Kí ni ìdí tí ìjọba àpapọ̀ ṣe gbẹ́sẹ̀lé ètò ìgbaniṣíṣẹ́ lọ́dún 2027?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ ti gbẹsẹle eto igbanisiṣẹ ni gbogbo ẹka ileeṣẹ rẹ fun odun 2027.
Ijọba ni eyii n waye gẹgẹ bii ọkan lara awọn eto rẹ lati bojuto iye owo to n na ati ọna ati fopin si awọn kudiẹkudiẹ to n waye ni ẹka owo oṣu sisan.
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan lati ọọfisi olori oṣiṣẹ Naijiria, eyii ti akọwe agba rẹ, Ishiyaku Musa Mohammed, buwọlu.
Gẹgẹ bii atẹjade naa to fi lede lọjọ kẹsan an, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 yii, gbogbo ileeṣẹ ijọba naa ko gbọdọ gba ẹnikẹni siṣẹ titi ọdun 2027 yoo fi pari.
Atẹjade naa fi kun pe wọn le gba eeyan lawọn ileeṣẹ ti ko fi bẹẹ si ọpọ oṣiṣẹ ti ẹri si wa pe owo ti wọn yo fi gbọ bukata afikun oṣiṣẹ naa wa nilẹ.
Ijọba apapọ tun fofin de awọn ileṣẹ rẹ pe wọn ko gbọdọ da awọn ẹka tuntun tabi ipo tuntun mii silẹ mii silẹ lawọn ileeṣẹ rẹ lai kọkọ gba aṣẹ.
Atẹjade ọhun ṣalaye pe eyikeyi ileeṣẹ to ba kuna lati fi akọsilẹ rẹ ṣọwọ ko si kin eto iṣuna rẹ lẹyin ṣeeṣe ko padanu owo to tọ si ninu eto iṣuna to n bọ.
Ki ni idi ti ijọba fi gbe igbesẹ yii?
Idi kan gboogi ti ijọba apapọ ṣe n gbe igbesẹ yii ni lati ṣakoso iye owo oṣu to n san.
Eyii n waye niwọn igba to jẹ pe gbogbo oṣiṣẹ ti ijọba ba gba ni yoo maa san owo oṣu fun, to n tumọ si pe afikun oṣiṣe yoo yọri afikun iye owo ti ijọba yoo na.
Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe ṣalaye, gbigbe gbedeke le iye oṣisẹ ti yoo gba ṣiṣẹ, ijọba n fẹ ki idi abajọ ti wọn gbọdọ fi gba awọn oṣiṣẹ naa han, ki wọn tun le fidi rẹ mulẹ pe wọn ni owo lati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ọhun.
A gbọ pe igbesẹ yii lo n waye lati fun ijọba lanfani ati fopin si awọn ayederu oṣiṣẹ to n gba owo oṣu ijọba lai ṣiṣẹ fun ijọba, iyẹn ti ọpọ mọ 'ghost workers'.
Igbesẹ ọhun tun waye ki ijọba apapọ le mọ iye oṣiṣẹ to n ba ṣiṣẹ ni pato.
Ijọba apapọ ko tun fe fopin si bi awọn ileeṣẹ rẹ ṣe n ṣadede da awọn ẹka tuntun silẹ lai kọkọ gba aṣẹ.
Ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn to n wa iṣẹ ijọba lọwọ yii?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe igbesẹ naa n tumọ si pe ijọba yoo gbẹsẹle eto igbaniṣiṣẹ, ko tumọ si pe ko ni gba eeyan siṣẹ mọ titi lai.
Awọn ileeṣẹ ijọba ti iye oṣiṣe rẹ ko to nnkan ṣi le gba eeyan siṣẹ, ti wọn ba le fidi re mulẹ pe lootọ ni wọn nilo awọn oṣiṣẹ ti wọn fẹ gba, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe owo ti wọn yoo fi gbọ bukata awọn oṣiṣẹ naa wa nilẹ.
Amọ ohun ti igbesẹ yii n dojukọ ni eto igbanisiṣẹ tuntun latiko yii ti ijọba n ṣayẹwo awọn oṣiṣẹ to wa nilẹ tẹlẹ.
Wayi o, gbogbo ileeṣẹ ijọba lanfani lati fi awọn akọsilẹ eto iṣuna wọn ṣọwọ si ijọba titi di ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 yii.
Eyikeyi ileeṣẹ to ba kuna lati ṣe bẹẹ le ma ri owo to tọ si wọn ninu eto iṣuna ọdun 2027.



























