Ṣé gbogbo àgbáyé yóò tún dojúkọ làásìgbò epo rọ̀bì tó wáyé lọ́dún 1970 bí?

Aworan obinrin to wọ aṣọ olomi aro ati funfun to n rọ epo sinu ọkọ ni New York, Amẹrika. Ọkunrin kan wa lẹyin rẹ to n rin lọ pẹlu ike epo lọwọ, bakan naa ni awọn kan to lori il lẹyin rẹ kan naa.

Oríṣun àwòrán, James Pozarik/Liaison via Getty Images

Àkọlé àwòrán, The oil crisis in the 1970s sparked a global economic and financial crisis
    • Author, Rachel Clun
    • Role, Business reporter
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oju ọna Strait of Hormuz ti wọn gbe ti pa lori omi okun fun bi oṣu kan bayii, eyi ti ko jẹ ki ọpọ orilẹede ma ri epo rọbi gbe lọ kaakiri agbaye mọ ti n ṣakoba fun ọrọ aje awọn orilẹede lagbaaye papaa julọ lori ọrọ epo.

O ṣee ṣe ki ogun to n lọ lọwọ lẹkun Middle East naa ṣakoba to pọ ju nnkan to ṣẹlẹ lọdun 1970 siwaju lọ.

Lars Jensen to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa irinajo ọkọ oju omi ati ọga agba tẹlẹ ri nile iṣẹ Maersk sọ fun BBC wi pe ipa ti ogun Israel-Amẹrika ati Iran yoo ni lori ọrọ aje agbaye le buru ju nnkan to ṣẹlẹ lọdun 1970 siwaju lọ.

Jensen sọrọ yii lẹyin ti adari ajọ IEAFB to n ri sọrọ epo rọba lagbaye sọ loṣu to kọja wi pe ogun to n ṣẹlẹ ni ẹkun Middle East le ṣokunfa rogbodiyan to buru julọ lagbaaye lẹka epo rọbi.

Rogbodiyan to ṣẹlẹ lori ọrọ epo rọbi lọdun 1970?

Rogbodiyan to ṣẹlẹ lọdun 1970 lori ọrọ aje epo rọbi yatọ si nnkan to n lọ lọwọ bayii, gẹgẹ bi onimọ nipa eto ọrọ aje, Ọmọwe Carol Nakhle, to jẹ ọga agba ile iṣẹ Crystol Energy ṣe ṣalaye fun BBC.

Ni oṣu Kẹwaa ọdun 1973, agbarijọpọ awọn orilẹede Araabu to n ta epo rọbi silẹ okeere fofin de awọn orilẹede kan ti Amẹrika ko wọn sodi ti wọn n ṣatilẹyin fun Israel lasiko ogun Yom Kippur.

Eyi si tun ni i ṣe pẹlu iye epo rọbi ti wọn gbọdọ maa wa lati ilẹ.

Nakhle sọ pe ohun to ṣẹlẹ nigba naa ni pe owo epo di ilọpo mẹrin iye ti wọn n ta a lagbaye lasiko naa.

O ni eyi lo jẹ ki ọpọ orilẹede to n ra epo lati ilẹ okeere bẹrẹ si ni ṣọ epo lo, eleyii si ṣakoba fun ọrọ aje awọn orilẹede agbaye.

Oluwadii ni ile ẹkọ giga fasiti Belfast, Ọmọwe Tiarnan Heaney sọ pe ọwọngogo epo ti ṣokunfa bi nnkan ṣe wọn kaakiri agbaye bayii.

"Eyi ni ipa to buru lori eto awujọ kaakiri agbaye pẹlu oniruuru ikọlu ado oloro, ti iṣẹ ati oṣi tun pọ si bi ọpọ idile ṣe n gbiyanju lati ri nnkan jẹ," o sọ.

Orilẹ ede Amẹrika àti UK ni airajaja eto ọrọ aje ṣakoba fun laaarin ọdun 1973 si 1975, pẹlu ipenija to fa iṣubu eto iṣejọba Ted Heath lọdun 1974.

Ki ni laasigbo to n waye lẹka epo rọbi bayii?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati igba ti US ati Israel ti n gbogunti Iran lati bii oṣu kan sẹyin, Iran ti ti oju ọna Strait of Hormuz pa, igbesẹ to ti n nipa lori irinna epo.

O ti ṣe idiwọ gbigbe epo rọbi, gaasi atawọn ohun mii gba awọn orilẹ ede Gulf, ibi ti wọn maa n gbe ida kan ninu ida marun-un ti gbogbo epo rọbi agbaye maa n gba kọja.

Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti n wa gbogbo ọna lati jẹ ki epo rọbi gba ọna naa kọja pada, to si n beere iranlọwọ awọn orilẹ ede ti wọn jọ ni aṣepọ lati fi awọn ọmọ ogun ranṣẹ lati da aabo bo oju ọna naa.

Bakan naa lo tun dunkoko lati tunbọ ṣe ikọlu si Iran si ti wọn ko ba jẹ kawọn ọkọ oju omi to gbe epo gba ọna naa kọja.

Amọ Jensen to n ṣe akoso eto irnna ori omi Vespucci Maritime sọ fun BBC pe ọpọ epo rọbi to ti kuro lawọn orile ede Gulf lati bii oṣu kan sẹyin ṣẹṣẹ n balẹ sawọn ibudo ifọpo ni ati pe o maa to tan.

"Fun idi eyi, aisi epo rọbi to wa tẹlẹ ṣẹṣẹ maa pọ si koda bi wọn ba ṣi oju ọna Strait of Hormuz ni ọla.

"A maa koju ipenija ohun amuṣagbara, kii ṣe lasiko ti ogun ba n lọ lọwọ nikan bikoṣe lẹyin oṣu mẹfa si ọdun kan ti ogun naa ba ti pari."

Ṣe o ṣeeṣe ki laasigbo epo yii lagbara ju ti ọdun 1970 lọ?

Nakhle, to tun jẹ akọwe apapọ fun ẹgbẹ Arab Energy Club sọ pe ọja epo ti pọ bayii lọja agbaye ju ti ọdun 1970 lọ, to si jẹ pe iye epo tawọn eeyan n lo ti din ku jọjọ.

O gbagbọ pe bi o tilẹ jẹ pe owo epo n lọ soke pupọ, o ni eyi to n ṣẹlẹ bayii ko to ohun to ṣẹlẹ nigba naa.

"Bi o tilẹ jẹ pe iye epo ti ogun n ṣe idiwọ fun pọ bayii – eyi to wa lara awọn eyi to pọ ju ni agbaye - ọja agbaye ni awọn ọna mii lati gbe epo gba ju ti ọdun 1970 lọ."

Ṣugbọn Joel Hancock, adari ẹka iwadii lori awọn ọja ni Natixis CIB sọ pe iyatọ kan to foju han ni pe awọn orilẹ ede to ti goke agba, ti wọn ti to tan, ti wọn ni ọna lati ṣakoso rẹ ni laasigbo ọdun 1970 doju kọ.

O ni ikọlu to n waye lasiko yii n ṣakoba fawọn orilẹ ede ti wọn ṣẹṣẹ n goke, ti ko ni owo atawọn ileeṣẹ lati ṣakoso ipenija naa bo ṣe yẹ.

Hancock ni gbogbo ipenija to n waye lẹka epo rọbi lo maa wa sopin ni kete ti ogun ti Amẹrika ati Israel n gbe ti Iran ba ti wa sopin.

Heaney woye pe iyatọ kan to wa lonii, to si n jẹ anfaani fawọn orilẹ ede agbaye ni pe o jẹ ki ọpọ orilẹ ede mọ bi eto ọrọ aje wọn ṣe n ṣiṣẹ, ti ọpọ wọn si n ni epo ni ipamọ.

"Ohun to dara bayii ni ki ogun pari kiakia, ki iduro ire sib a ẹka epo rọbi."