Àbọ̀ ìwádìí EFCC rèé lórí ẹ̀sùn àjẹ́bánu tó fi kan Pasitọ Jerry Eze pé owó Dọ́là àti Pọ́ùn ń rọ̀ bíi òjò sínú àkáǹtì rẹ̀ fún oṣù mẹ́fà

Oríṣun àwòrán, @REALJERRYEZE/INSTAGRAM
O le jẹ iyalẹnu ti eeyan ba n gbọ pe awọn ti a mọ si ẹni Ọlọrun n lọwọ si ẹsun ajẹbanu ati jibiti lilu, to bẹẹ ti wọn n wa ni atimọle fun iwa yii.
Ṣugbọn eyi ni aṣiri ti Alaga ajọ EFCC to n ri si ẹsun ajẹbanu ni Naijiria, Ola Olukoyede, ṣẹṣẹ tu sita l'Ọjọru, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.
Olukoyede sọ pe awọn pasitọ atawọn imaamu kan ni Naijiria wa lahamọ lọwọlọwọ, kootu si ti da awọn kan lẹjọ paapaa fun ajẹbanu ati jibiti lilu.
"Mo ni wọn to pọ nileeṣẹ mi bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii.
"Mo ni wọn ti wọn ti da wọn lẹjọ fun ẹsun jibiti.
"Iwa buruku ti eeyan ba n wu ko kan ti ẹsin ti ẹni naa n ṣe, inu ni iwa ti kaluku n wu wa."
Bẹẹ ni Alaga EFCC naa wi nibi eto ami ẹyẹ kan to waye l'Abuja.

Oríṣun àwòrán, EFCC
EFCC tọpinpin Pasitọ Jerry Eze, ti owo nla nla n wọle si akanti rẹ ni dọla ati pọun lati mọ ibi ti owo ti n wa
Gẹgẹ bi Alaga EFCC yii ṣe wi, iwa ajẹbanu ati jibiti lilu ko kan ti ẹsin musulumi tabi ti igbagbọ, jibiti ko nilo ẹsin ti eeyan n ṣe.
Olukoyede ṣalaye pe pasitọ kan, Jerry Eze, ti owo nla nla n wọle si akanti rẹ ni dọla ati pounds, ni EFCC tọpinpin rẹ lati mọ ibi ti owo ọhun ti n wa, ati iṣẹ to n ṣe ti awọn owo naa fi n wọle kiri bẹẹ.
Alaga EFCC tẹsiwaju nipa akanti naa pe :
"A ri dọla ati pounds to n rọ bii ojo fun oṣu mẹfa lati awọn ilu bii Colombia, America, Sri Lanka ati Togo si akanti ilẹ okeere naa."
Eyi lo ni o fa a ti ajọ naa fi bẹrẹ si i wadii Pasitọ Jerry Eze to n dari ijọ Streams of Joy International, fun ẹsun kikowo jọ lọna èrú ( Money laundering).
Ilana yii ni pe ẹni to n fi jibiti kowo jọ naa yoo maa bo aṣiri ibi ti owo ọhun ti n wa, ti yoo fi da bii pe ọna ire lo gba kowo jọ.
Àbọ̀ iwadii EFCC ni Pasitọ Jerry Eze ṣe daadaa, ti ọwọ rẹ si mọ lori ẹsun iwa ajẹbanu
"Yatọ si lilo ofin lati mu ẹni ti ọwọ rẹ ba kun fun jibiti lilu, EFCC tun maa n fi awọn ti wọn ba ṣewadii ti ọwọ wọn si funfun nẹnẹ lẹyin iwadii naa han fun awọn eeyan lati ri, ki won le fi wọn ṣe awokọṣe."
Eyi ni alaye ti Olukoyede ṣe nigba to n sọrọ nipa bi wọn ṣe wadii pasitọ Eze Jerry fun oṣu mẹfa, ṣugbọn ti abọ iwadii naa pada fi han pe pasitọ naa ko lu jibiti.
"Mo wadii ọkunrin yii fun oṣu mẹfa, fun ẹsun kikowojọ lọna èrú ati lilo ọna ẹburu lati bo aṣiri jibiti.
"A ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, a ṣe ti ifisun.
"Mo ṣaa n wo o pe ta a ni ọkunrin yii, mo ti n gbọ orukọ rẹ tipẹ, mo si ti roju rẹ fun awọn igba diẹ ri, mi o ronu si ohun to n ṣe nigba yẹn.
"Lẹyin iwadii naa ni mo ranṣẹ pe Pasitọ Eze lati ki i.
O si ṣalaye bawọn owo naa ṣe n wọle fun mi ati boun ṣe maa n ran awon eeyan lọwọ.
Mo sọ fun un pe mi o pe ọ wa sibi lati ṣalaye, awa ti ṣiṣẹ tiwa tẹlẹ, mo pẹ ọ wa sibi lati ki ọ ku pe o ṣe daadaa ni."
Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Olukoyede sọ pe o yẹ ki oun fun pasitọ naa ni iwe pe awọn fọwọ sọya pe ọwọ rẹ mọ bayii ni.
"Ohun kan to ku bayii ni lati fun ọ ni lẹta ifọwọsọya pe ọwọ rẹ mọ, amọ mi o ni i fun ọ, nitori mo ṣi maa maa tọpinpin awọn owo rẹ."
Bẹẹ ni Alaga EFCC toun naa jẹ pasitọ, sọ fun Pasitọ Eze, nibi eto fififuni ni ami ẹyẹ to waye l'Abuja.

Oríṣun àwòrán, @REALJERRYEZE/INSTAGRAM
Ta a ni Pasitọ Jerry Eze?
Pasitọ Jerry Eze ni Olori awọn pasitọ ninu ijọ Streams of Joy International.
Ijọ yii wa fun nini ipa laye awọn eeyan kaakiri agbaye.
Pasitọ yii kan naa lo tun n dari eto New Season Prophetic Prayers & Declarations (NSPPD), eto kan ti wọn ti maa n gba adura lori ayelujara.
Nibẹ ni wọn ti maa n sọ aṣọtẹlẹ sinu aye awọn eeyan, awon to si ti ri iyanu nibẹ maa n jẹrii si agbara Oluwa.
O ti ju ọdun mọkanla lọ ti Pasitọ Jerry Eze ti da ijọ rẹ yii silẹ, o si ti gbèrú gidi.
Pastor Eze lo maa n sọ aṣayan ọrọ oyinbo kan to kari bayii, iyẹn 'What God Cannot Do Does Not Exist'. To tumọ si pe ko sohun ti Ọlọrun ko le ṣe.
Ẹka ijọ rẹ bayii ti le ni mẹrindinlọgbọn (26), wọn wa ni Naijiria, Canada, America ati UK.
Gbajumọ Pasitọ ni Jerry Eze, o si ti farahan ni awọn ikanni agbaye bii BBC, CNN atawọn mi-in.
Loju opo YouTube, ikanni rẹ ni wọn lo ni awọn eeyan to n wo o ju ni Naijiria.
Oun naa ni awon eeyan maa n woju to ba n ṣeto ẹsẹkẹsẹ (live) lori ayelujara bi akọsilẹ ṣe sọ.



























