Wo ọ̀pọ̀ àǹfààní ẹyẹ Igún àti ewu tó wà nínú bí ẹyẹ náà ṣe ń tán lọ nílẹ̀ wa
"Awọn eeyan bẹrẹ sii pe mi ni "Ezeudene", eyi ti o tumọ si 'Ọba Igun'.
N ko si le salọ, ni wọn igba ti mo mọ pe niṣe ni mo n ja fun ohun adanida gẹgẹ bi o ti yẹ."
Ọkunrin yii, Chukwuemeka lo gbiyanju lati daabo bo awọn Ẹyẹ Igun.
Wọn maa n ṣe afiwe wọn pẹlu iku ati ohun to bajẹ, bẹẹ si ni ko wọpọ lati jẹ Igun ni ọpọ ilu nilẹ Afrika.
Chukwuemeka ba BBC News Yoruba sọrọ nipa awọn ẹyẹ igun to n poora yii.

"Awọn ẹiyẹ igun ni Afrika ti din ku ni iye si ida mẹtadinlọgọrun ninu ọgọrun, eyiun 97%, si bo se ri ni aadọta ọdun sẹyin"
Chukwuemeka ni "Nigba ti a n dagba ni nibi yii, mo n sọ fun yin, ọpọ awọn Ẹyẹ Igun lo fo kaakiri gbogbo ayika yii, nitori ko si ẹni to n dọdẹ wọn lati mu pa jẹ.
Abule rẹ ni Guusu-Ila Oorun Naijiria maa n daabo bo awọn Ẹyẹ Igun lati igba pipẹ...
Ṣugbọn awọn ara agbegbe mi ma n sọdẹ wọn, lati ta oku wọn fun awọn to n fi ni soogun.
Sibẹsibẹ, agọ kan ni agbegbe naa n fun wọn ni ibi abo to ṣọwọn.
Laaarin agbegbe ojubọ to wa nibi, ẹ maa rii pe awọn eeyan maa n bẹru ibi ti ojubọ naa wa.
Ko si ohun buburu kan to le ṣẹlẹ nibi.
Awọn ẹiyẹ igun ni Afrika ti din ku ni iye si ida mẹtadinlọgọrun ninu ọgọrun, eyiun 97%, si bo se ri ni aadọta ọdun sẹyin.
Ẹya ẹiyẹ igun meje ni wọn ti wa ninu ewu, ti awọn ẹya mii ti fẹ parun tan, eyi lo fa ti Chukwuemeka ṣe darapọ mọ awọn to n pese aabo fun ayika lati daabobo awọn ẹiyẹ yii
Gbogbo ibi ti awọn ọdọ ba ti pejọ, mo maa n sọ fun wọn pe Ẹyẹ Igun ni iranwọ to maa n ṣe ni igbesi aye eeyan.

"Ni awọn agbegbe ti awọn Ẹyẹ Igun ti parun tan, a ri pe awọn arun to le kọja lati ara ẹranko si eniyan ti pọ si, awọn arun yii ni a mọ si_zoonotic diseases"
Pẹlu iranlọwọ awọn to risi eto aabo ayika, Chukwuemeka n se akiyesi awọn ẹyẹ igun, o n ṣe ipolongo nipa wọn, o si n ṣiṣẹ pẹlu awọn olori agbegbe ati awọn ẹṣọ alaabo lati daabobo awọn ẹiyẹ yii.
Awọn Ẹyẹ Igun ma n sọ ayika di mimọ, wọn ni agbara debi wi pe ounjẹ maa n tete da ni ikun wọn, paapaa julọ awọn ohun to le ṣe ipalara si agbegbe wa.
Ni awọn agbegbe ti awọn Ẹyẹ Igun ti parun tan, a ti ri pe awọn arun to le kọja lati ara ẹranko si eniyan ti pọ si, awọn arun yii ni a mọ si_zoonotic diseases.
Lẹyin wi pẹ wọn n pa Ẹyẹ igun, bi wọn ṣe ṣọwọn, nii ṣe pẹlu igbagbọ awọn eeyan lẹkun Iwọ Oorun Afrika.
Ibeere fun ẹiyẹ igun ti mu ki o di owo, wọn n ta wọn kaakiri orilẹ-ede yii, pẹlu awọn orileede miran kaakiri.
Ṣugbon awọn to n ri si idaabo bo wọn, ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu awọn ara agbegbe yii so wi pe awọn n ri ami rere ni awọn apa kan ni Naijiria.
Awọn Ẹyẹ Igun to ti sọnu ti n pada, ni awọn igba kan, wọn pọ, igba to ya, wọn tun poora, ṣugbọn ni bayii, wọn ti pada de patapata.
Ohun ti a ti ṣe ni gbegbe Awka-Etiti jẹ apẹẹrẹ rere ti itan ti a n kọ, nibi ti awọn eeyan ti gba iṣakoso ayika wọn. O jẹ idunnu fun wa.






