Rògbòdìyàn tó ń wáyé lemọ́lemọ́ níbi ìwọdé, Ààrẹ Tinubu tẹ pẹpẹ ìkìlọ̀

Aworan AarẹTinubu ati aworan ero nibi ipade iwọde kan.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ fawọn ẹṣọ alaabo lati koju rogbodiyan yowu to ba n jẹ jade lagbo oṣelu, to si le ṣe akoba fun ijọba awaarawa.

Tinubu paṣẹ yii latari bi rogbodiyan ati iwa janduku ṣe n gbilẹ si I lagbo oṣelu, ṣaaju idibo ọdun 2027 to n bọ lọna.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ fi soju opo X rẹ lọjọ Ẹti lo ti koro oju si jagidijagan to n waye lawọn ibudo ipolongo ibo.

Ikede naa n waye lẹyin tawọn kan kọlu ẹgbẹ alatako Nigeria Democratic Congress (NDC) nibi ipade ẹgbẹ wọn to waye niluu Eko laipẹ.

Eyi kọ ni igba akọkọ ti awọn janduku yoo da rogbodiyan silẹ lasiko iwọde tabi ipagọ oṣelu.

Awọn rogbodiyan to ti waye

Awọn eeyan to n fa ara wọn nibi ipolongo ibo

Rogbodiyan to waye laipẹ yii niluu Eko ni ọpọ alẹnulọrọ koro oju si.

Lọjọ kejila oṣu Kejila ọdun 2026 ni awọn kan kọlu awọn ọmọ ẹgbe oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) lagbegbe Oregun, ipinlẹ Eko.

Niṣe ni ọpọ eeyan to wa sibi eto naa bẹrẹ si I sa asala fun ẹmi wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn fọ igo silẹ kaakiri ibudo ti eto naa ti waye, awọn afurasi ọmọ ita to wa nibẹ si ba ọpọ mọto to jẹ tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NDC to wa nibẹ jẹ.

Ni ipinlẹ Gombe, lọjọ kọkanla oṣu Kọkanla yii ni awọn afurasi janduku da ina taya soju ọna, wọn si fọ awon gilasi ọkọ Isa Pantami to n dije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ PDP nipinlẹ naa.

Eyi waye lasiko ti oloṣelu naa wa siluu rẹ fun ipolongo ibo.

Ni Katsina, awọn afurasi janduku kọlu ẹgbẹ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC, lasiko ti wọn n lọ so ibi ipolongo ibo fun Gomina Dikko Radda.

Awọn ọlọpaa sọ pe niṣe ni awọn ero di oju ọna pa ni Yankara, wọn si bẹrẹ si I ju okuta, bẹẹ ni wọn n dana sun awọn iwe alẹsode ipolongo ibo lẹyin ti Gomina Dikko Radda kọja loju ọna ọhun lọ si ibi ipolongo APC ni Faskari.

Awọn eeyan farapa lẹyin tawọn janduku dana sun awọn ọkọ.

Bi African Democratic Congress ṣe koju ikọlu tiẹ naa lo ṣe kan PDP nibi awọn ipolongo ibo to waye lawọn ilu bii Enugu, Benue, Delta, Edo ati Sokoto.

A ko ni fi aaye gba iwa janduku kankan - Tinubu

Lori awọn rogbodiyan yii, Aarẹ Tinubu sọ pe gbogbo bo ṣe n ṣẹlẹ ni oun n gbọ, oun ko si ni i fi aaye gba rogbodiyan oṣelu kankan.

"Gẹgẹ bii olori orilẹede yii, mo fi ara mi jin fun ibo alaafia ti yoo lọ ni irọwọ-rọsẹ, mo si ti rọ awọn olori oṣelu atawọn alatilẹyin wọn lati huwa bii ọmọluabi."

Tinubu sọ pe jijẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọtọọtọ ko tumọ si pe ki eeyan di ọta ẹnikeji rẹ, bi ko ṣe ki wọn jọ wa ilọsiwaju orilẹede wọn.

Aarẹ sọ pe oun ti paṣẹ fawọn ẹṣọ alaabo lati fi ọwọ lile mu awọn to ba n da rogbodiyan silẹ, atawọn to n huwa to tako alaafia ijọba awaarawa.