Emi ni obìńrin àkọ́kọ́ tí yóò lo wáyà iná tí kò wúlò láti ṣe iṣẹ́ ọ̀nà àwòrán - Patience Adekunle

Àkọlé fídíò, Emi ni obìńrin àkọ́kọ́ tí yóò lo wáyà iná tí kò wúlò láti ṣe iṣẹ́ ọ̀nà àwòrán - Patience Adekunle
Emi ni obìńrin àkọ́kọ́ tí yóò lo wáyà iná tí kò wúlò láti ṣe iṣẹ́ ọ̀nà àwòrán - Patience Adekunle
Published

Ọpọ obi ni kii fara mọ pe ki ọmọ rẹ lọ kọ isẹ ọna ti a mọ si Fine Arts, paapaa tiru ọmọ bẹẹ ba tun jẹ obinrin.

Lero awọn obi kan, ọmọ ti ko ba mọwe lo maa n kọ nipa isẹ ọna nile ẹkọ fasiti amọ eyi ko ri bẹẹ.

Bi ọrọ se ri ree nipa akẹkọjade ile ẹkọ fasiti LAUTECH kan, Patience Adekunle, ẹni to kọ isẹ ọna, Fine Arts jade nile ẹkọ Fasiti naa.

Amọ isẹ ọna ti Patience Adekunle n se yatọ si tawọn onisẹọna miran nitori pe waya ina ti ko dara mọ ni obinrin naa n lo lati ya isẹ ọna rẹ.

Patience, ọmọ bibi ilu Ogbomoso yii si ni obinrin akọkọ ti yoo kọkọ maa lo waya ina se isẹ ọna afọwọse.

Idi ree ti BBC News Yoruba se tọ Patience Adekunle lọ lati mọ ohun to mu ki isẹ naa wu, ipenija to n ri nibẹ.

Patience Adekunle wọ sokoto penpe ati asọ T-Shirt, o tẹri mọlẹ maa fi waya ya aworan obinrin kan

"Idọti to wa kaakiri ayika wa lo mu mi maa lo waya ina to ti bajẹ fi se isẹ ọna aworan"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọ̀rọ̀, Patience salaye irinajo rẹ sidi yiya aworan tabi sise isẹ ọna eyi to ni o bẹrẹ lati kekere.

Patience ni awọn obi oun, gẹgẹ bi ọpọ obi se maa n se, ko nifẹ si pe ki oun se isẹ ọna tabi lọ kọ nipa rẹ ni fasiti rara tori oju abuku ti wọn fi n wo isẹ naa.

"Lati kekere ni mo ti nifẹ lati maa fi aworan dara, ti mo si pada lọ sile ẹkọ fasiti LAUTECH lati lọ kọ imọ kun imọ.

Oun to sun mi lati maa lo awọn waya ifana wọle to ti bajẹ ti awọn eeyan ko mọ tabi ti wọn ti da nu ni pe mo wo ayika mi, mo si ri pe a ni awọn idọti to pọ kaakiri.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn onisẹọna miran maa n lo awọn nnkan miran to ti bajẹ bii asọ to ti bajẹ, ọra to maa n di gọta ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọna lati mu ki idọti ayika wa dinku, ka si sọ awọn aatan wa di ọrọ̀ lo mu mi maa lo waya to ti bajẹ lati fi se isẹ ọna aworan naa."

Patience Adekunle wọ asọ ankara alawọ yẹlo, o n ge waya lati fi ya aworan, ọkunrin kan duro ti lẹgbẹ.

"Awọn miran a ni isẹ mi ko dara to, isẹ mi ko buyi kun awujọ ati orisirisi awọn ọrọ mii ti ko mu inu mi dun, amọ n ko ka awọn ọrọ yẹn si"

Patience Adekunle tẹsiwaju pe oniruuru abuku ati ẹnu atẹ ni awọn eeyan sọ nipa isẹ ọna ti oun n se lati mu irẹwẹsi ba oun nidi isẹ naa.

"Awọn eeayn sọ wi pe oun ti mo n se ko mu ọpọlọ dani, pe ko tiẹ ni iwulo kankan, abi bawo ni maa se maa lo waya to ti bajẹ fi se isẹ mi?

Mo ri pe awọn eeyan ko ni imọ pupọ nipa ohun ti mo n se amọ n ko jẹ ki awọn ọrọ abuku ti mo n gbọ nipa isẹ mi da omi tutu si mi lọkan.

Amọ se ni mo tubọ n se isẹ naa, mo n wa okun lorisirisi, mo si n sọ fun awọn eeyan nipa isẹ mi.

Awọn miran a ni isẹ mi ko dara to, isẹ mi ko buyi kun awujọ ati orisirisi awọn ọrọ mii ti ko mu inu mi dun, amọ n ko ka awọn ọrọ yẹn si."

Obinrin onisẹ ọna naa salaye pe oun n sisẹ oun leralera siwaju si, ti oun si ri pe oniruuru awọn eeyan lo ti n tẹwọ gba isẹ naa.

Koda, o ni kii se Naijiria nikan ni wọn ti nifẹ si isẹ oun, tori awọn eeyan loke okun gan n wa gba isẹ oun.

"Nigba ti mo se afihan ifẹ lati kopa si ipatẹ isẹ mi, n ko gbọ esi rara lati ọdọ awọn eeyan to se agbatẹru ipatẹ ọja naa.

Nigba miran, awọn eeyan kii kọbi ara si isẹ mi tori wọn ko ni imọ nipa rẹ."

Aworan ti obinrin kan to di irun Suku ti wọn fi waya ina to ti bajẹ se

"O maa n gba mi ni ọsẹ mẹrin tabi ju bẹẹ lọ lati fi pari isẹ kan, to ba jẹ pe isẹ kekere ni amọ mo ti lo osu mẹta si mẹfa lori isẹ kan tori bo se tobi si"

Patience Adekunle fikun pe nigba to ya, ni ọdun diẹ sẹyin awọn eeyan ti n tẹwọ gba isẹ ọna ti oun n se.

"Laarin bi ọdun kan si isinyii, mo ti n ta isẹ mi, ọna ti awọn eeyan fi n tẹwọ gba ti yatọ.

O maa n gba mi ni ọsẹ mẹrin tabi ju bẹẹ lọ lati fi pari isẹ kan, to ba jẹ pe isẹ kekere ni.

Amọ igba miran ti mo ti lo osu mẹta si mẹfa lori isẹ kan tori bo se tobi si.

Bi awọn obi mi se ri pe n ko maa se isẹ yii lasan, ti awọn eeyan ti n ra isẹ mi, ti mo si n ta sita, inu awọn obi mi dun pupọ.

Emi ni obinrin akọkọ to maa kọkọ lo waya ina ati ẹrọ ifanawọle ti ko dara mọ lati fi ya aworan isẹ ọna.

Eleyi tun jẹ ohun to mu inu awọn obi mi dun, idunnu wọn si wa lara awọn nnkan to n ti emi naa lẹyin lati maa se isẹ mi siwaju si.

Patience Adekunle wa gba awọn obinrin nimọran lati maa sisẹ isẹ ọna yii bi o tilẹ jẹ pe awọn ọkunrin lo pọ nidi isẹ naa."