Mo gun alùpùpù fún ọjọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n láti London dé Nàíjíríà láti kówójọ fún ìgbógunti àìsàn Polio - Okedeyi

Àkọlé fídíò, Mo gun alùpùpù fún ọjọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n láti London dé Nàíjíríà fún ìkówójọ fún ìgbógun ti àìsàn Polio - Okedeyi
Mo gun alùpùpù fún ọjọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n láti London dé Nàíjíríà láti kówójọ fún ìgbógunti àìsàn Polio - Okedeyi
Published

Yoruba ni ẹni nla, lo maa n se ohun nla, ko si si ohun ti ẹda kan ko le se, to ba fi pinnu lati se e.

Ọkunrin kan ree, Olatunji Okedeyi, to gun alupupu lati ilu London, nilẹ United Kindom, UK wa si orilẹede Naijiria.

Okedeyi, tii se ọmọbibi ilu Ibadan ni o ti to ọjọ mẹẹdọgbọn ni oun fi wa alupupu naa lati London de Naijiria.

BBC News Yoruba ba Olatunji sọrọ nipa ohun to mu ko gunlẹ igbesẹ naa, wọn ni ti ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii dede sẹ.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keje oṣu Keje lo si balẹ si Naijiria, nibi ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti gba a lalejo.

Olatunji Okedeyi wa lori alupupu rẹ, o wọ asọ dudu alamutan lati oke delẹ, o si de akẹtẹ sori

Oríṣun àwòrán, Olatunji Okedeyi

"Orilẹede mẹrinla ni mo la kọja pẹlu alupupu, ti mo si kọja ni ẹkun orilẹede agbaye meji, tii se Europe ati Africa"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Olatunji Okedeyi salaye pe Irinajo ti oun rin naa jẹ kilomita ẹgbẹrun mejila ati igba(12,200-kilometer).

Okedeyi tawọn eeyan tun maa n pe ni Captain, ni Aarẹ ẹgbẹ Rotary Club ti Mushin, niluu Eko.

Irinajo naa lo pe ni "London to Lagos: Two Wheels, One Mission to End Polio."

Okedeyi ni bi oun se gun alupupu lati London wa si Naijiria, kii se pe oun jẹ ọmọ lile rara.

O ni ọpọ eeyan lo maa n ro pe ọmọ lile lo n gun alupupu bi eyi amọ o ti le ni ọdun mẹẹdọgbọn ti oun ti n gun alupupu naa.

"Ọjọ mẹẹdọgbọn ni mo lo loju ọna lati gun alupupu lati London wa si Naijiria, mo si bẹrẹ irinajo ọhun lati ilu London lọ si ilẹ Faranse.

Lati Faranse ni mo ti lọ si Spain, Morroco, Mauritania, Senegal, Gambia de Guinea-Bissau.

Lati Guinea-Bissau ni mo ti lọ si Guinea Conakry, mo tun pada si ẹkun guusu Senegal, ki nle kọja si Ivory Coast.

N ko fẹ wọ ilu Mali ni mo se pada gba ẹkun guusu Senegal naa nitori ogun abẹle to n waye lọwọ nilẹ Mali.

Lati ẹkun guusu Senegal naa ni mo ti kọja si Ivory Coast, de Ghana, Togo, Republic of Benin wa ja si Naijiria nibi."

Olatunji fikun pe orilẹede mẹrinla ni oun la kọja pẹlu alupupu oun naa, ti oun si kọja ni ẹkun orilẹede agbaye meji, tii se Europe ati Africa.

Olatunji Okedeyi wa lori alupupu rẹ, o wọ asọ dudu alamutan lati oke delẹ, o si de akẹtẹ sori

Oríṣun àwòrán, Olatunji Okedeyi

"Nigba ti mo n bọ, mo pade oyinbo kan to jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọrin, to n gun kẹkẹ alupupu lati Italy, lọ si Gambia"

Nigba to n sọrọ lori iru awọn eeyan to le fi alupupu se isẹ akin bayii, Olatunji ni nilu oyinbo ti oun ti wa, wọn kii fi oju ọmọ lile wo ẹni to ba n gun alupupu gẹgẹ bi wọn se maa n lero nibi.

"Nigba ti mo n bọ, mo pade oyinbo kan to jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọrin, to n gun kẹkẹ alupupu lati Italy, lọ si Gambia.

A si dijọ kọja ni aṣalẹ Sahara ni, ti wọn ba wa ni ọmọ lile lo n gun alupupu kiri, ki wa ni ka pe baba ẹni ọdun mejidinlaadọrin naa to n gun alupupu kiri?

A ni awọn eeyan to jẹ ẹni ọgọta ọdun,aadọrin ati ọgọrin ọdun ti wọn si n wa alupupu.

Koda, awa ti a n wa alupupu kiri bayii lasiko yii, kii se pe a fin n da igboro ru, amọ o ni eto, ti eeyan ba ti mọ ohun to n se.

Bakan naa, o gbọdọ mọ idi to se fẹ rinrin ajo, eyi si lo n ti mi siswaju pe ko tii si isinmi tori pe n ko tii pari irinajo naa."

Olubadan ilẹ Ibadan, ọba Rasheed Adewolu Ladoja gbalejo Olatunji Okedeyi, ni kete to gunlẹ silu Ibadan, tii se ilu abinibi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Olatunji Okedeyi

"Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rasheed Adewolu Ladoja fún wa ní ẹgbẹrun kan Pọnun lati gbogun ti aisan Polio"

Olatunji Okedeyi, ẹni to n se ikowojọ lati gbogun ti aisan rọmọlapa-rọmọlẹsẹ, ti a mọ si polio, lo gunle irinajo alupupu naa lati London wa si Naijiria lati ri owo kojọ.

Afojusun rẹ naa ni lati fi awọn owo to ba ri ko jọ lẹnu irinajo yii lati gbogun ti aisan asekupani ọhun, eyi to wọpọ nilẹ Naijiria atawọn orilẹede Afirika lapapọ.

Olatunji sọ pe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni oun ni lọkan lati fi irinajo iyanu naa ko jọ, ki arun naa le kasẹ nilẹ patapata lagbaaye.

Eto ikowojọ naa si lo mu ko se abẹwo si Olubadan ilẹ Ibadan, ọba Rasheed Adewolu Ladoja ni kete to gunlẹ silu Ibadan, tii se ilu abinibi rẹ.

Olatunji fikun pe afojusun irinajo naa si lo n ti oun siwaju, lai tii pari irinajo naa, oun ko ni le sọ pato .

"Bi Kabiyesi se fun wa ni ẹgbẹrun kan Pọnun yii, se maa le ri gba ti n ko ba pari irinajo yii, tori naa, awọn afojusun mi naa lo n ti mi lati pari irinajo ti mo gun le, to si gbọdọ pari si ayọ."