Ta ló ń pààrọ̀ orúkọ àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú NDC lójú òpó àjọ elétò ìdìbò, bí INEC ṣe sẹ́ pé òun kọ́?

Peter Obi wọ asọ idamọ ẹgbẹ iselu ADC, o n rin lọ pẹlu Rabiu Kwankwaso to wọ asọ toketilẹ funfun

Oríṣun àwòrán, NDC/web

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress, NDC, ti fi ẹsun kan ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC wi pe wọn ti bẹrẹ sii yọ orukọ awọn oludije sipo oṣelu ninu ẹgbẹ awọn, ṣaaju eto idibo apapọ ọdun 2027.

NDC sọ pe ajọ INEC ti bẹrẹ sii fi awọn orukọ ajoji miran rọpo awọn ojulowo orukọ to ti wa ni akọsilẹ wọn tẹlẹ, eyi ti wọn lo ti n ni ọwọ oṣelu ninu.

Alaga agba fun ẹgbẹ oṣelu NDC, Sẹnetọ Moses Cleopas Zuwoghe lo pariwo yii sita lọjọ Aiku ana, lẹyin ti ajọ INEC fi orukọ awọn oludije lẹgbẹ oṣelu sita.

Sẹnetọ Zuwoghe sọ pe awọn orukọ ti ajọ INEC n fi rọpo awọn oludije awọn, ni awọn ko mọ rara, nitori pe wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn.

O ni igbesẹ INEC yii, ko yatọ si wi pe wọn n wa gbogbo ọna lati dabaru eto ẹgbẹ oṣelu NDC, ṣaaju idibo ọdun 2027.

"Kí INEC tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí káàkiri Nàíjiríà"

Sẹnetọ Moses Cleopas Zuwoghe fikun pe "Ẹgbẹ oṣelu NDC, bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ajọ eleto idibo, INEC ati awọn oṣiṣẹ rẹ lori bi wọn ṣe n fi awọn orukọ kan ti a ko fọwọ si, gẹgẹ bi oludije sawọn ipo oṣelu kan sawọn ipo oṣelu kan, paapaa julọ nile igbimọ aṣoju ipinlẹ Anambra, nibi ti oludije sipo aarẹ, Peter Obi ti wa,"

Wọn fi kun ọrọ wọn pe: "Awọn orukọ mẹsan ti ẹgbẹ oṣelu ko mọ rara, awọn ti ẹgbẹ ko fọwọ si, awọn orukọ ti ẹgbẹ ko fi ranṣẹ si INEC, ni ibamu pẹlu ofin, ni wọn ti wa n fi soju opo wọn gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ.

"A wa n pe alaga ajọ INEC lati tete bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ yii, lati mọ bi awọn orukọ naa ṣe jẹ, ati ibi ti wọn ti wa."

Bakan naa ni wọn sọ siwaju pe iwadii naa gbọdọ lọ kaakiri orileede Naijiria, nibi ti igbagbọ ti wa pe iru nnkan bẹẹ tun e ti ṣẹlẹ, lati le dẹkun yiyan awọn ti wọn ko mọ le wọn lori.

"Ki iwadii yii waye lawọn ẹkun bii Benue, Imo ati awọn ipinlẹ miran, nitori pe itiju nla ni igbesẹ yii jẹ fun ẹgbẹ oṣelu wa, ati gbogbo awọn alakoso pata."

Sẹnetọ Zuwoghe sọ pe ẹgbẹ oṣelu NDC naa yoo bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iṣẹ ti wọn lati mọ ibi ti awọn orukọ ọhun ti wa, ati awọn to wa nidi iwa ibajẹ ọhun.

Àwọn orúkọ ti wọn paarọ

Nigba to tọka si awọn orukọ naa, alaga NDC sọ pe awọn orukọ naa ni:

ANAMBRA (SHOA)

1. Onitsha South 1 – Umennaajiego Jude Ezenwa

2. Onitsha South 2 – Akpotue Obinna Chibuike

3. Orumba North – Nwankwo Chiemerie

4. Anaocha 1 – Maduagwu Eric K

5. Idemili North – Ngoebisi Obinna

6. Njikoka 1 – Isintume Charles

7. Nnewi South – Nwachukwu Nonso

8. Nnewi South 2 – Okeke Ifeanyi Akunne

9. Ayamelum – Nnonyelu Samson E.

10. Dunukofia – Azotani Chuks Francis

"Àwa kọ́ la fi àwọn orúkọ wọ̀nyí ránṣẹ́"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sẹnetọ Moses Cleopas Zuwoghe tun sọ siwaju pe "Emi gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu ati alakoso gbogbo eto ti NDC gbe agbara le lọwọ lati fi orukọ awọn oludije sita, kọ ni mo fi awọn orukọ wọnyi ranṣẹ si INEC, bakan naa si ni kii ṣe ẹgbẹ oṣelu wa lo fi awọn orukọ mẹsan wọnyi sita.

"Ohun to ṣẹlẹ ni pe, lẹyin eto idibo abẹle ati ọrọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun (leyi to wa lara ilana yiyan awọn oludije kaakiri), awọn alẹnulọrọ nipinlẹ Anambra ṣiṣẹ papọ pẹlu igbimọ iṣakoso, awọn aṣoju oludije sipo aarẹ, ati igbimọ kotẹmilọrun, leyi to jẹ iṣe wa, fi awọn orukọ ti a buwọ lu ranṣẹ.

"Ṣugbọn ṣa, nigba ti ajọ INEC fi yoo fi awọn orukọ ti a fi ranṣẹ si wọn, soju opo wọn pẹlu aami wa, ajọ INEC da awọn orukọ kan duro.

"Ohun ti wọn sọ ni pe awọn ti ni awọn orukọ naa tẹlẹ, eyi ti wọn sọ pe awọn aṣoju awọn to wa nibi eto idibo abẹle ti a ṣe fi ranṣẹ."

O ni lẹyin ti awọn ti lọ sile-ẹjọ kotẹmilọrun lori igbesẹ naa, nitori pe wọn ko wa sibi eto idibo abẹle ti awọn ṣe, ati pẹlu wi pe awọn fi orukọ awọn to wa ranṣẹ, sibẹ ajọ INEC kọ eti ikun.

O wa rọ ajọ INEC latu ṣe atunṣe lori awọn orukọ naa, ko to di pe o pẹ ju.

Kò sí òtítọ́ nínú ẹ̀sùn tí NDC fi kàn wá – INEC

Ajọ eleto idibo, INEC ti wa jẹ ko di mimọ pe ko si otitọ kankan ninu gbogbo ẹsun ti awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu NDC fi kan awọn.

INEC sọ pe awọn ko ṣe ayipada kankan nibi orukọ ti ẹgbẹ oṣelu naa fi ranṣẹ si awọn.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, Adedayo Oketola to jẹ akọwe iroyin fun ajọ INEC sọ pe irọ to jinna si totiọ ni NDC fi kan awọn.

Oketola to tun jẹ oludamọran pataki fun alaga ajọ naa jẹ ko di mimọ pe INEC ko ni agbara kankan labẹ ofin lati yan oludije fun ẹgbẹ oṣelu, tabi ṣe ayipada ninu orukọ ti ẹgbẹ oṣelu ba fi ranṣẹ si wọn.

"INEC kọ lo n yan oludije fun awọn ẹgbẹ oṣelu. Ojuṣe awọn ẹgbẹ oṣelu ni lati yan oludije wọn, ni ibamu pẹlu ofin ilẹ Naijiria, ati ofin eto idibo ti ọdun 2026, to fi mọ awọn ofin, ilana ati alakalẹ miran," Oketola sọ bẹẹ.

O ni awọn ẹgbẹ oṣelu ni wọn ni aṣẹ ati ẹtọ lati fi orukọ oludije ranṣẹ, bẹẹ si ni wọn lẹtọọ lati fi awọn orukọ ti wọn ba fẹẹ fi rọpo ranṣẹ si awọn.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ojuṣe INEC ni lati tẹle aṣẹ ati itọni ti iwe ofin idibo la kalẹ.

Oketola fi kun ọrọ rẹ pe oju opo ti wọn n fi orukọ awọn oludije si, jẹ eyi ti awọn ẹgbẹ oṣelu fi silẹ fun awọn, lati fi ẹri aridaju awọn oludije wọn si.

O ni, wi pe ajọ INEC ṣe ayipada lori awọn orukọ oludije ẹgbẹ oṣelu NDC kii ṣe otitọ rara, nitori pe ko si nnkan ti awọn le fi pamọ loju opo awọn.

Bakan naa lo ṣalaye pe, ojuṣe ajọ INEC ni lati bojuto eto idibo abẹle fun yiyan awọn oludije, kii ṣe pe ki wọn sọ iru ẹni ti wọn yoo yan si ipo oṣelu.

"INEC ko le bẹrẹ sii gba ojuṣe ẹgbẹ oṣelu ṣe, nipa yiyan ọmọ oye, tabi pe ki wọn ma ṣe gba ilana bi ẹgbẹ oṣelu kọọkan ṣe yan ọmọ oye sipo oṣelu fun wọn," o fidi rẹ mulẹ.