sọrọ lori bi awọn ajinigbe naa ṣe kan si wọn lati beere fun owo itusilẹ, o ṣalaye pe loootọ lawọn ajinigbe naa ba awọn dunaadura, ti wọn si ja owo naa walẹ lati aadọta miliọnu naira si million marun-un naira ti gbogbo wa si ṣe igbiyanju lati ri owo naa.
"Ibẹru pe ki wọn ma fi iya jẹ awọn ọmọ wa ni a kọkọ ṣe wa owo ti wọn beere fun wọn nitori a o mọ ipo ti awọn ọmọ wa nigba naa ki wọn ba fi iya jẹ wọn."
O fi kun pe gbogbo awọn ẹṣọ alaabo patapata ni wọn ṣe iṣẹ takuntakun lati gba itusilẹ awọn ọmọ naa ṣugbọn ara abiyamọ n ta ọpọlọpọ awọn, ti awọn si gbiyanju lati da owo laaarin ara awọn lati fun awọn ajinigbe naa.
"Gbogbo ọrọ ti wọn sọ ni gbogbo igba naa ni ko ba wa l'ara mu pe awọn n ṣiṣe lati gba awọn ọmọ wa jade, eyi lo jẹ ki awa naa maa ṣe igbiyanju lati ọdọ ara wa lati le jẹ ki awọn ọmọ wa tete jade ni ọwọ awọn ajinigbe.
"Ọmọ mi sọ fun mi ni owurọ ọjọ Ẹti ti o bami sọrọ pe ni oru mọ ju inu ọjọ ni awọn wa ti oun o si ro pe oun le lo ọjọ kan si mọ lọdọ awọn ajinigbe ti oun wa.
"Gbogbo ọrọ yẹn lo n d'ẹru b'awa ti awọn naa fi ṣe igbiyanju ti wa ṣugbọn awọn ẹṣọ alaabo patapata ni wọn ṣe daadaa ti wọn si b'awa gba awọn ọmọ wa sile l'ayọ ati alafia."
'Mi o le gba ki ọmọ lọ ṣe agunbanirọ ni ilu mii mọ'
Arabinrin Akande ni pẹlu ohun ti oju awọn ti ri lẹnu igba ti ọmọ oun w ani ahamọ ajinigbe naa, oun ko le gba ki ọmọ tun pada si ipinlẹ naa fun eto sinsin ile baba rẹ.
"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ọmọ mi ti de pada l'ayọ ati alafia sugbọn wi pe ki ọmọ mi tun pada si ilu yẹn lati lọ ṣe kini?
"Ọmọ ko le pada lọ si agbegbe yẹn mọ lati lọ sin ilẹ baba rẹ mọ, iku to ba fẹ pa'ni ti o ba ṣini ni fila ọpẹ lo yẹ.
"Emi kan fẹ bẹ ijọba apapọ lati wa ojutuu si gbigbe ti wọn gbe awọn ọmọ lọ si ọdọ awọn ẹya miran nitori pe wọn kan fi ẹmi awọn ọmọ wa weyu ni.
"Ki awọn ọmọ Ilẹ Yoruba maa ṣe agunbanirọ nilẹ Yoruba ki awọn Igbo maa ṣe agunbanirọ ti wọn naa ni ilẹ wọn ki awọn Hawusa naa ma ṣe ni ilẹ ti wọn naa nitori pe a o dawa bakan naa.
"Nigba ti ko ti si ọrọ ajinigbe ni orile-ede Naijiria ọkan balẹ nigba naa ko da bi a ko ba i tii gbọ ohun ẹni wa ni gbogbo igba naa ọkan si ma balẹ wi pe o si maa pe wa ti gbogbo ọrọ ti o ba lọ ba yanju ṣugbọn ni asiko yii a n bẹẹ ijọba apapọ lati ṣe atunto si ọrọ agunbaniro ti o wa l'ode yii."




























