Ojú mi rí màbo láti kékeré títí mo fi délé ọkọ, mo fẹ́ pa ègún, tó ja ìyá mi àti èmi rẹ́ lórí ọmọ - Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/ Instagram
Gbajugbaja oṣerebinrin ilẹ Naijiria nni, Iyabo Ojo, ti sọ idi pataki to fi gba baba awọn ọmọ rẹ, Ọgbẹni Ademidun Ojo laye lati wa nibi ayẹyẹ igbeyawo akọbi wọn, Precilia Ojo-Mkabala.
Iyabo sọrọ naa nibi ifọrọwerọ ori ayelujara to ṣe laipẹ yii pẹlu Morayo Afolabi-Brown.
Oṣere naa sọ pe oun ko fẹ ki ègún iran to ja awọn obi oun, titi de ori oun, tun tẹsiwaju de ori awọn ọmọ, idi niyẹn toun fi wa gbogbo ọna lati pa a rẹ.
Siwaju sii ni obinrin naa jẹ ko di mimọ pe kii ṣe nnkan kekere loju oun ri, latigba toun ti wa ni kekere, titi toun fi di ẹni to n lọkọ, ati pe nigba ti ẹmi oun ko gbe e mọ, lo jẹ koun pinnu lati da duro.
"Mi o fẹ ki egun iran ja lori ọmọ mi"
Lori awuyewuye to dide lasiko ati lẹyin igbeyawo ọmọ rẹ, nipa bo ṣe gba baba awọn ọmọ rẹ laaye lati kopa nibi eto igbeyawo naa, Iyabo Ojo sọ pe lara awọn igbesẹ akikanju toun gbe nigbesi aye oun niyẹn.
"Nnkan kan wa ti wọn maa n pe ni 'Ègún ìran', awa Yoruba nigbagbọ ninu rẹ, awọn Kristẹni naa si maa n nigbagbọ ninu rẹ.
" Mo si nigbagbọ pe bi a ko ba fẹ ki nnkan maa tẹsiwaju, a ni lati wa ọna lati ṣẹgun ni.
"Ṣe ẹ mọ pe baba ati iya mi ko si papọ, gbogbo aṣiṣe ti wọn ti ṣe, ti emi naa si ti ṣe, awọn ọmọ mi ko tun gbọdọ ṣe iru aṣiṣe bẹẹ.
"Gbogbo ohun ti mo n ro tẹlẹ ati awọn kudiẹ-kudiẹ ni mo gbe sẹgbẹ kan, lati le ṣe ẹtọ to yẹ lori ọmọ mi.
"Baba ọmọ mi ko ku, o ṣi wa laye, ki lo wa de ti ko ni i si nibi igbeyawo ọmọ rẹ.
"Ko ṣẹ ọmọ rẹ, emi pẹlu rẹ la jọ ya ara wa, ta a si lọ lọtọọtọ, leyi ti ko kan ọmọ mi. Emi ni mo pinnu lati fẹ ọkọ mi-in nigba naa, ohun to ba ṣẹlẹ laaarin emi pẹlu rẹ, ko yẹ ko kan awọn ọmọ wa."
Bẹẹ ni Iyabo Ojo ṣalaye.
Idi ti mo fi sọrọ igbesi aye mi lori ayelujara
Oṣere naa sọ pe ọkan lara awọn ololufẹ oun to fi atẹjiṣẹ ranṣẹ soun nipa awọn ohun to n la kọja ninu igbeyawo rẹ, lo ti oun lati jade ṣalaye awọn adojukọ toun naa.
O ni nigba tẹni naa fi atẹjiṣẹ ranṣẹ soun, to si bu sẹkun loun ri i pe lara awọn nnkan toun naa ti la kọja sẹyin nile ọkọ ni ẹni naa kọ ranṣẹ.
"Nigba to di pe mo bẹrẹ si i lokiki, mo maa n ri oniruuru ọrọ abuku ti wọn maa n sọ sawọn alabiyamọ to n da gbe pẹlu ọmọ.
"Niṣe lo maa n dabi eewọ nigba naa pe ki eeyan maa dagbe lai lọkọ. Mo si maa n ba ara mi sọrọ pe awọn eeyan yii ko mọ itan mi, ki lo de ti ẹ wa n da mi lẹbi?
Iyabo Ojo fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo obinrin kọ lo maa gbele
ọko titi laye, o ni bi nnkan ko ba lọ bo ṣe yẹ, eeyan yoo kuro nibẹ naa ni.
"Mi o le kọ gbogbo awọn nnkan ti mo la kọja tan, ṣugbọn mo wa ronu pe ki n tiẹ sọ diẹ nipa awọn adojukọ mi, idi niyẹn ti mo fi ṣe fọnran to kaakiri ori ayelujara nigba yẹn."

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/Instagram
Jijẹ agbẹnusọ awọn eeyan maa n mu ori mi wu
Bakan naa lo tun sọ pe gbogbo igba ni inu oun maa n dun, nigba toun ba ri ara oun gẹgẹ bi ẹni to n ja fun ẹtọ awọn eeyan, paapaa awọn obinrin ti wọn n fiya jẹ lawujọ
"Mi o le sọ pe mo ṣi maa maa tẹsiwaju lati maa ja fẹtọọ awọn eeyan, bẹẹ si ni n ko le sọ pe mi o ṣe mọ. Ṣugbọn mo ti n juwọ rẹ silẹ bayii nitori ọmọ-ọmọ mi.
"Ṣebi ẹ mọ pe Pricilia ti ṣegbeyawo bayii, mi o si fẹ kawọn ana mi maa fi oju miran wo mi.
"Ọpọ nnkan lo rọ mọ jija fun ẹtọ eeyan, ṣugbọn to ba yẹ fun mi lati sọrọ soke, maa sọrọ ni gbogbo igba."


























