Rofiat Imuran, agbábọ́ọ̀lù Super Falcons sọ̀rọ̀ lórí àwọn ayò tuntun tí Nàìjíríà yóò tun fi tayọ ní WAFCON ọdún yìí
Rofiat Imuran, agbábọ́ọ̀lù Super Falcons sọ̀rọ̀ lórí àwọn ayò tuntun tí Nàìjíríà yóò tun fi tayọ ní WAFCON ọdún yìí
Published
Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti orilẹede Naijiria yoo bẹrẹ ilakaka wọn lati tun gba ife ẹyẹ bọọlu nilẹ adulawọ fun awọn obinrin, WAFCON.
Ẹgbẹ agbabọọlu Falcons ti gba ife ẹyẹ WAFCON ni igba mẹwaa ọtọọtọ: Ọdun 1998 (Naijiria), 2000 (South Africa), 2002 (Naijiria), 2006 (Naijiria), 2006 (South Africa), 2014 (Namibia), 2016 (Cameroun), 2018 (Ghana), 2024 ti wọn gba ni ọdun 2025 (Morroco).
Ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlọgọrin ni Super Falcons ti gba ni idije WAFCON, wọn bori mejilelọgọta, wọn ta ọmi mẹwaa, wọn si padanu meje.
Goolu ojilelugba o din mẹta ni wọn ti gba sinu awọn.





