Kókó ẹ̀sùn tí ọlọ́pàá fi kan pásítọ̀ tó 'fẹ́ jí' òkú Toluwanisings ní mọ́ṣúárì

Oríṣun àwòrán, Toluwanisings/Instagram
Pasitọ to gbiyanju lati ji oku akọrin ẹmi to doloogbe, Olayemi Bayonle Bolaji tawọn eeyan mọ si Toluwanisings, ti dero ọgba ẹwọn nipinlẹ Oyo.
Pasitọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni, Moses Idowu, ni ọlọpaa ṣafihan rẹ pẹlu akọroyin kan, Oladapo Joshua Dunmininu lori oniruuru ẹsun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ọgbẹni Idowu lọ sibi ti oku Toluwanisings wa lẹyin to sọ pe oun lagbara lati ji i dide.
Awọn ọlọpaa ni pasitọ yii ṣe fidio oku akọrin ẹmi naa, o si gbe e sori ayelujara lai gba aṣẹ lọwọ ẹbi oloogbe.
Wọnyii lawọn ẹsun ti wọn fi kan Wolii Idowu ati akọroyin Dunmininu
Lara ẹsun ti wọn fi kan wolii Idowu ati akọroyin Dunmininu ni pe wọn gbe iroyin to le bani lorukọ jẹ jade nipa oṣẹlẹ iku Toluwanisings.
Ẹsun miran ti wọn tun fi kan wọn ni pe wọn parọ lori iku Toluwanisings, eyi to le da alaafia ru lawujọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun fẹsun kan Wolii Idowu pe o ni iyawo oloogbe, Arabinrin Olayemi Elizabeth Damilola ati alabaṣiṣẹpọ oloogbe lo jẹ ki Toluwanisings ku lai si ẹri.
Lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ka awọn ẹsun yii ni ile ẹjọ paṣẹ wi pe ki wọn ju pasitọ naa si ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ rẹ yoo fi waye lọjọ keji oṣu Kejila to n bọ.
Lori ọrọ akọroyin Dunmininun ni tiẹ, ọlọpaa mu un lori ẹsun wi pe o sọrọ ninu fidio kan lọjọ kejila oṣu Kọkanla yii pe alabaṣiṣẹpọ atawọn ẹbi Toluwanisings lo ṣeku pa a.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ni Dunmininu tẹsiwaju lati maa gbe oriṣiiriṣii fidio jade, eyi ti kii ṣe ootọ, lẹyin ti ọlọpaa ati ẹbi oloogbe ti kilọ fun gbogbo eeyan lati dẹkun gbigbe fidio to jẹ irọ nipa iku Toluwanisings jade.
Ẹsun onikoko mẹta to da lori gbigbe iroyin ofege jade lori Facebook, pinpin iroyin to le bani lorukọ jẹ ati da alaafia ilu ru jade.
Ileẹjọ sun igbẹjọ akọroyin naa si ọjọ kọkanla oṣu Kejila ọdun yii.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa kilọ fawọn eeyan wi pe ki wọn yago fun gbigbe iroyin ofege jade ati pinpin aworan eeyan to ba ti ku.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun rọ araalu wi pe ki wọn dẹkun gbigbe iroyin to le da omi alaafia ilu ru jade lori ayelujara.
Ko lo ṣẹlẹ lori ọrọ beeli ti wolii Idowu ati akọroyin Dumininu fi dero ọgba ẹwọn?
Akọroyin Joshua Oladipupo to n jẹjọ lori ẹsun gbigbe iroyin ofege lori iku Toluwanisings kuna lati ri beeli gba nile ẹjọ majisireeti niluu Ibadan.
Ileeṣẹ iroyin NAN fidii rẹ mulẹ pe Oladipupo loun o jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Majisireeti Oluwabusayo Osho paṣẹ pe akọroyin naa gbọdọ mu N2m wa pẹlu oniduro meji fun beeli rẹ.
Adajọ Osho tun paṣẹ wi pe awọn oniduro meji ọhun gbọdọ jẹ ibatan Oladipupo, wọn si gbọdọ ni ilẹ lagbegbe ti ile ẹjọ wa.
Majisireeti wa paṣẹ wi pe ki wọn fi akọroyin naa si ọgba ẹwọn Agodi n'Ibadan titi ti yoo fi ri gbogbo nnkan ti ileẹjọ n beere fun beeli rẹ.



























