Wo nǹkan mẹ́tàdínlógún tí ìjọba ti fòfin dè pé wọn ò gbọdọ̀ kò wọlé sí Naijiria mọ́ látòkè òkun

Apo simẹnti, kondoro ti ororo wa ninu rẹ, oogun lilo atawọn ẹru to wa ninu baagi dudu

Oríṣun àwòrán, Nigerian Customs/X/Dangote Cement/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti kede afikun awọn ọja ti wọn o gbọdọ ko wọle si orilẹede Naijiria mọ.

Simẹnti, ọṣẹ, ajilẹ atawọn nnkan mi ti wa lara awọn ọja tawọn eeyan ko le ko wọle mọ bayii.

Ileeṣẹ ijọba to n ri eto iṣuna lo kede ọrọ yii ninu atẹjade kan ti minisita eto iṣuna, Wale Edun, buwọlu.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti ṣalaye, lati ọjọ kini oṣu Kẹrin ni ofin yii ti di titẹle ni Naijiria.

Minisita eto iṣuna sọ ninu atẹjade naa wi pe Aarẹ Bola Tinubu tu buwọlu igbesẹ naa ki awọn to kede rẹ.

Atẹjade naa ṣalaye wi pe lati awọn orilẹede ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ ajọ ECOWAS ni irufẹ awọn ọja bẹẹ ko ti gbọdọ wọle si Naijiria mọ.

''Igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu ofin ajọ ECOWAS to sọ nipa awọn ọja ti ko le wọle lati ilẹ okeere mọ papaa julọ awọn orilẹede ti ko si ninu ajọ ECOWAS.''

Awọn ọja ti ijọba fofin de pe wọn o le ko wọ Naijiria mọ

Lara awọn nnkan ti wọn o le ko wọle mọ si Naijiria mọ ni ẹran adiẹ ati tolotolo ti wọn ti pa, ẹran ẹlẹdẹ ti wọn ti pa, ẹran maalu atawọn ẹran mii to fi mọ nnkan inu ẹran.

Awọn nnkan mii ni ẹyin adiẹ yatọ sawọn to ba fẹ fi pa ọmọ adiẹ lati maa sin tabi to fẹ lo o fun iṣẹ iwadii.

Oniruuru ororo isebẹ ati eyi tawọn eeyan maa fi n para, awọn nnkan ti wọn n fi koko ṣe, tomato bo ya tutu tabi alagolo naa wa lara awọn ọja ti wọn o le ko w|ole si Naijiria mọ.

Oriṣiiriṣii ọti ẹlẹrindodo, simẹnti to wa ninu apo, oogun lilo, ajilẹ, ọsẹ, iwe, paali ati igo.

Ijọba tun kede owo ori tariifu eyi ti yoo bẹrẹ loṣu Kinni ọdun 2027.

Ileṣẹ ijọba to n ri eto iṣuna ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe awọn ti ọja wọn ti wa lọna ṣaaju ọjọ kinni oṣu Kẹrin ọdun 2026 yoo lanfaani lati ko iru ọja bẹẹ wọle.

Amọ, ileeṣẹ ijọba ṣalaye pe ofin tuntun ni yoo mu awọn to ba n ṣẹṣẹ ko ọja wọn bọ lati ọjọ kinni oṣu Kẹrin yii.

Ijọba ni oun gbe igbesẹ yii lati jẹ ki awọn ileeṣẹ to wa ni Naijiria dagba ati lati mu adinku ba bi Naijiria ṣe n ko ọja wọle lati ilẹ okeere.