You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀dọ́mọkùrin tó fẹ́ràn láti máa já ọ̀kadà gbà há l’Ékìtì
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin kan, Bernard Shedrach ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju ko maa digun ja ọkada gba lọ, ti wọn si lo ti n bẹbẹ fun oju aanu.
Ọwọ ọlọpaa tẹ Bernard pẹlu iranlọwọ awọn ara agbegbe kan ti wọn n pe ni Trinity Hostel to wa loju ọna Egbe niluu Ọyẹ-Ekiti, ipinlẹ Ekiti.
A gbọ pe asiko ti Bernard n gbiyanju lati digun gba ọkada lọwọ ọkunrin ọlọkada kan ni ọwọ palaba rẹ segi, ko to di pe wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa ẹkun Ọyẹ lọwọ.
Nigba to n ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu jẹ ko di mimọ pe kii ṣe Bernard nikan lo n da ṣiṣẹ ọkada jijagba naa, o sọ pe ẹnikeji rẹ ti na papa bora.
Abutu ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun yii lọwọ tẹ Bernard lasiko ti oun pẹlu ẹnikeji rẹ dọgbọn bii pe wọn n da ọlọkada duro, ṣugbọn to jẹ pe ọtọ ni ero to wa ninu wọn.
O ni oju ọna ni wọn ti da ọlọkada naa duro, ti wọn si da ata gbigbẹ sii loju, koda ti wọn tun la irin mọ-ọn lori.
Ẹnikan ti wọn lo n kọja lọ lo ṣakiyesi ohun to n ṣẹlẹ, tiyẹn si figbe ta, ko to di pe awọn ara adugbo naa sare debẹ.
Abutu jẹ ko di mimọ pe awọn ọlọkada meji kan ti wọn ṣẹṣẹ gba ọkada lọwọ sọ pe Bernard wa lara awọn to ja ọkada gba lọwọ wọn lọjọ keji ati ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2024.
Bakan naa lo ni Bernard ti jẹwọ fun wọn, to si ni wọn yoo foju rẹ ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lẹkunrẹrẹ.