"Àwọn agbébọn tó ń jà fún ẹ̀sìn gan ń lo òògùn ìbílẹ̀, ṣé ìjọba le fi 1000 Kùránì àti 1m Bíbélì jagun agbébọn báyìí?"

Àkọlé fídíò, Àwọn agbébọn tó ń jà fún ẹ̀sìn gan ń lo òògùn ìbílẹ̀, ṣé ìjọba le fi 1000 Kùránì àti 1m Bíbélì jagun agbébọn báyìí?
"Àwọn agbébọn tó ń jà fún ẹ̀sìn gan ń lo òògùn ìbílẹ̀, ṣé ìjọba le fi 1000 Kùránì àti 1m Bíbélì jagun agbébọn báyìí?"
Published

Ni origun mẹrẹẹrin nilẹ Yoruba ni eto aabo ti mẹhẹ, tawọn agbebọn si n soro bi agbọn, bi wọn se n ji eeyan gbe, ni n pa eeyan.

Koda, isẹlẹ naa ko yọ ọmọde, agba, ọkunrin tabi obinrin silẹ, tawọn ileesẹ agbofinro si ti sisẹ, to ti rẹ wọn.

Ọpọ awọn sọja, ọlọpaa, Amotekun, ọdẹ ibilẹ, Figilante, Asọgbo to n saayan lati mu adinku ba iwa ibi awọn agbesunmọmi yii si ni ẹmi wọn ti bọ si.

Eyi si lo mu ki ọpọ ọmọ Kaarọ oojire maa beere pe ki lawọn ẹlẹsin abalaye, ti a mọ si Ìṣẹ̀ṣe n se lati kun awọn ileesẹ alaabo lọwọ fi dẹkun iwa agbebọn?

Yoruba ni ki agbado to daye, nkan kan sa ni adiẹ n jẹ, sebi ọkan kan lawọn baba nla wa daabo bo ilu ki awọn oyinbo to de.

Idi si ree ti ileesẹ BBC News Yoruba se tọ diẹ lara awọn onisẹse yii lọ pe ki ni wn n se lati koju awọn agbebọn yii?

Awọn Onisẹse to wọ asọ funfun lati oke de ilẹ, ti wọn to lọwọọwọ tẹle ara wọn

"Ti a ba ri awọn onisẹse to jẹ olotitọ, ti kii se onisẹse ori ayelujara lasan, apa wa ka awọn agbebọn"

Ọpọ awọn Onisẹse to ba BBC News Yoruba sọrọ ni ipa awọn ka awọn agbebọn ati ajinigbe yii.

Akinojo Atayese to jẹ Olori awọn onisẹse ni ipinlẹ Ekiti fi ọwọ gbaya fun ikọ iroyin wa pe ọwọ awọn ka awọn ajinigbe ati agbesunmọmi yii.

"Ti a ba ri awọn onisẹse to jẹ olotitọ, ti kii se onisẹse ori ayelujara lasan, apa wa ka wọn.

Isẹse ko fẹ ibọn ati ada, ewe ati egbo ni wọn n pe ni Isẹse.

Sebi awọn agbesunmọmi yii, sebi inu igbo ni wọn n gbe, inu igbo naa la ti n lọ mu ewe ati egbo ti a fi n se oogun.

Ohun naa la maa ran sinu igbo naa, sebi ibọn ni ajinigbe gbe dani, sebi ilẹ ni wọn n tẹ, sebi awọn kan lo se ibọn nigba iwasẹ, o sa ni bi ibọn ati ọta inu rẹ se daye?"

Atayese wa bu ẹnu atẹ lu awọn onisẹse to fẹ lọ ba ajinigbe ja amọ ti wọn yoo kọkọ gbe sori ayelujara.

O ni awọn ajinigbe naa ni pupọ wọn kii se ọmọ onilu, bawo wa ni wọn se fẹ mọ ilu ju onilu lọ.

Akinojo Atayese to jẹ Olori awọn onisẹse ni ipinlẹ Ekiti

"Ta lo n jẹ Ajinigbe, sebi isiju wa, a maa si oju wọn kuro nilẹ Yoruba lai pariwo, wọn maa lọ"

Bakan naa, Atayese fi ọwọ gbaya pe oogun wa daadaa to le le awọn ajinigbe kuro nilẹ Yoruba.

"Ẹni to ba ni oogun lọwọ, kii pariwo, awọn eeyan ko ni mọ, amọ ti ẹ ba kan, ẹ mọ pe ọkunrin lẹ ri.

Ko si ilu ti ko ni ọba tabi onisẹse, ti wọn ba pe wa, ọwọ yoo kan ọwọ.

Ta lo n jẹ Ajinigbe, sebi isiju wa, a maa si oju wọn kuro nilẹ Yoruba lai pariwo, wọn maa lọ.

Ki awọn agbaagba ilẹ Yoruba pe wa si ipade idankọnkọ, kii se ipade ti wọn yoo ka silẹ lori ẹrọ ayaworan, ti wọn yoo maa fi ransẹ sori ayelujara, tabi Tẹlifisan.

Ọjọ ti a ba si maa se ipade yii, ẹni ti kii ba se ẹya Yoruba tabi ti ko gbọ Yoruba, ki wọn mase pe e si ipade naa.

Oogun wa daadaa to le le awọn ajinigbe kuro nilẹ Yoruba."

 Omobolaji Adifakawo, tii se Ọbarisa ti Ilorin Afọnja

"Afi ki ẹsin ma pa wa, awọn banditi ti wọn ni awọn n ja fun ẹsin kan yii, awọn gangan n lo oogun dudu"

Omobolaji Adifakawo, tii se Ọbarisa ti Ilorin Afọnja, lero tiẹ ni awọn gbọmọgbọmọ ti wa lati ọjọ to ti pẹ, o si ni bawọn baba nla wa ti sẹgun awọn gbọmọgbọmọ naa

"Ewe ati egbo pẹlu etutu ti wọn lo nigba naa si wa lati sẹgun awọn gbọmọgbọmọ si wa di isinsinyii.

Amọ wọn ti fi ẹsin aseju yi ọpọlọ awọn oloselu wa pada, ọpọ nnkan to yẹ ki wọn maa pe awọn onisẹse ati onibilẹ si, ni wọn ko fẹ ka da si mọ.

Kurani ni, Bibeli ni, se wọn le lọ gbe Kurani ẹgbẹrun kan jagun banditi bayii?

Se a le gbe Bibeli miliọnu kan fi jagun banditi bayii?

Afi ki ẹsin ma pa wa, awọn banditi ti wọn ni awọn n ja fun ẹsin kan yii, awọn gangan n lo oogun dudu.

Ti ẹ ba wo idi banditi mii, oogun dudu ti ẹ ba lara rẹ ju oogun ibilẹ Yoruba lọ."

Asiwaju Awo agbaye, Dokita Ifagbenusola Atanda, tii se olori awọn onisẹse nipinlẹ Osun

"Wọn yoo pe wa ni, wiwa la n wa Babalawo ko to rubọ fun ni, tori Babalawo kii wa ẹnikan"

Asiwaju Awo agbaye, Dokita Ifagbenusola Atanda, tii se olori awọn onisẹse nipinlẹ Osun naa salaye ọna tawọn onisẹse fi le sẹgun awọn agbesunmọmi to yi wa ka.

"Ifa, Sango, Osun n bẹ nibi to wa, sugbọn wọn yoo pe wọn ni.

Wiwa la n wa Babalawo ko to rubọ fun ni tori Babalawo kii wa ẹnikan.

Eto ti wa laarin ilu ti nnkan ba sẹlẹ, kii se babalawo nikan lo n se etutu ilu.

Ọba mọ awọn eeyan ti ọrọ kan, bi Ifa ba ni ka lọ bọ Sango, Onifa ko ni lọ bọ Sango, awọn Onisango ni yoo pe, Ọlọya ati Ọlọsun naa si ni yoo bọ orisa tiwọn.

A ti da gbogbo rẹ pọ, a ti n kere ẹnikan, a ko le kere ara wa, ika to ba tọ simu, ni a fi n ree.

Nibi ti nnkan daru de yii, ti a ba pada sidi ika to tọ simu, ki a fi re imu, gbogbo ilu yoo tu, yoo si ba."

O wa gba awọn ọmọ ilẹ Yoruba niyanju pe ki wọn se bi wọn ti n se, ko le ba ri bo se yẹ ko ri.

Eegun to da ẹku bo ori

A n bẹ ijọba ko ransẹ pe awa onisẹse gidi, yatọ sawọn to ni awọn nibọn, awọn ni 'boys', isẹse ko gba gbogbo iyẹn"

Oluwo Ifa tilẹ Egba, Ifagbeminiyi Atanda ati Oluwo Ifa ipinlẹ Ogun, Aregbesola Anipupo naa gba awọn adari to wa nijọba ni imọran lati gba awọn onisẹse laaye lati ru ẹbọ fun ilu.

"A maa n fi etutu le ibi lọ nilu ni.

Odu Ifa kan lo ni ẹ wi fun alejo ko lọ, a ti sasara bọ agbo.

A n bẹ awọn ijọba pe ki wọn ransẹ pe awa onisẹse gidi, yatọ sawọn to ni awọn nibọn, awọn ni 'boys', isẹse ko gba gbogbo iyẹn.