Toluwanisings, Bunmi Omije Ojumi, Taiwo Adegbodu àtàwọn olórin ẹ̀mí mí-ìn tó ti kú ní 2026

Oríṣun àwòrán, Toluwanisings/Facebook/ Bunmi Akinnanu/Facebook/ Taiwo Adegbodu/Facebook
Bi ọdun tuntun ba de, gbogbo eeyan a fogo fun Oluwa fun riri ọdun, amọ ko si eeyan to mọ ọdun aṣegbẹyin, ko si sẹni to mọ boya oun yoo ri opin ọdun toun n ba wọn yọ pe o de gan-an.
Ni 2026 to n pari lọ yii, ọpọ eeyan lo bẹrẹ rẹ lọjọ akọkọ ọdun naa pẹlu ayọ ati idunnu, amọ to jẹ lasiko yii, wọn ti kọja si ajule ọrun.
Lara ibi ti iku ti ṣọṣẹ bẹẹ ni agboole orin awọn onigbagbọ, awọn akọrin ẹmi kan ko si mọ lonii lara awọn to ri ibẹrẹ ọdun 2026.
Eyi ti iroyin rẹ gbode lọwọ ni iku Toluwanisings, iyẹn akọrin ẹmi ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Olayemi Bayonile Bolaji.
Amọ ṣaaju ti Toluwanisings, eyi ni awọn olorin ẹmi to ti papoda ninu ọdun 2026 yii:
Bunmi Akinnaanu-Adeoye (Omije Ojumi)

Oríṣun àwòrán, Bunmi Akinnanu/Facebook
Bunmi Akinnaanu tawọn eeyan mọ si Omije Ojumi, jade laye lọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026, nileewosan kan nipinlẹ Eko.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ni Oloogbe naa nigba to papoda.
Ohun ti a kọkọ gbọ pe o n ṣe e ni pe ẹsẹ n dun un, wọn si gbe e lọ si ṣọọṣi kan ti wọn ti n gbadura fun un.
Lẹyin eyi ni Omije Ojumi pada sileewosan, nibi to pada dakẹ si. Ọkọ ati ọmọ meji lo fi saye lọ.
Taiwo Adegbodu
Ibeji ni Oloogbe yii jẹ fun Kehinde Adegbodu ti wọn jọ n kọrin ẹmi.
Ṣadeede ni iroyin iku Taiwo Adegbodu gbode lọjọ kin-in-ni oṣu Kẹta ọdun 2026.
Gẹgẹ bi Kehinde rẹ ṣe kede nigba naa, o ni ko si kinni kan to ṣe Taiwo tẹlẹ, ju pe o wa si yara oun ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ naa, o si ni aya n dun oun.
Wọn gbera o di ileewosan, amọ lori aga ti Taiwo jokoo si lọsibitu naa lo dakẹ si bi Kehinde ṣe sọ.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọta (46) ni i ṣe.
Toun Soetan

Oríṣun àwòrán, Toun Soetan Instagram
Agba ọjẹ olorin ẹmi ni Arabinrin Rachael Olatoun Soetan.
O jade laye lẹni ọdun mẹtalelaadọrin (73), loṣu Kẹta ọdun 2026.
Ọkan lara awọn to bẹrẹ orin ẹmi ni Oloogbe Toun Soetan, o si le ni ogoji ọdun to fi kọrin.
Toluwanisings:

Oríṣun àwòrán, Toluwanisings/Facebook
Agbọsọgbanu ni iku Olayemi Bayonile Bolaji tawọn eeyan mọ si Toluwanisings.
Bi iroyin iku naa ṣe gbode lọjọ kẹrinla oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni ọpọ eeyan ti n gbadura pe ko gbọdọ jẹ bẹẹ.
Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kẹẹẹdogun oṣu yii kan naa, awọn ẹbi olorin ẹmi tọpọ eeyan fẹran naa kede iku rẹ.
Bẹẹ lo si ṣe ti gbogbo aye n daro ọmọkunrin to ti n ba irinajo rẹ bọ fọdun pipẹ, ṣugbọn to papoda nigba ti ogo rẹ ṣẹṣẹ n buyọ.
Bi akọsilẹ ṣe fi han, ẹni ọdun mọkanlelogoji (41) ni Toluwanisings.
Ki i ṣe pe o ṣe aarẹ ki ọlọjọ too de, o ṣubu lori akasọ ninu ile rẹ ni iroyin sọ.
Wọn gbe e digbadigba de ọsibitu bii mẹjọ, amọ wọn ko gba a, nibi ti wọn si ti jaja gba a ni wọn ti sọ pe oku ni wọn gbe wa.
Toluwanisings fi iyawo atawọn ọmọbinrin meji ti ọjọ ori wọn ko to nnkan silẹ saye, titi dasiko yii si ni iku rẹ ṣi n ṣe ọpọ eeyan ni haa.


























